Ìwọ́de gbòde ní Australia láti fòpin sí pípa àwọn obìnrin lọ́nà àìtọ́

Àwọn tó ń ṣe ìwọ́de ní Australia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn ara ìlú ní orílẹ̀ èdè Australia ti bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn láti tako ìwà fífi ìyà jẹ àwọn obìnrin èyí tó ń fi ojoojúmọ́ peléke si ní orílẹ̀ èdè ọ̀hún.

Àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà ń fẹ́ kí ìjọba orílẹ̀ èdè Australia kéde pé ìwà fífi ìyà jẹ àwọn obìnrin bíi ohun tó nílò àmójútó ní kíákíá.

Bákan náà ni wọ́n ń fẹ́ kí ìjọba gbé ìgbésẹ̀ láti fòpin si ní kíákíá.

Olóòtú ìjọba Australia, Anthony Albanese ní ọ̀rọ̀ náà ti di ohun tó ń dààmú gbogbo orílẹ̀ èdè àwọn.

Ní Australia, ní ọdún yìí nìkan, ní ọjọ́ mẹ́rin síra wọn ni ìwà fífi ìyà jẹ àwọn obìnrin àti lílu obìnrin ń rán àwọn obìnrin lọ sọ́run.

Agbátẹrù ìwọ́de náà, Martina Ferrara ní àwọn ń fẹ́ kí ìjọba mọ̀ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà nílò àmójútó ní kíákíá, kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ lásìkò.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ìwọ́de kan ní Canberra, olóòtú ìjọba, Albanse ní ìjọba ní gbogbo ẹ̀ka nílò láti dá sí ọ̀rọ̀ náà.

Àwọn tó ń ṣe ìwọ́de ní Australia

“A nílò láti ṣe àyípadà àṣà, ìwà, òfin àti ìhà tí gbogbo ìjọba kọ sí ìwà fífi ìyà jẹ àwọn obìnrin.

“A nílò láti ri dájú pé kìí ṣe àwọn obìnrin nìkan ló ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, àwọn ọkùnrin nílò láti ṣe àyípadà ìwà wọn.”

Nígbà tó ń bá àwọn olùfẹ̀hónúhàn tó ń bèèrè pé kí ìjọba kéde ìwà fífi ìyà jẹ àwọn obìnrin bíi ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì sọ̀rọ̀, Albanese ní àwọn nílò láti mójútó ọ̀rọ̀ náà díẹ̀díẹ̀ àti pé ohun tí àwọn nílò láti jòkòó yanjú ni.

Àmọ́ agbẹjọ́rò àgbà ní orílẹ̀ èdè Australia, Mark Dreyfus ní ọ̀rọ̀ fífi ìyà jẹ àwọn obìnrin kò tó nǹkan tí àwọn yóò gbé ìgbìmọ̀ díde lórí rẹ̀.

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní Albanese ti máa ń sọ pé ọ̀rọ̀ fífi ìyà jẹ àwọn obìnrin nílò àmójútó àmọ́ kìí ṣe ohun tuntun.

Ní ọdún 2021 ni ìwọ́de ti kọ́kọ́ wáyé ní Australia nígbà tí àwọn kan ń fẹ̀sùn kàn ìjọba pé wọ́n ń bá àwọn obìnrin ṣe ìbálòpọ̀ lọ́nà àìtọ́ nínú ìjọba.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, ọkùnrin kan gún àwọn ènìyàn mẹ́fà lọ́bẹ pa ní ilé ìtajà Sydney, márùn-ún nínú wọn ló jẹ́ obìnrin.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ń ṣe ìwádìí láti mọ̀ bóyá àwọn obìnrin ọ̀hún náà ni ẹni tó gún wọn lọ́bẹ gbèrò láti ṣọṣẹ́ fún ní ilé ìtajà náà.

Àjọ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Destroy the Joint nínú àtẹ̀jáde kan ní obìnrin mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn láàárín ọjọ́ 119 lọ́dún 2024.