Ọmọ mẹ́wàá ni Ọlọ́run fún mi ṣùgbọ́n méje ló jáde láyé nípasẹ̀ ààrùn Measles- Olùṣọ́-Aguntan Adio

Olusọ aguntan Michael Olaosebikan Adio ti ijọ Christ Apostlic Church ni bi oun ṣe padanu ọmọ meje ninu ọmọ mẹwaa ti Ọlọrun fun oun ko da omi tutu si oun lọkan.

O ni Ọlọrun ti sọ fun oun pe onigbagbọ ko le ṣe alai ma la nnkan wọnyi kọja sugbọn ọja ọla oun yoo dara.

Olusọ aguntan yii to jẹ afọju ba BBC News Yoruba sọrọ lori irinajo aiye rẹ bi o ṣe di pe o padanu oju rẹ.

N kò ní ìrètí pé mo le jẹ́ nǹkan kan láyé

Aworan

Ninu alaye rẹ, Baba Adio ni gẹgẹ bi awọn Obi oun ṣe sọ fun oun pe oun ti le ni ọmọ oṣu meje nigba ti oun gunle aisan igbona.

“Akoko yẹn kii dẹ ṣe akoko ti wọn ni anfani pe ẹ jẹ gbe e lọ si ile iwosan sugbọn wọn n tọju mi .

“Sugbọn nigba ti mo maa gbadun, inu oju yii lo yọri si, koda ọrọ oju yii gan an lo gbe mi de idi iṣẹ iranṣẹ ni ọdun 1951.

“Wọn mu mi lọ si ọdọ iransẹ Ọlọrun ni ọdun 1951pe ki wọn le gbadura fun mi ki n le riran.

“Sugbọn ohun ti Oluwa wi ni pe ọkan ninu iranṣẹ ni mo jẹ fun oun Ọlọrun

“O ni maa fi oju inu riran sugbọn tode ko ni riran.”

“Igbona lo n pa mi lọmọ”

Nigba ti Baba Adio n sọrọ nipa bi o ṣe padanu ọmọ mẹwaa, Olusọ aguntan Adio ni ko si ọkankan ninu awọn ọmọ oun to ku iku ijamba ọkọ ninu wọn sugbọn igbona to gba oju lọwọ oun lo ṣekupa wọn.

“Ọmọ mẹwaa ni Ọlọrun fun mi sugbọn meje ni Ọlọrun pe si ọdọ ara rẹ pada saaju mi laye

“Bi igbona sanpọnna ti a n pe ni “Measle” yẹn lo ṣekupa wọn.

“Ohun naa lo n pa mi lọmọ

“Bi isẹlẹ yii ti n ṣẹlẹ, ko da omi tutu si mi lọkan, mi o le ṣe alai ma laa nkan wọnyii kọja”

Baba Adio gba awọn to n la ipenija tabi iṣoro kanakan kọja lasiko yii lati ma ronu pa ara wọn.

Baba agba yii sọ pe ko si ohun tuntun labẹ ọrun mọ ninu iṣoro ninu aye ṣugbọn ki onikaluku fi ọkan tan Olorun Olodumare to da aye ati ọrun ti yoo si fun wa ni isinmi nigab ti akoko ba to.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí

Babalawo ati ọpọn Ifa