Wo àwọn nǹkan méje tí o kò mọ̀ nípa Egbin Orun, akọrin ẹ̀mí tó dolóògbé

Egbin ọrun

Oríṣun àwòrán, Egbin ọrun @Facebook

Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 ni ìròyìn ikú òjijì akọrin ẹ̀mí, Morenikeji Adeleke, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Egbin Orun sọ ọ̀pọ̀ sínú ìbànújẹ́.

Níṣe ni ọ̀pọ̀ ènìyàn ń ké pé àwọn kò gbọ́ pé akọrin ẹ̀mí náà ṣe àárẹ̀ kankan kó tó di pé ọlọ́jọ́ mu lọ.

Àwọn nǹkan márùn-ún tí ẹ kò mọ̀ nípa akọrin ẹ̀mí náà nìyí:

  • Ní ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kejì, ọdún 1985, ni wọ́n bí Egbin Orun èyí tó túmọ̀ sí pé ó jáde láyé lẹ́ni ọdún mọ́kàndínlógójì.
  • Ọmọ bíbí Òkè-Igbó ní ìpínlẹ̀ Ondo ni Egbin Orun bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpínlẹ̀ Eko ni ó ti lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbésì ayé rẹ̀ kó tó fayé sílẹ̀.
  • Ní ọdún 2014 ló bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ orin ẹ̀mí àmọ́ ọdún 2010 ló bẹ̀rẹ̀ ìrńṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìyá ijọ́.
  • O kẹ́kọ̀ọ́ gboyè gẹ́gẹ́ bí dókítà àwọn ọmọdé kó tó di wí pé ó yà sísìí orin ẹ̀mí kíkọ àti iṣẹ́ ìrànṣẹ́.
  • Ó ní orí òkè Egbin Orun tó wà ní agbègbè Ifo, ìpínlẹ̀ Ogun
  • Láti ìgbà tó ti lé ní ogun ọdún ló ti ń kọrin ẹ̀mí, tó sì tún jẹ́ ìyá ìjọ.
  • Ọ̀pọ̀ àwọn akọrin ẹ̀mí ẹgbẹ́ rẹ̀ ló ń fi ìwà ìtọrẹ àánú ròyìn Egbin Orun àti pé ó máa ń ṣe àtìlẹyìn tó gbòòrò fún àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀.

Busola Oke, Esther Igbekele, Omobutty, Madam Saje ṣelédè lẹ́yìn Egbin Orun

Lẹ́yìn tí ìkéde ìròyìn ikú Morenikeji Adeleke, Egbin Orun gbòde ni àwọn òṣèré tíátà kan ti ń kọrin arò lẹ́yìn rẹ̀.

Esther Kalejaye nínú ohun tó kọ sórí Instagram, ní ohun ìbànújẹ́ ni ìròyìn ikú Egbin Orun náà jẹ́ fún òun.

Ó ní àwọn iṣẹ́ ribiribi tí akọrin ẹ̀mí náà ti gbéṣe nígbà ayé rẹ̀ yóò máa wà lọ́kàn àwọn fún ìgbà pípẹ́ àti pé àwọn máa ṣe àfẹ́kù rẹ̀.

Esther Igbekele nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní òun gbàdúrà pé Ọlọ́run tẹ́ olóògbé Egbin Orun sí afẹ́fẹ́ rere àti pé ipá rẹ̀ sí ẹ̀ka orin ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ jẹ́ ohun tí àwọn kò lè gbàgbé láéláé.

Skip Instagram post, 1

Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

Content is not available

View content on InstagramBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

Bákan náà ni gbajúmọ̀ òṣèré Biodun Okeowo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Omobutty náà ní òun kò gbàgbọ́ pé Egbin Orun le ṣe bẹ́ẹ̀ jáde láyé.

Fausat Balogun tí ọ̀pọ̀ sí Madam Saje náà kọrin arò ẹ́yìn Egbin Orun nígbà tó gbé àwòrán àbẹ́là sójú òpó Instagram rẹ̀.

Akọrin ẹ̀mí, Busola Oke nígbà tó gbé fídíò ibi tí òun àti Egbin Orun ní gbogbo ìgbà ní akọrin ẹ̀mí náà yóò máa wà ní ọkàn òun.

