Wọ́n ti sìnkú Egbin ọ̀run, arẹwà olórin ẹ̀mí tó dolóògbé

Oloogbe Egbin ọrun ati posi rẹ

Oríṣun àwòrán, Others

Egbin ọrun

Oríṣun àwòrán, Egbin ọrun @Facebook

Pẹlu ipohunrere ẹkun ati ibanujẹ nla ni wọn fi sinku gbajugbaja akọrin ẹmi nni, Basirat Morẹnikeji Adeleke (Egbin ọrun), ẹni tiku rẹ ba aye lojiji.

Oni, ọjọ Aiku, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹrin ọdun 2024 ni Egbin ọrun wọ kaa ilẹ lọ nile rẹ to wa ni Ijakọ, Sanngo, nipinlẹ Ogun.

Ojiji ni iroyin iku Egbin ọrun de setigbọ awọn eniyan, nitori arẹwa obinrin naa ko ṣe aarẹ ti aye gbọ .

Olorin ẹmi bii tiẹ, Esther Igbẹkẹle, lo fi iroyin iku naa soju opo Instagram rẹ lọjọ Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹrin yii.

Nibi ikede naa ni Igbẹkẹlẹ ti sọ pe awọn ṣi jọ wa lọsẹ to kọja, oun ko mọ pe irinajo àlọọ̀dé wa niwaju rẹ.

Ta ni Egbin ọ̀run?

Egbin ọrun

Oríṣun àwòrán, Egbin ọrun @Facebook

Yatọ si pe o jẹ akọrin ẹmi to gbajumọ, oludasilẹ ijọ tun ni Basirat Morenikeji Adeleke (Egbin ọrun).

Ijọ Kerubu lawọn eeyan mọ obinrin to gbajumọ loju opo Tik-Tok naa si.

Ọpọ eeyan to n daro rẹ lo n royin bo ṣe jẹ ẹlẹyinu aanu to.

Wọn ni Egbin ọrun maa n fi tiẹ silẹ ti yoo maa gbọ ti ẹni ẹlẹni nigba to wa laye.

”Egbin ọ̀run ti dáa jù lò ṣe kú ikú tó kú yìí”

Egbin ọrun

Oríṣun àwòrán, Egbin ọrun @ Instagram

Aburo Egbin, ẹni ti oloogbe gba laburo, sọ nibi isinku naa pe didaa ti ẹgbọn oun daa ju lo jẹ ko ku lojiji.

Obirin pupa naa sọ pe boya ka ni ẹgbọn oun daju diẹ ni, ti ko fi gbogbo ẹ daa tan, o ṣee ṣe ko ma ti i ku.

Pẹlu omije lo fi ni afi kawọn ọmọ to fi silẹ ma rare, k’Oluwa ma jẹ ki wọn jiya bii eyi tawọn jẹ nigba ti iya awọn ku.

Dẹrẹba rẹ naa sọrọ, o ni Egbin ọrun ki i ṣe eniyan, angẹli to gbe awọ eeyan wọ ni.

Dẹrẹba to pe orukọ ara rẹ ni Kazeem naa sọ pe, ọga oun ti daa ju leeyan.

O loun ko mọ boya oun le ri eeyan bii tiẹ ba ṣiṣẹ mọ.

Ohun tí a gbọ́ nípa ikú Egbin ọ̀run

Ẹnikan to sunmọ Oloogbe Morenikeji Egbin ọrun, sọ pe iṣẹ abẹ lobinrin naa lọọ ṣe l’Amẹrika.

O ni lẹyin iṣẹ abẹ naa ni wahala ọhun tun pada, to si pada ja siku.

Musulumi ni Egbin ọrun nibẹrẹ aye rẹ, ṣugbọn o pada gba ipe, o si di Kristẹni ati Ajiyinrere ko too ku.

Posi funfun balau ni wọn fi gbe e wọ kaa ilẹ, lẹyin ti wọn fi eeru f’eeru tan.

Ọkọ ati awọn ọmọ lo gbẹyin Oloogbe Morẹnikeji Egbin ọrun