Ta ló tú ayédèrú dókítà tó gbẹ̀bí fún aláboyún tó kú sílẹ̀ lẹ́yìn táwọn agbófinró mú u nípínlẹ̀ Osun?

Aworan ile iwosan naa ati afurasi ọhun

Oríṣun àwòrán, BBC/screenshot

Ọwọ awọn agbofinro ti tẹ Ọladiti Saheed Toyin, ọmọ ọdun mejilelọgbọn to n fi iwe ẹri ile ẹkọ girama ṣe dokita ni ipinlẹ Ọṣun.

Ọwọ awọn oṣiṣẹ agbofinro abo ara ẹni labo ilu sifu difẹnsi tẹ Saheed Ọladiti lẹyin to ṣe iṣẹ abẹ fun alaboyun kan, ti alaboyun naa si ku lẹyin iṣẹ abẹ naa.

Amọ ṣa, bi a ṣe n sọrọ yii, Saheed ti gba itusilẹ laijẹ wi pe o fi oju ba ile ẹjọ fun ẹsun ti wọn fi kan an; koda bi a ṣe n sọrọ yii, o ti pada si ẹnu iṣẹ rẹ gẹgẹ bii dokita ni ile iwosan to da silẹ ni ilu Ọrọruwọ ni ipinlẹ Ọṣun.

Bawo ni Ọrọ ṣe jẹ gan lati ibẹrẹ?

Saheed da ile iwosan kan silẹ ni Ojule keji lagbegbe Lakewu, ni ilu Ọrọruwọ ni ipinlẹ Ọṣun

Saheed pe orukọ ile iwosan to da silẹ ni ilu Ọrọruwọ ni Ọlọruntoyin Clinic.

Iwe ẹri girama ni Saheed fi ẹnu ara rẹ sọ fun awọn akọroyin pe oun ni.

Yatọ si pe Saheed n fi aini iwe ẹri to tọ ṣe iṣẹ dokita, n ṣe lo tun n kọ awọn eeyan ni iṣẹ iṣegun oyinbo. Lasiko ti ọwọ ofin tẹ ẹ, ọmọ iṣẹ mẹfa lo wa labẹ rẹ ti wọn n kọ ẹkọ iṣegun oyinbo lati le mu ki awọn pẹlu di ‘dokita iṣegun oyinbo’ bii ti Saheed funrarẹ.

Ọga awọn Sifu Difẹnsi nipinlẹ Osun Michael Adaralewa salaye wi pe, Saheed Oladiti jẹ akẹkọọ jade ile Ẹkọ Girama, ti ko si tesiwaju mọ rara.

Michael Adaralewa ni fun ìyàlẹ́nu, Saheed Oladiti ni ile iwosan ara rẹ eleyi to ni o ni ijiya labẹ ofin iwa ọdaran ti orile-ede Naijiria n lo lọwọ.

Bawo ni iku alaboyun to ku ni ile iwosan Saheed ṣe jẹ

Aworan akọyinsi afurasi naa

Oríṣun àwòrán, screenshot

Alaboyun ni ibikunle Ọlanikẹ, ọrọ ibi alaafia lo ba lọ si ile iwosan Saheed Ọladiti ni ọjọ karundinlogun oṣu kẹrin ọdun 2024.

Ọlanikẹ ko le tẹsiwaju pẹlu eto itọju alaboyun ni ile iwosan to n lọ tẹlẹ lẹyin ti oun ati ọkọ rẹ ni ija.

Saheed ṣe ayẹwo ifunpa rẹ eyi to ni o ti n lọ silẹ nigba naa.

Lẹyin eyi o fun un ni awọn ogun kan lati lo, ki o si pada wa si ile iwosan naa ni kete ti o ba ti fẹ rọbi.

Ni ọjọ kejidinlogun, Ọlanikẹ bẹrẹ si ni ri ọwọ irora ibimọ, o si gba ile iwosan Saheed lọ. kete to bimọ naa tan ni nnkan ba yiwọ. Loju ẹsẹ ni oun si gbe digbadigba lọ si ile iwosan ti ìjọba, nibẹ ni wọn ti sọ fun oun pe o ti ku.

