Kí ni nǹkan tí àwọn èèyàn tó fẹ́ kú máa ń rí lásìkò tí wọ́n bá fẹ́ kú?

Obìnrin aláàárẹ̀ kan ní orí bẹ́ẹ̀dì pelu won eeyan kan

Oríṣun àwòrán, Christopher Kerr

Ní oṣù Kẹrin ọdún 1999, Dókítà òyìnbó ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan, Christopher Kerr rí ìrírí kan tó mú àyípadà bá iṣẹ́ rẹ̀.

Ọ̀kan lára àwọn aláàárẹ̀ tó ń tọ́jú wà lórí ibùsùn tó ti ń gba ìtọ́jú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rin.

Lásìkò tí Mary ń pọ̀kàkà ikú ló bẹ̀rẹ̀ sí ní hu àwọn ìwà tó yani lẹ́nu, tó sì ń dẹ́rù bani.

Ìyá ẹni àádọ́rin ọdún nígbà náà dìde jókòó bí ẹni tó gbé ọmọ tí ẹnikẹ́ni kò rí lọ́wọ́, tó sì ń bá a ṣeré. Ó pe orúkọ ọmọ náà ní Danny.

Àwọn ọmọ ìyá náà kò lè ṣàlàyé nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí ìyá wọn nítorí wọn kò mọ ẹnikẹ́ni tó ń jẹ́ Danny rí.

Nígbà tó di ọjọ́ kejì tí àbúrò Mary yọjú sí ilé ìwòsàn sọ pé Mary ti kọ́kọ́ bí ọmọ kan tó ń jẹ́ Danny ṣáájú kó tó bí àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù àmọ́ tí ọmọ náà jáde láyé lẹ́yìn tí wọ́n bi tán.

Ó ní ikú ọmọ náà dun Mary débi wí pé kìí sọ̀rọ̀ ọmọ náà mọ́ láti ìgbà náà.

Kerr, tó jẹ́ onímọ̀ nípa àìsàn ọkàn, rí ìṣẹ̀lẹ̀ náà bí ohun tó jọnilójú, tó sì pinnu láti ṣe àyípadà ohun tó yàn láàyò padà sí ṣíṣe ìwádìí lórí àwọn tí wọ́n bá ti ń pọ̀kàkà ikú.

Iya ati omo dimo ara won lori ibusun ile iwosan

Oríṣun àwòrán, Plan Shoot / Imazins / Getty Images

Ṣíṣe àwárí àláfíà

Ní báyìí, lẹ́yìn ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tí Kerr ti pàdé Mary, ó wà lára àwọn onímọ̀ tó ń léwájú nínú àwọn tó ń ṣe ìwádìí àwọn ìran àti àlá tí àwọn tó wà ní bèbè pípàdánù máa ń rí nígbà tí wọ́n bá ń súnmọ́ àkókò tí ọlọ́jọ́ bá dé tán.

Ó ní ìrírí yìí máa ń bẹ̀rẹ̀ bí i ọ̀sẹ̀ díẹ̀ fún ẹni tí ẹ̀mí rẹ̀ fẹ́ bọ́, tó sì máa ń pọ̀ si lásìkò tí ikú bá ti súnmọ́ tán fún wọn.

Kerr ní òun ri bí àwọn tó ń pọ̀kàkà ikú ṣe máa ń sọ pé àwọn rí àwọn èèyàn wọn tó ti kú ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn tí àwọn sì jọ ń sọ̀rọ̀.

Fún àwọn kan, àwọn ìran kan jẹ́ ohun tó máa ń mú àláfíà bá ọkàn won.

Kerr sọ fún BBC News Brasil pé ọ̀pọ̀ àwọn tó bá ń pọ̀kàkà ikú ló máa ń rí àwọn tí wọ́n ti jọ ní àjọṣepọ̀ rí, tí wọn yóò sì tún jọ máa ṣe lọ́nà tí yóò mú àláfíà bá ọkàn wọn.

Ó ní àwọn ìrírí yìí máa ń dín ẹrù ikú kù lọ́kàn wọn.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn yìí ló mọ ohun tí wọ́n ń rí, tí àwọn nǹkan tí wọ́n sì ń sọ yé wọn dáadáa nítorí ẹ̀mí wọn ṣì dúró digbí bí ó tilẹ̀ àláfíà ara wọn kò pé mọ́.

Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn Dókítà ló máa ń sọ pé àwọn èèyàn náà ń ṣìrànrán àti pé ìwádìí tó rinlẹ̀ gbọ́dọ̀ wáyé kí a tó lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bẹ́ẹ̀.

Èyí ló mú kí Kerr bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lọ́dún 2010 ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà láti máa béèrè lọ́wọ́ àwọn aláàárẹ̀ tó ti ń pọ̀kàkà ikú nípa àwọn nǹkan tí wọn ń rí.

Christopher Kerr n rerin-in

Oríṣun àwòrán, Christopher Kerr

Gbogbo àwọn aláàárẹ̀ tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ ni wọ́n ṣe àyẹ̀wò fún láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀rọ̀ kò dàrú mọ́ wọn lójú.

