A o kábamọ̀ ìgbésẹ̀ wá rárá – Afurasí ajìjàgbara Oodua Nation

Aworan

Oríṣun àwòrán, OYO POLICE/INSIDEOYO

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti safihan eeyan mọkanlelogun to jẹ ajijagbara olominira Oodua Nation to yawọ ọfisi Gomina ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo.

Ninu ifọrọwerọ wọn pẹlu awọn akọroyin, pupọ awọn afurasi yii ni awọn ko fi igba kankan kabamọ igbesẹ ti awọn gbe rara nitori o ba ofin mu.

Awọn afurasi ni awọn ko fi ọbẹ ẹyin jẹ ẹnikẹni ni isu, ti gbogbo igbesẹ ti wọn gbe lo jẹ eyi to ni atilẹyin ofin lọwọ.

Alabi Ogundeji, ẹni ọdun marundinlọgọta to jẹ olukọ ile ẹkọ gbogbo nise College of Education ti ijọba apapọ to wa niluu Oyo sọ fun awọn akọroyin pe ọkan oun balẹ pupọ nitori oun wa lori ẹtọ oun, to si tun jẹ ko di mimọ pe nnkan ti oun gunle jẹ nnkan to ba ofin Naijiria ati agbaye mu.

“Mo wa lara awọn ajijagbara, mi o le sọ pe mi o ki n ṣe arawọn. Yoruba gẹgẹ bii ilu nla ti di orilẹede bayii.

“A ni ọpọlọpọ orilẹede labẹ Naijiria, ti Yoruba si jẹ ọkan lara wọn.

“Awọn olori Oodua ti gbe gbogbo igbesẹ to yẹ ki wọn gbe, a ti gunle ayipada ti ọọdẹgbẹta awọn ọmọ Yoruba buwọlu pe ka tẹsiwaju.

“Awọn olori wa lọ si gbogbo ipinlẹ Yoruba lati fun awọn alaṣẹ ni iwe ti awọn olori wa kọ, ti awọn naa si ni ẹda ti wa lọwọ.

“Lẹyin eyi ni akede fun gbogbo agbaye pe Yoruba ti di orilẹede agbaye.

“A wa si ọgba ọfisi Gomina ipinlẹ Oyo lati wa se ajọyọ nitori a ti ni orilẹede ti wa.

“Ko jẹ tuntun pe ilẹ Yoruba ti di orilẹede nitori pe a fẹ da duro fun ara wa. A ti wa pẹlu Naijiria fun ogun ọdun.”

A gbagbọ ninu awọn olori wa – Afurasi

Ademola Adeniyi, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ti oun naa wa lara awọn afurasi naa ni oun ko kabamọ igbesẹ oun lati darapọ mọ awọn ajijagbara ominira ilẹ Yoruba

“A mọ pe ko si nkankan to n sisẹ mọ ni Naijiria, nkan le fun gbogbo araalu ayafi awọn to wa ni ijọba, a wa ni ọgba ọfisi Gomina, ti a n duro fun awọn olori wa lati wa ba wa sọrọ.

“A gbagbọ pe awọn olori wa mọ nipa ofin, fun idi eyi ẹru ko ba wa lati darapọ mọ wọn nigba ti wọn pe wa.

“Awọn olori wa sọ gbogbo ipenija ti n Ilẹ Yoruba n koju ati bi wọn yoo ṣe pese ọna abayọ.”

Ki ni Ileeṣẹ ọlọpaa sọ?

Skip Twitter post, 1

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post, 1

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

Ẹwẹ nigba to sọrọ, Kọmisana ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Adebola Hamzat ni iwa ọdaran ni awọn ajijbara na wu eyi to ni ijiya nla labẹ ofin.

O ni ṣeeṣe koko ki orilẹede Naijiria wa ni iṣokan nitori gbogbo igbiyanju awọn eeyan nla ko gbọdọ ja si ofo.

Hamzat ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ko ni fi igba kankan ju wọ didẹkun iwa ibajé lawujọ paapa lọwọ awọn ajijagbara.

A kò ní fi ààyè gba àwọn tó bá fẹ́ dá wàhálà Yoruba Nation sílẹ̀ l’Ọ́ṣun – Adeleke

Aworan Gomina Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Gomina Ademola Adeleke/X

Gomina Ademọla Adeleke ti ipinlẹ Ọṣun ti gbe awọn ẹṣọ aabo dide lati tako awọn ajijangbara fun idasilẹ ominira ilẹ Yoruba, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni ‘Yoruba Nation Agigators’.

Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni awọn ajijangbara yawọ ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ ninu aṣọ ologun, nibi ti ewọn ti lọ da wahala nla silẹ, ṣugbọn ti ọwọ ọlọpaa pada tẹ awọn ti ko dini ni ogun.

Ṣugbọn lati le dẹkun iru iṣẹlẹ yii nipinlẹ Ọṣun, Gomina Adeleke ti paṣẹ fun oludamọran pataki lori ọrọ eto aabọ, Samuel Ojo lati dide si ọrọ naa.

Adeleke ni oun ko laju silẹ lati jẹ ki ohun to ṣẹlẹ nipinlẹ Ọyọ tun ṣẹlẹ nibi toun ti jẹ gomina, fun idi eyi, o ni awọn eleto aabo duro digbi ni igbaradi si ileeṣẹ ijọba ipinlẹ naa.

Bakan naa lo tun ni ki awọn eleto lọ daabo bo ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ tipinlẹ naa, iyen Osun State Broadcasting Corporation (OSBC), eyi to ni o ṣee ṣe ki awọn ajijangbara naa kọlu.

A gbọ pe lati ọjọ Abamẹta, ọsẹ to kọja yii lawọn eleto aabo ti lọ duro si awọn ileeṣẹ ijọba ati gbogbo ibi ti ijọba ni dukia to jọju si niluu Oṣogbo fun eto aabo to pe ye.

Adeleke ti wa gba awọn eeyan lamọran lati lo ifẹ, iṣọkan ati lati jẹ ki alaafia jọba lasiko yii.

O ni dipo ki awọn ajijangbara maa pe fun idasilẹ orileede Yoruba, ki wọn gbajumọ bi atunṣe yoo ṣe tubọ deba iwe ofin orileede yii, eyi ti yoo ro awọn ipinlẹ lagbara nipa ojuṣe wọn.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe wahala ko le yanju iṣoro orileede yii, bi ko ṣe ijiroro ati apero to lọ ni ibamu pẹlu iwe ofin, to si loun nigbagbọ pe atunṣe to n lọ lọwọ lori iwe ofin Naijiria yoo tan iṣoro naa.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàfihàn ojú afurasí Oodua Nation 20 tó ya wọ ọgbà ọ́físì Gómìnà Oyo

Awọn afurasi ajijagbara Yoruab Nation tọwọ ọlọpaa ba n'Ibadan

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army

Ko din ni ogun eeyan ti wọn ti wa lahaamọ awọn ọlọpaa bayii niluu Ibadan, latari bi wọn ṣe ni wọn ya wọ ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ, nitori ijangbara Ilẹ Olominira Yoruba ti wọn n beere.

Satide, ọjọ kẹtala oṣu kẹrin 2024 lawọn eeyan naa ti wọn wọṣọ ologun, ya bo ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa l’Agodi, niluu Ibadan.

Alukoro ọlọpaa Ọyọ, Adewale Osifẹsọ, ṣalaye pe niṣe lawọn eeyan naa dihamọra ogun wa, wọn si kọju ija sawọn ẹṣọ alaabo.

Aworan

Oríṣun àwòrán, X/Nigerian Army

Lara awọn nnkan ti wọn lawọn ri gba lọwọ wọn ni ibọn mẹta, ọta ibọn ti wọn ko ti i yin to din diẹ lọọdunrun (291).

Ada mẹtadinlaadọrin (67), ẹwu akọtami marun-un, bata tẹkowii mẹfa, aṣọ ologun Oodua mọkanla ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ninu atẹjade ileeṣẹ ọlọpaa Ọyọ ni wọn ti sọ pe iwa ọdaran gbaa to lodi sofin lawọn eeyan naa hu.

Wọn ni ohun to le da omi alaafia gbogbo ilu ru ni wọn danwo.

Iwadii ti n lọ lọwọ lati tun mu awọn mi-in ti wọn ba lọwọ ninu jagidijagan naa.

