Àwọn Oba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí Oba míràn jẹ lójú ayé wọn

Ọba Ibikunle Akitoye

Oríṣun àwòrán, Others

Yoruba ni a ko ri iru eyi ri, a fi n dẹru ba ọlọrọ ni nitori ko si ohun ti oju ko ri ri, ẹsin ta ta ta, o ku, eniyan rin, rin, rin, o sọnu.

Ọpọ ọdọ ni ẹnu ya nigba ti wọn kede pe wọn yọ odidi ọba lapa oke ọya, ti wọn si n sọ pe eyi ko le e sẹlẹ nilẹ Kaarọ oojire.

Ọpọ eeyan si lo maa n pa owe pe bi ọba kan ko ba ku, ọba miran ko lee jẹ, eyi to ti n di irọ nla bayii nitori awọn oriade ana kan wa nilẹ Yoruba, to jẹ pe loju aye wọn bayii, ni wọn se fi ọba miran jẹ lati rọpo wọn.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Idi si ree ti BBC Yoruba fi wọ inu itan lọ, paapa pẹlu awọn akọsilẹ to wa lori itakun agbaye, se itan kii ku, lati selanilọyẹ lori awọn isẹlẹ to ti waye sẹyin nipa ọpọ ọba ti wọn ti rọ loye, ti awọn miran ninu wọn, ko si pada sori oye mọ titi di ọjọ iku wọn.

Awọn ọba alaye nilẹ Yoruba ti wọn ti rọ loye:

Ọba Ibikunle Akitoye ati ọba Kosọkọ tilu Eko:

Ọba Kosoko

Oríṣun àwòrán, Others

  • Ori ọba Ibikunle Akitoye tilu Eko ni itan sọ fun wa pe isẹlẹ iyọnipo ọba ti kọkọ waye nilẹ Yoruba, nigba ti awọn eebo amunisin le kuro lori itẹ, ki isẹlẹ ti ọba Kosọkọ naa to tẹle
  • A si lee ni awọn eebo amunisin lo sefilọlẹ asa rirọ ọba loye nilẹ Yoruba, tori ko si akọsilẹ isẹlẹ kankan to ti waye saaju ki awọn oyinbo to de.
  • Ọdun 1841 ni Ọba Akitoye gori itẹ awọn baba nla rẹ, gẹgẹ bi ọba tilu Eko, asiko yii si ni owo ẹru gbinaya, eyi ti ko dun mọ ọba naa ninu ati awọn oyinbo kan nilẹ Gẹẹsi

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

  • Oba naa gbinyanju lati pa owo ẹru run amọ o ba ibinu awọn olowo ẹru labẹle pade, ninu eyi ta ti ri ipa obinrin takuntakun Ẹfunroye Tinubu, ti wọn si le kuro lori itẹ ati kuro ni ilu Eko, pẹlu atilẹyin awọn oyinbo kan, ti ọba Akitoye si gba ilu ọba lọ
  • Aburo rẹ, Kosọkọ lo jọba lẹyin rẹ amọ lẹyin tilẹ Gẹẹsi fofin de owo ẹru sise patapata lọdun 1807, lawọn eebo ba tun se atilẹyin fun Akitoye lati pada sori itẹ lọdun 1851, ti wọn si le ọba Kosokọ kuro lori oye ati laarin ilu, lọ si Badagry.
Ọba Akitoye

Oríṣun àwòrán, Others

Ọba Samuel Adedapọ Ademola keji, Alake tilẹ Ẹgba:

  • Ọba Samuel Adedapọ Ademola keji, Alake tilẹ Ẹgba ni ọba keji ta a ka pe wọn le lori itẹ nilẹ Yoruba, bi o tilẹ jẹ pe ọba ọlaju, olokoowo nla ati ọmọwe ni
  • Ọdun 1920 ni ọba Ademola jọba, to si lo ọdun mejilelogoji lori oye amọ wọn le kuro fun ọdun meji laarin ọdun 1948 si 1950 nitori ija igboro ati iwọde kan ti awọn obinrin bẹrẹ rẹ lati tako ọba naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

