Yahaya Bello pe Alága EFCC lẹ́jọ́, ó ló tàpá sí àṣẹ kóòtù lórí ọ̀rọ̀ oun

Yahaya Bello

Ile-ẹjọ giga kan ni Lokoja, ipinlẹ Kogi, ti paṣẹ pe ki Alaga ajọ to n ri si ajẹbanu lorilẹ-ede yii, EFCC, Ọla Olukoyede, yọju si kootu lati ṣalaye lori ẹsun ti Yahaya Bello, gomina Kogi tẹlẹ fi kan an.

Ọjọ kẹtala, oṣu karun-un ọdun 2024 yii ni kootu naa paṣẹ pe ki Olukoyede yọju.

Ẹsun ti Yahaya Bello n ka si Alaga EFCC lẹsẹ ni pe ile-ẹjọ ti paṣẹ fun un tẹlẹ pe ki wọn ma ti i gbiyanju lati mu oun rara.

O ni kootu ti paṣẹ pe o digba ti ipinnu ba waye lori igbesẹ naa lati ile-ẹjọ ti ọrọ ajẹbanu yii ti bẹrẹ.

Yahaya Bello sọ pe Olukoyede tapa si aṣẹ yii, EFCC ya bo ile oun laaarọ kutu ọjọ Kẹtadinlogun, oṣu kẹrin 2024.

Gomina tẹlẹ naa tun sọ pe gbogbo ohun ti EFCC danwo nile oun l’Abuja lọjọ naa lodi si aṣẹ kootu.

O ni titapa si aṣẹ ile-ẹjọ ni wiwa ti wọn wa naa.

”Nnkan bii aago mẹjọ aarọ ọjọ naa ni EFCC ko idaamu ba Yahaya Bello nilee rẹ l’Abuja”

Alaga EFCC, Ọla Olukoyede

Ajọ EFCC gbiyanju lati mu gomina Kogi tẹlẹ naa lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹrin yii lai wo ti aṣẹ kootu to ni ki wọn ma ti i gbe igbesẹ naa.

Ṣaaju ni kootu naa ti paṣẹ lọjọ kẹsan-an, oṣu keji ọdun 2024, pe ki EFCC ṣi ni suuru nipa mimu ti wọn fẹẹ mu Yahaya Bello.

Fun pe wọn tako eyi ni Yahaya Bello ṣe tun gba kootu lọ.

Nigba to n gbe idajọ kalẹ lọjọ Kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹrin yii, Adajọ I. A Jamil, paṣẹ pe ki Alaga EFCC waa ṣalaye idi rẹ to fi tako aṣẹ ile-ẹjọ.

O ni Olukoyede yoo ni lati ṣalaye idi ti ida ofin ko fi ni i ge e.

Igbẹjọ di ọjọ kẹtala, oṣu karun-un ọdun 2024 yii.

Iléèwé ilẹ̀ Amẹrika dá owó tí Yahaya Bello san fún ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ padà fún EFCC

Bi eyi ṣe n lọ lọwọ ni EFCC jẹ ko di mimọ, pe ileewe ilẹ Amẹrika ti Yahaya Bello sanwo si fun ẹkọ awọn ọmọ rẹ ti da owo naa pada.

Ẹka iroyin Punch to fi eyi lede, ṣalaye pe $760,000 owo ilẹ okeere ni awọn alaṣẹ ileewe naa da pada fun ajọ EFCC.

Agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale, fidi ẹ mulẹ pe American International School of Abuja, fi owo naa ranṣẹ lẹyin ti wọn beere alaye kikun lọwọ EFCC, ti ajọ naa si pese rẹ fun wọn.

O ni $845,852 ni owo ti Yahaya Bello san fun igbẹkọ awọn ọmọ rẹ gẹgẹ bi asansilẹ, eyi to bẹrẹ lọjọ keje, oṣu kẹsan ọdun 2021.

EFCC sọ pe ileewe naa loun ko le da gbogbo ẹ pada mọ nitori ẹkọ tawọn ọmọ naa ti jẹ anfaani ẹ.

Idi niyẹn ti wọn fi da $760,910 pada sọdọ EFCC.

Ipele keji si ikẹjọ ni awọn ọmọ Yahaya Bello wa nileewe oyinbo naa bi wọn ṣe sọ.

Ẹ o ranti pe Alaga EFCC lo tu aṣiri nipa owo yii lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ l’Abuja laipẹ yii.

Nibi to ti sọ fun pe gomina kan fẹẹ kuro lori aleefa, o si sare ko owo ijọba ipinlẹ rẹ gba ọdọ awọn abaniṣẹwo (Bureau de change lọ).

Owo naa lo ni o fi sanwo ileewe awọn ọmọ rẹ ni asansilẹ.

Ipinlẹ Kogi ni Olukoyede sọ pe gomina tẹlẹ naa ti huwa ọhun.

Bẹẹ ni gbogbo aye ṣe mọ pe Yahaya Bello ni.