Kí ni òfin sọ nípa títàbùkù owó Náírà?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yoruba ni ilu ti ko si ofin, ẹsẹ ko si sugbọn orilẹede Naijiria, ofin wa, ti ijiya si wa fun ẹnikẹni to lodi si awọn ofin ti ilu gba kalẹ.

Lọsẹ to kọja ni Ileẹjọ ran gbajugbaja ilumọka ọkunrin to n mura bi obinrin, Idris Olarewaju Okuneye, ẹni ọpọ si Bobrisky lọ ẹwọn fun oṣu mẹfa fun ẹsun pe o tabuku si owo naira.

Adajọ Abimbola Awogboro ni riran Bobrisky sẹwọn ni yoo jẹ ẹkọ fun ọpọ awọn eeyan to n lodi si ofin orilẹede Naijiria.

Gẹgẹ bii ofin ti banki apapọ gbe kalẹ, o ni awọn iwa kan nipa owo naira to lodi sofin orilẹede Naijiria.

Wọ ọna to fi le lodi sofin ti tabuku si owo naira.

  • Nina owo loju agbo- O lodi sofin orilẹede Naijiria pe ki eeyan ma na wo loju agbo.
  • Kikọ nnkan sori owo- Ofin ko faye gba ki eeyan ma n kọ nnkan sowo rara.
  • Lilẹ owo pọ pẹlu irin- Eyi naa lodi sofin pupọ.
  • Yiya owo- Eeyan ko lẹtọ lati yawo labẹ ofin
  • Jijo lori owo tabi titẹ owo mọlẹ- Fun awọn oni ode ariya, titẹ owo mọlẹ lodi pupọ si ofin orilẹede Naijiria
  • Tita owo- Tita owo tabi rira owo lodi si ofin .
  • Dida owo pada – Fun Ontaja, o lodi si ofin pe ki wọn da owo pada .

Bobisky kò gba ìtọ́jù tò yàtọ̀ sí ti ẹlẹ́wọ̀n míì– NCS

Aworan Bobrisky

Oríṣun àwòrán, EFCC/X

Ileeṣẹ to n ṣakoso ọgba ẹwọn, Nigeria Correctional Service, ẹka ti Ikoyi nipinlẹ Eko ti sọ pe gbajugbaja ọkunrin to n ṣebi obinrin nni, Idris Okunẹyẹ ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Bobrisky ko gba itọju kankan to yatọ si ti ẹlẹwọn tó kù.

Bi ẹ ba gbagbe, Bobrisky ni Onidajọ Abimbọla Awogbọrọ ti ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa niluu Eko ju sẹwọn oṣu mẹfa gbako pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun ṣiṣe owo naira niṣekuṣe.

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn alabojuto ọgba ẹwọn ti Bobrisky wa ṣe ṣalaye fun iwe iroyin abẹle PUNCH, wọn ni itọju to tọ si awọn ẹlẹwọn naa ni ọdọkunrin ọhun n gba lọgba ẹwọn awọn ọkunrin to wa.

Ẹni naa to ni ki wọn fi orukọ bo oun laṣiri nitori ti ko ni ẹtọ lati sọrọ ṣalaye siwaju pe kete ti wọn ti mu Bobrisky de lawọn ti ṣayẹwo fun un.

O ni ọkunrin pọmbele ni Bobrisky, ko si si ayipada kankan lara rẹ to yatọ si ti ọkunrin.

“Loju gbogbo aye ni Bobrisky ti sọ pe ọkunrin lohun, igbẹjọ ile-ẹjọ si jẹ eyi to ni akọsilẹ. Gbogbo ẹlẹwọn ti wọn ba ṣẹṣẹ mu de ni wọn ma n la ayẹwo kọja.

“Ohun ti a ṣe fun un ko yatọ si eyi ti a n ṣe fun awọn ẹlẹwọn yooku. Lẹyin ayẹwo, a ko ri ohunkohun to yatọ si ti nnkan ọmọkunrin rẹ.

“Gbogbo ohun ti ọkunrin fi n jẹ ọkunrin lo wa lara Bobrisky. Lẹyin eyin, a fun un ni ẹwọn to tọ sii, to si tun ni iye awọn ẹlẹwọn to wa pẹlu rẹ.

“A fun un ni agbegbe ibusun rẹ. Niṣe lo dabi ile adagbe nibi ti ọga eeyan yoo ti fun ẹni to n ba ṣiṣẹ lawọn ohun ti yoo lo.”

Bakan naa ni ẹni naa tun ṣalaye fun PUNCH pe ọdọkunrin to n ṣebi obinrin yii n tẹle ilana ati ofin ọgba ẹwọn to ba.

“Nigba to ba to asiko lati lọ kilaasi, o maa n yọju. Nigba to ba to asiko ounjẹ, o maa lọ gba ounjẹ tiẹ. Bẹẹ naa lo ri pẹlu awọn eto yooku.

“Gbogbo awọn ohun to n ṣẹlẹ lọgba ẹwọn lo n yọju si. Oun naa si ti n ba kadara rẹ yi gẹgẹ bi awọn ẹlẹwọn yooku to ba nibi ṣe n ṣe.”

Bakan naa lo tun fi kun ọrọ rẹ pe ileeṣẹ ọgba ẹwọn ko fi aaye gba ki awọn ẹlẹwọn maa fi iya jẹ ara rẹ, paapaa awọn to ba ṣẹṣẹ de.

“Ko gba itọju to yatọ si ti awọn yooku to ba, ko jaye alakata nibi, bẹẹ si ni ko sẹni to daabo bo o kurọ lọdọ ẹnikẹni. Gbogbo ilana ati ofin lo n tẹle gẹgẹ bi awọn to ba nibi ṣe n ṣe.

“Ọgba ẹwọn adagbe wa fun lati dena arun to le tan kaakiri. Ni ọgba ẹwọn awọn ọkunrin, ko saaye fun ki ọkunrin maa ba ọkunrin lajọṣepọ, ẹṣẹ nla ti ofin koro oju si ni.

“Ṣiṣe iṣekuṣe ati ibalopọ ọkunrin si ọkunrin tako ofin. Fun idi eyi, ẹlẹwọn to ba gbiyanju lati ṣe iru nnkan bayii yoo fi oju winna ofin.”