  • Iya ilumọọka olorin kan, Fela, eyiun Funmilayo Ransome Kuti la gbọ pe o se agbatẹru ifẹhonu han naa fawọn obinrin ti wọn le ni ẹgbẹrun lọna ogun.
  • Koda, wọn si koro oju si ofin sisan owo ori ti wọn gbe kalẹ
  • Wọn fi ẹhonu yii le ọba ni aafin, lọ se atipo ni ilu Osogbo, amọ wọn pe pada wa sori itẹ lẹyin ọdun meji.
  • Itan fi ye wa pe Alaafin tilu Ọyọ lọwọlọwọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta, naa ba ọba Ademọla lọ silu Osogbo, nitori ọdọ ọba naa lo n gbe lasiko ti isẹlẹ iyọloye naa waye.
Ọba Ademola ati awọn oyinbo

Oríṣun àwòrán, Others

Ọba Adeniran Adeyemi Keji, Alaafin tilu Oyo:

  • Itan tun sọ fun wa pe baba to bi Alaafin to wa lori oye bayii, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi Kẹta, ti orukọ rẹ n jẹ Ọba Adeniran Adeyemi keji ni ijọba ẹgbẹ oselu Ọlọpẹ, Action Group, AG le kuro lori oye
  • Ọba Adeyẹmi keji si lo jẹ Alaafin tilu Ọyọ laarin ọdun 1945 si ọdun 1954 ti wọn yẹ itẹ sba mọ nidi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

  • A gbọ pe eyi ko sẹyin isẹlẹ kan to waye, eyi to mu ẹmi Oloye Olabode Thomas lọ, ẹni to jẹ agba oselu ninu ẹgbẹ oselu naa, ti ọrọ si se bii ọrọ laarin awọn mejeeji nibi ipade kan to waye lọjọ kejilelogun osu kọkanla ọdun 1953 eyi to mu ki wọn so iku agba oselu naa mọ ọrun Alaafin
  • Ọdun 1954 ni wọn yọ ọba Adeyemi keji lori oye, wọn le kuro nilu Ọyọ lọ si Ilesa, ko to pada lọ gba nilu Eko nibi to ti tẹri gbasọ lọdun 1960.
Oba Adeniran Adeyemi ati ọm rẹ kan

Oríṣun àwòrán, Others

Ọba Adetoyese Laoye, Timi tilu Ede:

  • Ọba Adetoyese Laoye lo jẹ Timi tilu Ẹdẹ laarin ọdun 1946 si osu karun ọdun 1975. Laoye ati awọn ọmọ oye to to mejilelọgbọn ni wọn jọ du oye ọba yii fun osu mọkanla gbako amọ ti ade naa ja mọ lọwọ, to si gori itẹ awọn baba nla rẹ lọjọ Kẹsan osu Kejila ọdun 1946
  • Amọ eekan kan gbogi ninu awọn ọmọ oye ti wọn jọ lọ apere naa ms ara wọn lọwọ, Memudu Lagunju gbe ọrọ naa lọ sile ẹjọ, to si gba idalare, eyi to mu ki wọn le Ọba Laoye kuro lori itẹ lọjọ kẹjọ osu kinni ọdun 1948, to si n gbe nilu Eko
  • Amọ ileẹjọ ẹkun iwọ oorun Afirika to gbọ ẹjọ kotẹmilọrun nipa oye naa le Memudu Lagunju kuro nipo naa , to si kede pe ki Laoye pada sori itẹ gẹgẹ bii Timi tilu Ẹdẹ lọdun 1952.
Oba Adetoyese Laoye, Timi ti Ẹdẹ

Oríṣun àwòrán, Others

Ọba Ọlatẹru Ọlagbẹgi, Ọlọwọ tilu Ọwọ:

