Yoruba Nation yàtọ̀ sí ẹgbẹ́ tí Dupe Onitiri dá sílẹ̀ – Banji Akintoye

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Adari Ilana Omo Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye ni ọrọ ko ri bi ọpọ awọn oni iweroyin ṣe n gbe kiri pe ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua lo wa ni di ikọlu ti awọn ikọ ajijagbara Yoruba Nation kan ṣe si ọgba ọfisi Gomina ipinlẹ Oyo.

Akintoye, ninu atẹjade kan to buwọlu fun akọroyin, salaye pe awọn ikọ ti wọn ṣe ikọlu yii lo wa labẹ idari Dupe Onitiri- Abiola, iyawo gbajugbaja oloṣelu to ti di oloogbe, M.K.O Abiola.

“Awọn ajijagbara yii darukọ wọn, DEMOCRATIC REPUBLIC OF THE YORUBA, ikọ ajijagbara to wa labẹ Arabinrin Dupe Onitiri-Abiola.

“A ni lati tan imọlẹ si ọrọ yii pe, ilana YORUBA NATION ko ni nnkan ṣe pẹlu Arabinrin Dupe Onitiri-Abiola ati ikọ ajijagbara rẹ.”

Bẹẹ ba gbagbe, ni ọsẹ to kọja ni awọn ajijagbara ti wọn pe ara wọn DEMOCRATIC REPUBLIC OF THE YORUBA ya wọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo pẹlu awọn ọmọ ologun wọn.

Awọn ikọ yii tun parọ aṣia orilẹede Naijiria pẹlu ti Yoruba Nation.

‘Ijọba ni lati kede sita pe awọn n wa Onitiri-Abiola’

Akintoyin ni o ṣeeṣe koko ki ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ gbe igbesẹ ni kiakia, ki wọn si kede sita pe awọn n wa Arabinrin Dupe Onitiri-Abiola lati sọ idi ti ikọlu naa fi waye.

O tẹsiwaju pe bi awọn oni iwe iroyin kan ṣe n gbe kiri pe awọn Ilana ọmọ oodua lo wa ni ikọlu to waye niluu Ibadan ni ko bojumu, to si yẹ ki wọn ṣe iwadii wọn ki wọn to gbe iroyin sita.

“Awọn eeyan to wa labẹ Yoruba Nation jẹ oni suuru eeyan to n gbe igbesẹ ni ilana to ba ofin mu sugbọn awọn ikọ ajijagbara to wa labẹ Dupe Onitiri-Abiola ni wọn jẹ oni jadijagan eeyan ti ko fẹran alaafia ilu.

“A ri fọnran kan nibi ti Arabinrin Dupe Onitiri- Abiola bọ sori afẹfẹ lati fidi rẹ mulẹ pe awọn ni wọn wa nidi ikọlu.

“A n rọ ijọba apapọ lati kede sita pe wọn n wa Arabinrin Dupe Onitiri-Abiola lati wa ṣalaye idi ti ikọlu naa fi waye.”

Afenifere pé fún ìfìyàjẹ àwọn Afurasí Oodua Nation tó yá wọ ọgbà ọ́físì Gómìnà Oyo

Aworan

Oríṣun àwòrán, X/Nigerian Army

Ẹgbẹ Afenifere ile Yoruba ti bu ẹnu atẹlu bi awọn ikọ ajijagbara Oodua Nation ṣe ya wọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ lọsẹ to kọja.

Afenifere, ninu atẹjade kan ti akọwe ẹgbẹ naa, Comrade Jare Ajayi fi lede fun awọn akọroyin, salaye pe awọn to lọwọ ninu ikọlu gbe igbesẹ naa ni ọna ti ọpọ ọmọ Yoruba ti wọn ni awọn n soju lodi si.

O ni ijọba ni lati ṣe iwadi, ko si fiya jẹ wọn ni ilana ti ofin gbekalẹ lati le jẹ ẹkọ fun awọn eeyan mii to ni erongba irufẹ bẹẹ

Bẹ ba gbagbe, ọjọ Satide ọsẹ to kọja ni awọn eeyan kan to pe ara wọn ajijagbara Yoruba Nation yawọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ni Agodi, ti wọn sapejuwe gẹgẹ bii olu ilu fun Ilẹ Yoruba.

Sugbọn Afenifere ni ko si nnkan to jọ mọ orilẹede Ilẹ Yoruba ni bi kibi.

“Ile Yoruba jẹ ilu kan gboogi to wa labẹ orilẹede Naijiria. Gẹgẹ bii a se mọ, ko si nnkan to n jẹ ominira”

Lọwọ lọwọ bayii, awọn eeyan Yoruba wa ni ipinlẹ Ekiti, Eko, Ogun, Ondo, Osun ati Oyo.

Bakan naa ni wọn ni awọn apa ibi kan ni Kwara, Kogi, Delta ati Edo.

Ajayi ni ọpọ iwa ibajẹ lo wa ni ọna ti awọn oloselu fi n da ri orilẹede Naijiria.

“Ọna abayọ si awọn iṣoro yii ki ṣe jagidijagan. Ohun to yẹ ka ma ja fun ni pe ka wa bi a ṣe wa ọna abayọ si iṣoro orilẹede yii.

“Afenifere si ni igbagbọ ninu iṣejọba Aarẹ Bola Tinubu to n sapa fun Naijiria ati awọn olugbe rẹ lati ma gbe papọ ni alafia laipẹ.”

Afenifere ni ilana ti awọn ikọ ajijagbara yii gunle ni ko mu ọpọlọ dani rara.

“Bawo ni eeyan kan tabi ẹgbẹ kan ma ro pe ti awọn ba ya wọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ tumọ si pe awọn ti da idasilẹ orilẹede mii.

“Yoruba ma ronu ki wọn to gbe igbesẹ papa irufẹ igbesẹ bayii. Yoruba ko ki n gbe igbesẹ ni ilana yii.

“Wọn yoo ro ori wọn ki wọn to ni awọn gunle nnkan bayii.”

Agbẹnusọ Afenifere wa pe fun iwadi, to si rọ ijọba lati fiya jẹ awọn afurasi naa ni ilana ti ofin gbe kalẹ, eyi to ni yoo jẹ ẹkọ nla fun awọn eeyan mii to ni irufẹ erongba kanaa.”