Ki ni awọn eeyan kan ni ilu Ọrọruwọ ko fẹ ko jade nipa Saheed ati ile iwosan rẹ?

Aworan ọga ajọ sifu difẹnsi ni ipinlẹ Ọṣun

Oríṣun àwòrán, screenshot

BBC Yoruba ba Saheed to yẹ ko wa ni ahamọ awọn agbofinro ni ile iwosan rẹ opada nibi to tun ti n ba iṣẹ lọ

Iyalẹnu lo jẹ fun BBC News Yoruba nigba ti ikọ wa de ilu Ọrọruwọ lati ri Ọgbẹni Saheed Ọladiti Toyin ti awọn agbofinro fi oju rẹ han ni ọjọ diẹ sẹhin , ni ile iwosan naa.

Ni kete to kẹfin pe oniroyin ni lo ba fariga to si pe awọn janduku mẹta pe ki wọn le akọroyin BBC to lọ sibẹ jina rere.

Saheed funra rẹ ni oun ko ni ọrọ kankan lati sọ ayafi ti kabiyesi ilu Ọrọruwọ, Ọba Kamarudeen Adeyẹmi.

Gbogbo ohun ti oju aṣojukọroyin BBC News Yoruba ri ni ilu naa fihan pe Kabiyesi atawọn eeyan ninu ilu naa ko fi gbgobo ara fara mọ iṣẹ iwadii ti BBC News Yoruba wa ṣe nibẹ.

To ba ri bẹ, Ki ni Kabiyesi atawọn eeyan ilu Ọrọruwọ n da ọwọ bo lara Saheed, ayederu dokita yii to yẹ ko wa lahamọ awọn agbofinro fun iwadii ipaniyan?

Gbogbo ẹrọ ibanisọrọ aṣojukọroyin BBC News Yoruba ni wọn gbọn wo yẹbẹyẹbẹ lati mọ boya o ya fidio tabi aworan kankan nipa Saheed ati ile iwosan rẹ.

Ọba Kamarudeen Adeyẹmi sọ ninu ọrọ rẹ wi pe, oun ko fẹ ki ẹnikẹni ko tun gbe iroyin lori Isẹlẹ naa mọ. Bi ẹnikẹni ba tun gbe iroyin oun yoo pe iru Ilésẹ bẹ naa lẹjọ ati pe iru ẹni to ba tun kọ iroyin nipa iṣẹlẹ naa yoo fi iku se fa jẹ.

Bawo ni Saheed ti agbofinro ṣe afihan rẹ ṣe gba itusilẹ?

Aworan ile iwosan naa

Riri ti aṣojukọroyin BBC News Yoruba tun ri Saheed ti gbogbo aye ro wi pe o wa lahamọ awọn agbofinro to n yan fandafanda kiri ilu Ọrọruwọ lẹyin ti ẹsun lilọwọ ninu iku alaboyun to wa bimọ lọdọ rẹ ṣi wa nilẹ lo mu ki a pada kan si alukoro ileeṣẹ sifu difẹnsi ni ipinlẹ Ọṣun pe bawo lọrọ tun ṣe jẹ?

Alukoro ileeṣẹ sifu difẹnsi ni ipinlẹ Ọṣun naa fi iyalẹnu han pe Saheed ti awọn mu ti gba itusilẹ pada si inu ohun gan ti wọn titori rẹ fi oju rẹ jhan fun araye.

O ṣalaye pe ni kete ti wọn mu afurasi naa ti wọn si ti fi oju rẹ ati iṣẹ laabi ti wọn n fi sun nipa rẹ lede ni wọn taare rẹ si ọdọ ileeṣẹ eto iṣedajọ ni ipinlẹ Ọṣun fun igbesẹ ati fi afurasi naa jẹjọ ni ibamu pẹlu ilana ofin.