Skip Instagram post, 2

Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2

Content is not available

View content on InstagramBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

Wọ́n ti sìnkú Egbin ọ̀run, arẹwà olórin ẹ̀mí tó dolóògbé

Oloogbe Egbin ọrun ati posi rẹ

Oríṣun àwòrán, Others

Pẹlu ipohunrere ẹkun ati ibanujẹ nla ni wọn fi sinku gbajugbaja akọrin ẹmi nni, Basirat Morẹnikeji Adeleke (Egbin ọrun), ẹni tiku rẹ ba aye lojiji.

Oni, ọjọ Aiku, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹrin ọdun 2024 ni Egbin ọrun wọ kaa ilẹ lọ nile rẹ to wa ni Ijakọ, Sanngo, nipinlẹ Ogun.

Ojiji ni iroyin iku Egbin ọrun de setigbọ awọn eniyan, nitori arẹwa obinrin naa ko ṣe aarẹ ti aye gbọ .

Olorin ẹmi bii tiẹ, Esther Igbẹkẹle, lo fi iroyin iku naa soju opo Instagram rẹ lọjọ Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹrin yii.

Nibi ikede naa ni Igbẹkẹlẹ ti sọ pe awọn ṣi jọ wa lọsẹ to kọja, oun ko mọ pe irinajo àlọọ̀dé wa niwaju rẹ.

Ta ni Egbin ọ̀run?

Egbin ọrun

Oríṣun àwòrán, Egbin ọrun @Facebook

Yatọ si pe o jẹ akọrin ẹmi to gbajumọ, oludasilẹ ijọ tun ni Basirat Morenikeji Adeleke (Egbin ọrun).

Ijọ Kerubu lawọn eeyan mọ obinrin to gbajumọ loju opo Tik-Tok naa si.

Ọpọ eeyan to n daro rẹ lo n royin bo ṣe jẹ ẹlẹyinu aanu to.

Wọn ni Egbin ọrun maa n fi tiẹ silẹ ti yoo maa gbọ ti ẹni ẹlẹni nigba to wa laye.

”Egbin ọ̀run ti dáa jù lò ṣe kú ikú tó kú yìí”

Egbin ọrun

Oríṣun àwòrán, Egbin ọrun @ Instagram

Aburo Egbin, ẹni ti oloogbe gba laburo, sọ nibi isinku naa pe didaa ti ẹgbọn oun daa ju lo jẹ ko ku lojiji.

Obirin pupa naa sọ pe boya ka ni ẹgbọn oun daju diẹ ni, ti ko fi gbogbo ẹ daa tan, o ṣee ṣe ko ma ti i ku.

Pẹlu omije lo fi ni afi kawọn ọmọ to fi silẹ ma rare, k’Oluwa ma jẹ ki wọn jiya bii eyi tawọn jẹ nigba ti iya awọn ku.

Dẹrẹba rẹ naa sọrọ, o ni Egbin ọrun ki i ṣe eniyan, angẹli to gbe awọ eeyan wọ ni.

Dẹrẹba to pe orukọ ara rẹ ni Kazeem naa sọ pe, ọga oun ti daa ju leeyan.

O loun ko mọ boya oun le ri eeyan bii tiẹ ba ṣiṣẹ mọ.

Ohun tí a gbọ́ nípa ikú Egbin ọ̀run

Ẹnikan to sunmọ Oloogbe Morenikeji Egbin ọrun, sọ pe iṣẹ abẹ lobinrin naa lọọ ṣe l’Amẹrika.

O ni lẹyin iṣẹ abẹ naa ni wahala ọhun tun pada, to si pada ja siku.

Musulumi ni Egbin ọrun nibẹrẹ aye rẹ, ṣugbọn o pada gba ipe, o si di Kristẹni ati Ajiyinrere ko too ku.

Posi funfun balau ni wọn fi gbe e wọ kaa ilẹ, lẹyin ti wọn fi eeru f’eeru tan.

Ọkọ ati awọn ọmọ lo gbẹyin Oloogbe Morẹnikeji Egbin ọrun