  • Ọdun 1941 ni ọba Ọlatẹru Ọlagbẹgi gori itẹ awọn baba nla rẹ, to si jẹ ọba fun ọdun mẹẹdọgbọn ko to di pe wọn le kuro lori itẹ, eyi ti ko sẹyin wahala to n waye laarin Awolowo ati Akintola nitori ọrọ oselu ati ẹgbẹ oselu Ọlọpẹ
  • A gbọ pe Ọlatẹru Ọlagbẹgi se atilẹyin fun Samuel Ladoke Akintola lati tako Obafemi Awolowo nigba naa, nigba tawọn ologun si gba ijọba lọdun 1966, awọn ara ilu Ọwọ fi ẹhonu han tako ọba wọn, eyi to mu kijọba Adekunle Fajuyi le kuro lori itẹ losu kẹfa ọdun 1966
  • O gbiyanju lati pada sori itẹ lọdun 1968 amọ eyi se okunfa iporogan nla nilu Ọwọ, wọn sun ọpọ ile nina, ti ọpọ ẹmi si lọ si bakan naa, eyi to mu ki ijọba Adeyinka Adebayọ kuku le kuro lori itẹ patapata, ti wọn si le silu Okiti pupa lati maa gbe, ti ọba Adekola Ọlagunoye si gun ori itẹ laarin osu kan
  • Ọba Ogunoye waja lọjọ kejilelogun osu kẹrin ọdun 1993, ti ijọba Bamidelu Olumilua si yan Ọlatẹru Ọlagbẹgi pada gẹgẹ bii Ọlọwọ tilu Ọwọ lọdun 1993, to si waja lọdun 1998, ti ọmọ rẹ, Folagbade Ọlatẹru Ọlagbẹgi si jọba lẹyin rẹ.
ọba Ọlatẹru Ọlagbẹgi

Oríṣun àwòrán, Others

Ọba Oluwadare Adepoju Adesina, Deji tilu Akurẹ:

  • Isẹlẹ irọloye Ọba Oluwadare Adepoju Adesina ko tiẹ jinna rara. Osu Kẹfa ọdun 2010 ni ijọba ipinlẹ Ondo rọọ loye gẹgẹ bii Deji tilu Akure nitori pe o n aọkan lara awọn olori rẹ nita gbangba
  • Orukọ Olori naa ni Bolanle Adepoju Adesina, ẹniti aawọ waye laarin oun ati ọkọ rẹ, ti Deji naa si ni ki awọn ẹsọ to wa ni aafin naa ni anadojubolẹ, ta si gbọ pe oun gan da eroja olomi kan si lara, ti wọn pe ni asidi, eyi to mu ki ara obinrin naa bo yanna-yanna
  • Idi ree ti awọn afọbajẹ ilu Akurẹ fi pinnu pe oriade naa ko yẹ ni ipo ọwọ naa, ti wọn si le kuro lori itẹ.
Oba Oluwadare Adesina ati olori Bolanle

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹkọ ti itan manigbagbe yii kọ wa:

  • Itan manigbagbe yii lo n ran wa leti pe bi aye ba yẹ wa tan, ka mase hu iwa ibajẹ nitori igba ko tọ lọ bii orere, aye ko tọ lọ bii ọpa ibọn
  • Ninu itan yii, o to sba meji ti wọn padanu itẹ wọn nitori aawọ obinrin, eyi si yẹ ko kọ awọn eeyan nla nla, olowo, ọlọrọ, gbajumọ ati awọn ọdọ lọgbọn pe obinrin ko see foju kere nitori agbara to wa lọwọ wọn lee fa isubu ọkunrin

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

  • Bakan naa la kọgbọ pe ọpa ẹru, wọn maa n fi ni, ko si yẹ ki awọn ọba alaye ati awọn asaaju wa ro pe awọn ni alagbara to ga julọ nitori oni la ri, ko sẹni to mọ ọla, Ọlọrun nikan ni alagbara
  • Itan yii tun kọ wa gbe obiri laye, to ba lo siwaju, o tun lee lo sẹyin, saa si ni ẹda ni, ẹnikan ko nile aye.

Ju gbogbo rẹ lọ, itan manigbagbe yii kọ wa pe akọsilẹ awa ẹda, ko lee tase nitori aye ko lee pa kadara da, wọn kan lee fa ọwọ aago sẹyin ni, ko si si bo se buru fun wa to loni, igba to dara n bọ lọla.