Wo ìdí tí ìjọba yóò ṣe máa fi ọlọ́pàá gbé àwọn olókòwò POS kan

Aworan POS

Oríṣun àwòrán, CAC/X

Ijọba apapọ ti kede pe awọn ọlọpaa yoo maa gbe awọ olokowo ẹrọ igbowo POS to ba kọ lati fi orukọ silẹ pẹlu ajọ CAC ọrọ idasilẹ ileeṣẹ ni Naijiria.

Ijọba ṣalaye pe iforukọsilẹ awọn olokowo POS yoo ṣe iranwọ fun ijọba lati ṣe adinku iṣẹlẹ ijinigbe tori yoo ran awọn ẹṣọ eleto aabo lọwọ lati le maa mu awọn to n gba owo itusilẹ lọwọ awọn eeyan ti wọn jigbe.

Ọjọ keje oṣu Keje ni gbedeke ọjọ ti ijọba fun gbogbo awọn olokowo POS da lati ṣe iforukọsilẹ pẹlu ajọ CAC.

Ọgagba ajọ CAC, Hussaini Magaji lo fidi ọrọ yii mulẹ nibi ifilọlẹ iforukọsilẹ awọn aṣoju ati olokowo ile ifowopamọ ori ayelujara niluu Abuja ni Ọjọru.

Ni ọjọ Aje to kọja ni ijọba kede pe gbogbo awọn olokowo POS gbọdọ forukọsilẹ pẹlu alakalẹ banki apapọ Naijiria, CBN.

Igbesẹ yii tun waye lati gbogun ti jibiti tawọn eeyan kan lu pẹlu ẹrọ POS atawọn to n lo POS fun kara-kata owo ‘’crypto.’’

Akọsilẹ ajọ to n ri si aawọ laarin awọn banki Naijiria fihan pe ida 26.37% ninu 100% ninu jibiti to wa ni akọsilẹ lọdun 2023 lo waye lori POS.

Ni ọsẹ to kọja ni banki CBN da awọn ile ifowopamọ ori ayelujara bii Kuda, Opay, PalmPay ati Moniepoint duro wi pe ki wọn ma gba onibaara tuntun mọ.

Skip Twitter post

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

Ogagba ajọ CAC tun sọ nipa ipinnu ijọba lati sọ awọn ile ifowopamọ di eyi to n lo ayelujara daadaa.

Ọgbẹni Hussaini ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe ijọba ko ni ṣe afikun oṣu meji to fawọn olokowo POS lati ṣe iforukọsilẹ wọn.

Ajọ CAC ni awọn ṣetan lati ṣe iranwọ fun ẹnikẹni to ba ni iṣoro kan tabi omiran ninu awọn olokowo POS nipa iforukọsilẹ wọn.

Ogagba ajọ CAC ni igbesẹ yii kii ṣe nitori eeyan kan tabi ẹgbẹ kankan, ṣugbọn o wa fun anfani olokowo POS atawọn atawọn onibara wọn bakan naa.