Yàtọ̀ sí ọkọ Dora Akunyili, wo àwọn ibòmìí tí wọ́n tún ti pààyàn ní Anambra lọ́jọ́ kan nàá

Awọn ọlọpaa ṣe abẹwo si ibi ti wọn pa ọkọ Akunyili si

Oríṣun àwòrán, others

Inu ibẹru-bojo ni awọn eniyan ipinlẹ Anambra ṣi wa lọwọlọwọ nitori iki Dokita Chike Akunyili, ọkọ oloogbe Dora Akunyili.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ṣe sọ, iku Dokita Akunyili nikan kọ lo waye nipinlẹ naa lọjọ Iṣẹgun.

Ọna marun-un ni itajẹ silẹ ti waye.

Akojọpọ awọn ipaniyan to waye ọhun rẹ e:

  • Dokita Chike Akunyili, ni awọn agbebọn ti ẹnikẹni ko mọ yinbọn pa ni Umuoji, nijọba ibilẹ Idemili North nirọlẹ ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an. Eyi waye lasiko to n pada si Enugu lẹyin to kopa nibi eto kan ti wọn fi yẹ iyawo rẹ si nilu Anambra. Wọn pa awakọ rẹ naa, ati ọlọpaa to wa pẹlu rẹ.
  • Awọn janduku kọlu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ni agọ wọn to wa ni Aguata Area Command ni nkan bi aago meji ọsan ọjọ Iṣẹgun bakan naa. Asiko ti awọn ọlọpaa naa n einkiri fun eto aabo ni opopona Ezinifite/Igboukwu ni wọn kọlu wọn, ti wọn si dana sun ọkọ wọn. Amọ, ko si ẹni to ku.
  • Ni bi aago marun-un irọle ọjọ naa bakan naa, awọn agbebọn kọlu ẹnikan ni opopona Oko.

Wọn dana sun ọkọ rẹ, wsn si fi onitshun silẹ pẹlu ọgbẹ ibọn, ki wọn o to o salọ.

Awọn eeyan ri ẹni naa doola, wọn si gbe lọ sileewosan.

  • Lọjọ yii kan naa, ni bi aago mẹrin irọle, awọn agbebọn kan gbiyanju lati gba ọkọ ayọkẹlẹ Lexus 350 lọwọ awakọ kan ni opopona Agulu, ti wọn si yinbọn mọ.

Botilẹ jẹ pe wọn pada salọ lai gbe ọkọ naa, ibọn ti wọn yin mọ ẹni naa gba ẹmi rẹ ki wọn o to o gbe de ileewosan.

  • Ni bi aago marun-un ọjọ yii bakan naa, ni awọn agbebọn tun yinbọn pa Isipẹtọ ọlọpaa kan ni Nkpor Round-abaout, wọn tun bẹ ọkunrin kan lori.

Gbogbo ikọlu yii waye ṣaaju idibo gomina ipinlẹ Anambra, ti yoo waye ni ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla.

Gomina ipinlẹ Anambra, Willie Obiano ti bu ẹnu ẹtẹ lu iwa ipanle to n waye nipinlẹ naa lati ọjọ diẹ sẹyin.

Gomina Willie Obaino

Oríṣun àwòrán, ANAMBRA STATE GOvernMENT

O si ṣeleri ogun miliọnu Naira fun ẹnikẹni to ba ni aṣiri to le ṣe atọna fun bi ọwọ yoo ṣe tẹ awọn to n ṣe ikọlu nipinlẹ naa.

Ẹgbẹ́ IPOB ní òun kò lọ́wọ́ nínú ikú ọkọ Dora Akunyili, Chike

Ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹ-ede Biafra, IPOB, ti kede pe oun ko lọwọ ninu bi awọn agbebọn ṣe pa ọkọ alaga ajọ NAFDAC nigba kan, oloogbe Dora Akunyili, Chike Akunyili.

Ọjọru ni iroyin jade pe awọn agbebọn pa ọjọgbọn Akunyili, awakọ rẹ, ati ẹṣọ alaabo rẹ kan, lasiko to n rinrinajo lati ipinlẹ Anambra si Enugu.

Ninu atẹjade ti ẹgbẹ IPOB fi sita, ẹgbẹ naa sọ pe oun ko lọwọ si awọn ipaniyan to n waye lasiko yii nilẹ Biafra.

O ni “awọn oloṣelu kan lo n fi orukọ IPOB boju, lati ma a pa awọn alatako wọn”.

“A ko ni ede aiyede kankan pẹlu Chike Akunyili, a ko si mọ ọ ri.”

IPOB sọ pe ki gbogbo awọn to n fi orukọ ẹgbẹ naa boju ṣe iṣẹ ibi jawọ ninu iwa naa.

Wọn ṣapejuwe iku Ọjọgbọn Akunyili gẹgẹ bi ipaniyan oṣelu, eyi to n waye lọwọlọwọ nitori eto idibo gomina ipinlẹ Anambra to n bọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bí àwọn agbébọn ṣe pa ọkọ mínísítà ètò ìròyìn tẹ́lẹ̀, Dora Akunyili

Awọ agbebọn kan ti yibọn pa dokita Chike Akunyili, to jẹ ọkọ minisita fun eto iroyin tẹlẹ, Ọjọgbọn Dora Akunyili.

Iroyin ni awọn agbebọn ọhun ṣekupa okunrin naa niulu Umuoji, to wa ni ijọba ibilẹ ariwa Idemili, ni ipinlẹ Anambra.

Ẹnikan to sumọ idilẹ oloogbe naa ṣalaye fun awọn akọroyin pe oloogbe ọhun ṣi wa nibi ipade awọn akẹkọjade faisiti ijọba apapọ to wa ni Nsuka, UNN, nibi ti wọn ti ṣe ayẹsi fun un.

Ẹni naa sọ pe “Mo ṣi wa pẹlu rẹ lanaa ni gbọgan Sheraton to wa nile ijọsin All Saints Cathedral niluu Onitsha.”

“Nibẹ ni a ti ṣe ipade awọn akẹkọjade faisiti ijọba apapọ to wa ni Nsuka nibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti ṣe ayẹsi fun. un”

Ẹni naa ṣalaye pe oloogbe ọhun sọrọ daadaa nipa iyawo rẹ to jẹ minisita nigba kan ri, o si fi ẹbun owo 500,000 naira ta ẹgbẹ awọn akẹkọjade lọrẹ.

O ni “Koda, oun ati ọmọ rẹ okunrin ti orukọ rẹ n jẹ Obum ni wọn jọjọ wa nibi ipade naa.”

“A sin awọn mejeji lọ sidi ọkọ wọn, baba ati ọmọ naa si di mọ ara wọn ki awọn mejeji to pinya lọ sidi ọkọ wọn.”

Ẹwẹ, ẹlomiran to sunmọ ẹbi ọloogbe naa ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC.

Ẹni naa ni inu ibanujẹ nla ni awọn ẹbi oloogbe naa wa lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