Aláboyún wà lára èèyàn tó ti pàdánù ẹ̀mí níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná ní Rivers

Aworan

Eeyan mẹta lo ti padanu ẹmi wọn, ti wọn si jona kọ idanimọ nibi iṣẹlẹ ijamba ina to waye nipinlẹ Rivers.

Akọroyin BBC to ṣe abẹwo si ibi ti iṣẹlẹ ti waye ni ọkọ ayọkẹlẹ mọkanlelọgọta ni o jona kọja kan eru.

Bakan naa ni a tun ṣawari oku alaboyun kan, ọmọ rẹ ati eeyan mii ti wọn ti jona kọja idanimọ.

Iye eeyan to ti lugbadi iṣẹlẹ laabi yii ni a ko ti le sọ sugbọn pupọ awọn to farapa lo ti wa ni ile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju.

Gomina ipinlẹ Rivers, Siminialayi Fubara naa ti ṣe abẹwo si agbegbe naa, to si sapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyi to gba omije loju.

“Pẹlu nnkan ti a ri nibi bayii lowurọ yii, ko dumọ wa ni inu. Ọpọ ọkọ ayọkẹlẹ ni lo jona, ti a si tun padanu ọpọ eeyan.”

Oṣojumikoro ati ọkan lara eeyan ti moribọ nibi iṣẹlẹ ijamba ina to waye ni agbegbe Aleto Eleme nipinlẹ Rivers, Idowu Obalola ni oun, iyawo ati ọmọ mẹta ni Ọlọrun ko yọ nibi iṣẹlẹ naa.

Obalola ni ọkọ ayọkẹlẹ oun jona kan eru lasiko ijamba ina ọhun.

O tẹsiwaju pe oun ati mọlẹbi oun n ti ile ijọsin bọ ni awọn kan sun kẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ni alẹ ti iṣẹlẹ naa waye.

Táńkà epo gbiná ní Rivers, àádọ́ta mọ́tò jóná, ọ̀pọ̀ èèyàn dàwátì

Ibudo iṣẹlẹ ijmaba ina naa

Oríṣun àwòrán, ISAAC LUBEM FACEBOOK

O le ni aadọta mọto to jona raurau lalẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹrin ọdun 2024 yii, nigba ti tanka epo kan gbina lojiji lagbegbe ibudo awọn elepo to wa ni Eleme, nipinlẹ Rivers.

Lasiko ti a n kọ iroyin yii, ko ti i sẹni to mọ iye eeyan to ku tabi farapa ninu iṣẹlẹ naa.

Gẹgẹ bi aṣoju BBC to wa nibẹ ṣe ṣalaye, o ni lẹgbẹ ile ifowopamọ Eco, eyi ti ko jinna si ileeṣẹ elepo Indorama, Eleme, ni ibugbamu naa ti waye.

O fi kun un pe sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ to lagbara to maa n waye loju ọna ọhun lo n ṣẹlẹ lọwọ ti tanka epo naa fi gbina lojiji.

Ti idaamu si ba awọn to wa nitosi lasiko naa.

Ibùdó ìfọpo Naijiria wà lójú ọ̀nà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé

Diẹ lara awọn mọto to jona

Oríṣun àwòrán, ISAAC LUBEM FACEBOOK

Loju ọna Eleme ti ijamba ọkọ yii ti waye, ọkan lara ibudo ifọpo mẹrin ti Naijiria ni wa nibẹ.

Bakan naa si ni ọpọ ileeṣẹ elepo tun wa nibẹ pẹlu.

Ọpọ igba ni sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ maa n wa loju ọna yii ba a ṣe gbọ, latari atunṣe ọna naa to n lọ lọwọ.

Yatọ sawọn ileepo nla wọnyi, awọn ileeṣẹ nla nla mi-in tun fi agbegbe Eleme yii ṣe ọfiisi pẹlu.

Eyi ni wọn lo maa n jẹ ki ero pọ nibẹ ni gbogbo igba.

Awọn fidio iṣẹlẹ naa to ti pọ lori ayelujara, ṣafihan bi ina ọhun ṣe jo ọlọkan-o-jọkan mọto.

Ko ti i si aridaju boya eeyan ku ninu ijamba naa ṣaa, bi ko ṣe ti awọn to farapa ati ọkọ to jona.

Awọn ọkọ̀ nal nibi iṣẹlẹ naa

Oríṣun àwòrán, ISAAC LUMBE FACEBOOK