Skip Twitter post, 2

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post, 2

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

Mi ò mọ nǹkankan nípa àwọn ajìjàgbara Oodu Nation tó kọlu ilé aṣòfin n’Ibadan – Sunday Igboho

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Ajigbara fun ominira ilẹ Yoruba, iyẹn Yoruba Nation, Oloye Sunday ‘Igboho’ Adeyemo ti sọ pe oun ko mọwọmẹseẹ ninu rogbodiyan ti awọn ajiagbara kan fa niluu Ibadan laarọ ọjọ Abamẹta.

Igboho lo sọ ọrọ naa ninu atẹjada kan to fi lede loju opo Instagram rẹ.

O ni oun ko lọwọ ninu ikọlu naa, bẹẹ lawọn ajijagbara ẹgbẹ oun ko ni da irufẹ nnkan bẹẹ laṣa lailai.

Igboho sọ pe “O ti to mi leti pe awọn kan ti wọn pe ara wọn ni ajigbara Oodua Nation gbiyanju lati ja ọọfisi ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo gba.

“Yoo si wu mi lati sọ ọ di mimọ pe mi o lọwọ ninu iṣẹlẹ naa rara.

“Ati pe, ko si ọmọ ẹgbẹ Oduduwa Nation kankan ti yoo jẹ dan irufẹ nnkan bẹẹ wo.

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

“M o rọ ijọba lati ṣewadii finifini lori ọrọ naa ko si fi oju awọn aṣebi ati abanilorukọjẹ naa lede.”

Ṣaaju laarọ ọjọ Abamẹta ni awọn eeyan kan ti kọkọ kọlu ile igbimọ aṣofin naa, ti wọn si gbiyanju lati gba ibẹ ki awọn agbofinro to ṣi wọn lọwọ iṣẹ.

A gbọ pe awọn eeyan naa yọ asia orilẹede Naijiria to wa nile igbimọ aṣofin naa kuro ti wọn si fi asia Oodua Nation sibẹ.

Wayi o, ọwọ awọn agbofinro ti tẹ diẹ lara awọn eeyan ti wọn funra si pe wọn da rugudu naa silẹ.

Ọ̀pọ̀ ajìjàgbara Odua Nation pẹ̀lú ohun ìjà olóró ya wọ ọgbà ọ́fìsì Gómìnà Oyo

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ni owurọ ọjọ Satide ni awọn eeyan kan ti wọn furasi si pe wọn jẹ ọmọ lẹyin ẹgbẹ ajijagbara Odua Nation yawọ ninu ọgba ọfisi Gomina Oyo to wa niluu Ibadan to jẹ olu ilu ipinlẹ naa.

Iroyin to tẹ Ileeṣẹ BBC Yoruba lọwọ ni pe awọn ajijagbara naa yawọ ile igbimọ aṣofin Oyo, ti wọn si parọ asia orilẹede Naijiria pẹlu ti Odua Nation ki awọn ọmọ ologun to de si ibẹ.

Ninu fọnran to tẹ wa lọwọ, awọn ajijagbara naa ni wọn wọ aṣọ ologun lasiko ti ọwọ tẹ wọn.

Bakan naa ni fọnran ọhun tun safihan bi ọwọ Ileeṣẹ Ọlọpaa ṣe tẹ wọn, ti wọn si da wọn dubulẹ ninu ọgba naa

Nigba to n fi iroyin naa mulẹ, oludanmọran si Gomina lori eto abo nipinlẹ Oyo, Fatia Owoseni Rtd ni ọwọ ti tẹ afurasi mẹrindinlogun lara awọn afurasi naa.

Bakan Oludamọran si Gomina lori iroyin, Abosede Sodiq naa fidi isẹlẹ naa mulẹ, o ni bi wọn se yawọ ninu ọgba ọfisi Gomina ni wọn si bẹrẹ si ni yin ibọn soke.

O ni ọwọ awọn agbofinro ti tẹ pupọ awọn afurasi naa

“A ti ke si awọn araalu nitori awọn eeyan yii ni wọn mura ninu aṣọ ologun, pe ki wọn fura si iru awọn eeyan bẹ.”

Nibayii, ọpọ awọn ẹsọ alabo, lati ori Ileeṣẹ ọlọpaa, ileeṣẹ ologun ati awọn Amọtẹkun lo ti wa kaakiri agbegbe naa lati ri pe alaafia jọba.

Bakan naa ni wọn ti gbe igi dina awọn pju ọna kan, ti wọn si rọ awọn araalu lati ma gba agbegbe ti wọn gbe igi dana.