Kí ló mú kí agbẹjọ́rò àgbà yọ ọwọ́ nínú ìgbẹ́jọ́ Dibu Ojerinde ọgá JAMB tẹ́lẹ̀?

Dibu Ojerinde

Oríṣun àwòrán, Insideoyo.com

Igbẹjọ ọga agba tẹlẹ fun ajọ eleto idanwọ igbaniwọle fasiti Naijiria JAMB ,Ọjọgbọn Dibu Ojerinde ti ri ifasẹyin diẹ pẹlu bi agbẹjọro Ojerinde ṣe ni oun ko ṣoju rẹ mọ.

Agbẹjọro agba Peter Olorunishola sọ pe ọrọ oun ni lati yanju awọn nkankan to ni ṣe pẹlu ọrọ owo ti Ojerinde ko ti san fun oun lo mu igbesẹ yi wa.

Lọjọ Kẹfa Oṣu Kẹfa ni wọn gbe Ojerinde lọ siwaju adajọ lori ẹsun onipele mejidinlogunto da lori pe o lu owo to le ni biliọnu marun un Naira ni ponpo.

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu lẹnu iṣẹ ijọba ICPC lo n ba ṣẹjọ yi ti wọn si fẹsun kan pe o ṣe aṣemaṣe lasiko to wa lori oye gẹgẹ bi ọga NECO titi di igba to tun fi di ọga JAMB.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Agbẹjọro ijọba Ebenezer Shogunle sọ niwaju adajọ pe awọn mu ẹlẹri mẹta wa sile ẹjọ ṣugbọn agbẹjọro Ojerinde Itieubong Usoroh to wa ṣoju agbẹjọro gangan Olorunishola sọ pe agbẹjọro agba naa ti kọwe sile ẹjọ pe oun ti yọ ọwọ ninu ẹjọ Ojerinde.

Olorunishola ṣalaye pe oun nilo asiko lati yanju ọrọ to niṣe pẹlu owo ooya rẹ ti Ojerinde ko ti san.

Usoroh ni nitori eleyi, oun fẹ beere asiko diẹ lọdọ adajọ ki awọn fi le yanju awọn ọrọ to wa nilẹ ki Olorunsihola baa le yọwọ ninu ẹjọ naa.

Shogunle to n ṣoju ijọba ni lootọ ni Ojerinde lẹtọ lati yan agbẹjọro to ba yan laayo ṣugbọn ki wọn ma ṣe lo anfaani yi ni ilokulo lati le fi mu idiwọ ba igbẹjọ naa.

Adajọ Obiora Egwuatu ninu idajọ rẹ loun faaye gba isunsiwaju ti agbẹjọro Ojerinde beere fun to si ni igbẹjọ yoo tẹsiwaju lọjọ Kẹjọ oṣu Kẹwaa.