Ninu iwe ti wọn kọ lati fi afurasi naa ranṣẹ eyi ti ọga agba ajọ sifu difẹnsi ni ipinlẹ Ọṣun, Adaralẹwa Michael fi ọwọ si, “gbe iwe ẹsun rẹ ṣọwọ si offisi” ileeṣẹ eto idajọ “lati bẹrẹ ipẹjọ rẹ”

Bi Saheed ṣe wa kuro ni ahamọ pada si ilu Ọrọruwọ laijẹjọ ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an lo ṣi jẹ kayeefi bayii.

Ṣe ka pe eyi ni atubọtan ijakulẹ awọn alamojuto eto ilera ni?

Inu ile iwosan Oluwatoyin

Ọrọ Ayederu dokita kii ṣe tuntun mọ lẹka eto ilera lorilẹede Naijiria. Amọ ohun to n jọ ọpọ loju ni bi awọn eeyan to n lọwọ ninu iwa yii ṣe n ni igboya lati ṣe iṣẹ wọn ni gbangba lainaani ohun ti awọn agbofinro, awọn ẹgbẹ dokita tabi ijọba le ṣe.

BBC News Yoruba kan si ẹgbẹ awọn Dokita nipinlẹ Ọsun lati mọ ohun ti wọn n ṣe lati ri i pe awọn kanda ninu irẹsi laarin awọn dokita iṣegun Oyinbo paapaa awọn to n fi ayederu iwe ẹri da ẹmi araalu lẹgbodo.

Dokita Ayodeji Ogungbemi ẹni to soju fun alaga ẹgbẹ awọn Dokita salaye wi pe, lọtitọ ni awọn gbọ si Isẹlẹ naa, ti iwadi awọn si fi múlẹ̀ wi pe, ayederu Dokita ni Saheed Oladiti.

Dokita Ayodeji Ogungbemi wa fi da gbogbo ara ilu loju wi pe, awọn yoo ri wi pe ile iwosan naa yoo di titi pa ati gbogbo ile iwosan to jẹ ayederu lapapọ.

Sugbọn ni bayi awọn ẹgbẹ Dokita nipinlẹ Osun ti dìde si Isẹlẹ naa lati ri wi pe, gbogbo awọn to jẹ ayederu Dokita ni awọn yoo fa le ijọba lọwọ lia pẹ yii.

Dokita Ayodeji wa rọ awọn ara ilu kọọkan lati sọra daada lati le mọ ko si ọwọ awọn ayederu ile iwosan ati Dokita.

Ko si orukọ ile iwosan ‘Oluwatoyin Clinic’ ninu awọn ile iwosan to forukọ silẹ ni ipinlẹ Ọṣun – Kọmiṣọna fun eto ilera ni ipinlẹ Ọṣun

Inu ile iwaosan naa

Jola Akintola ẹni to jẹ Komisanna fun eto ilera nipinlẹ Osun salaye Isẹlẹ naa bi oun to buru ati oun ti ko yẹ ko mọ sẹlẹ lawujọ.

Bawo ni ẹni ti ko jade iwe girama se le ni ile iwosan. O jẹ oun to ku diẹ Kato gidigidi. Oun iyalẹnu nla lo jẹ fun mi nigba ti mo gbọ Isẹlẹ naa.

Nigba ti a se ayẹwo awọn ile iwosan aladani to fi orukọ silẹ nipinlẹ Osun, ko si orukọ ile iwosan ayederu Dokita Oladiti Saheed nibẹ rara.

Eleyi tumọ wi pe, otitọ ni iwadi awọn agbofinro ti wọn fi oju ayederu Dokita Oladiti Saheed lede.

Jola Akintola tun salaye siwaju si wi pe, ki awọn Sifu Difẹnsi ko tun bọ tẹra mọ iwadi naa daada ati wi pe, ki wọn gbe ẹjọ naa dele ẹjọ nitori iru awọn to ku lẹyin n to se iru isẹ bẹ le kọọgbọn ati ki awọn ara iluu gbogbo le mọ awọn ayederu Dokita ati ile iwosan.

O ni Iseijọba Gomina Ademola Adeleke ko ni fi aye gba iwa buruku bayi rara.