Ọlọ́pàá Ogun àtàwọn ajínigbé dojú ìbọn kọ ara wọn lójú ọ̀nà Sagamu, dóòlà ọmọ India mẹ́ta

SP Odutola Omolola

Oríṣun àwòrán, SP Odutola Omolola

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti doola ọkunrin mẹta to jẹ ọmọ orilẹede India ti awọn agbebọn kan ji gbe lọju ọna marosẹ Sagamu si Benin.

Iroyin ni agbegbe Kajola ni awọn ajinigbe naa ti kọkọ ṣina ibọn bo ọkọ akero ti wọn wa ki wọn to ji wọn gbe, nigba ti awọn akẹgbẹ wọn to ku moribọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Odutola Omolola ni ọlọpaa ṣekupa meji lara awọn ajinigbe naa lasiko ti wọn kọju ija sira wọn.

O ni alaṣẹ ileeṣe Breeze Company Nigeria to wa loju ọna Ibadan si Eko lo pe DPO ọlọpaa to wa ni Mowe lọjọ kẹta, oṣu karun un, ọdun 2024 yii pe awọn agbebọn ṣina ibọn fun awọn ọga oun lasiko ti wọn n lọ sile wọn ninu ọkọ Toyota Haice meji.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn eeyan to wa ninu ọkọ ọhun to mẹrindinlogun lasiko ikọlu naa amọ awọn ẹṣọ alaabo to wa pẹlu wọn da ibọn pada fun awọn ajinigbe ọhun.

Bo tilẹ pe awọn kan moribọ, awọn ajinigbe naa ji ọmọ orilẹede India mẹta gbe lọ lara wọn.

Orukọ awọn ọkunrin mẹta ti wọn ji gbe naa ni Tejaram Chauhan, Kaduwal Pradhan ati Medani Kathiwada.

Eredi aṣeyọri awọn ajinigbe naa lati gbe awọn eeyan ọhun ko ṣẹyin bi ọkọ ti wọn wa ko ṣe ni ẹṣọ alaabo.

Ẹwẹ, nigba ti awọn alaṣẹ ileeṣe naa kan si ọlọpaa ipinlẹ Ogun ni Mowe, ọlọpaa kan lu igbo lẹyin ọjọ kẹrin ti wọn si n wa awọn ajinigbe naa.

Ibi ti wọn ti n wa wọn lawọn ajinigbe ọhun ti ṣina ibọn bole ti ọlọpaa naa si da pada fun wọn

Bi iro ibọn ṣe n dun lakọlakọ yii ni meji lara awọn agbebọn naa fara gbọta, ti ọlọpaa si doola awọn ti wọn ji gbe.

Lara awọn ohun ija oloro ti ọlọpaa ri gba lọwọ awọn ajinigbe naa ni ibọn AK47 meji, ibọn agbelẹrọ kan, ida kan, ẹrọ ilewọ, oogun abẹnugọngọ ati ọta ibọn marunlelọgọta.

Ọlọpaa tun ri owo ti iye rẹ to N7,900,000 gba lọwọ wọn, eyii ti igbagbọ wa pe o jẹ owo itusilẹ ti wọn gba lọwọ awọn ti wọn ji gbe ṣaaju.

Wayi o, ọlọpaa ti ko oku awọn ajinigbe to jade laye sile igbokusi, iwadii si ti bẹrẹ.