Ṣáájú ìwádìí yìí, àwọn èèyàn ló máa ń gbẹ́nu aláàárẹ̀ tó ti wà ní bèbè ikú sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí wọn ń rí tí wọ́n sì ti ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀ sínú ìwé tó fi mọ́ National Library of Medicine ti Sweden.

Kerr kò le sọ ní pàtó ohun tó ń fa ìrírí yìí àti pé ìwádìí ohun tó ń fà á kọ́ ni iṣẹ́ òun dálé lórí.

“Pé mi ò lè sọ ohun tó ń fà á àti bí ó ṣe ń wáyé kò túmọ̀ sí pé àwọn aláàárẹ̀ kìí ní ìrírí yìí.”

Kerr ti di adarí iléeṣẹ́ kan tó ń pèsè ìtọ́jú ní Buffalo, New York.

Ìwé rẹ̀, Death Is But a Dream: Finding Hope and Meaning at Life’s End, ni wọ́n tẹ̀ jáde ní ọdún 2020 tí wọ́n sì ti tú u sí èdè mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Noosi mu alaaare kan dani ni ile iwosan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ó bá BBC News Brasil sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìwádìí rẹ̀ ati nǹkan tí àwọn ìrírí ìkẹyìn ẹ̀dá túmọ̀ sí.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìrírí rẹ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tó ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí yìí, Kerr ní ikú kọjá òye nǹkan tí èèyàn ń rí ní òkèrè tàbí ara lọ, ó máa ń ṣe àyípadà bí èèyàn ṣe ń rí nǹkan.

“Ikú máa ń mú kí èèyàn ní ìrònújinlẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń gbájúmọ́ àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì sí wọn, ohun tí wọ́n gbéṣe, tó sì máa ń jẹ́ àjọṣepọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn èèyàn lọ́pọ̀ ìgbà.

“Ó máa ń wáyé lọ́nà tó tuni lọ́kàn nípa ìgbé ayé tí èèyàn ti gbé rí, tó sì máa ń dín ẹ̀rù ikú kù lọ́kàn.

“A rí ọ̀pọ̀ tó gba ìfẹ́ láàyè lásìkò tí wọ́n ń pọ̀kàkà ikú.”

Ó ní ìwádìí àwọn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé méjìdínláàdọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn ló ní ọ̀kan nínú àwọn ìrírí náà.

Ó ṣàlàyé pé bí ojúmọ́ ṣe ń mọ́ ni ìhùwàsí àwọn ènìyàn yìí máa ń yàtọ̀ pàápàá bí ọlọ́jọ́ bá ṣe ń súnmọ́ sí.

Awon dokita ati alaaare ní orí bẹ́ẹ̀dì ile iwosan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìrìnàjò

Kerr ni ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn ènìyàn tí àwọn bá sọ̀rọ̀ ló sọ̀rọ̀ nípa ìrìnàjò. Ọ̀pọ̀ wọn ló máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àtàwọn tí wọ́n ti pàdánù.

“Rírí àwọn ènìyàn wọn tó ti jáde láyé máa ń pọ̀ si bí ọjọ́ ikú wọn bá ṣe ń súnmọ́ sí. Wọ́n ní èyí ló máa ń tu àwọn lọ́kàn jùlọ.”

“Àwọn tí wọ́n máa ń rí lójú àlá náà jẹ́ ohun tó máa ń wáyé lọ́pọ̀lọpọ̀ fún wọn, tí wọ́n sì máa ń gbájúmọ́ àwọn èèyàn tó ṣe àtìlẹyìn fún wọn. Ó lè jẹ́ òbí tàbí àwọn ọmọ ìyá ènìyàn.

“Ìdá méjìlá ni àwọn tí wọ́n sọ pé àlá tí àwọn ń lá kò tuni lọ́kàn rárá.

“Gbogbo egbò tí èèyàn bá dì sọ́kàn ni èèyàn máa ń yanjú ní àsìkò yìí.

Bákan náà ló fi kun pé àwọn tí kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe pàápàá ní ìgbẹ̀yìn ayé náà wà àmọ́ kò papọ̀ pẹ̀lú àwọn tí àwọn ṣe ìwádìí rẹ̀ yìí.

Agbalagba kan ní orí bẹ́ẹ̀dì ile iwosan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àlá

Ọkùnrin kan ní orí bẹ́ẹ̀dì

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kerr ṣàlàyé pé àwọn ènìyàn kan sọ pé ojú àlá ni àwọn ìrírí yìí ti máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí àwọn mìíràn sì ní ojú ayé gan ló ti ṣẹlẹ̀.

Ó ní lásìkò tí èèyàn bá ń pọ̀kàkà ikú, wọ́n máa ń sùn fún ọ̀pọ̀ wákàtí tí wọn kò sì ní mọ ìgbà tàbí bí àkókò ṣe ń lọ.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìyàtọ̀ bí àwọn ọmọdé àti àgbà ṣe máa ń rí àwọn àsìkò tí wọ́n bá ti ń wà ní ìgbẹ̀yìn ayé wọn sí, ó ní àwọn ọmọdé ló máa ń sọ nípa ìrírí wọn yìí jùlọ.

Ó ní àwọn ọmọdé kò ní àṣírí tàbí fi ọ̀rọ̀ sí abẹ́ ahọ́n sọ, wọ́n kàn máa ń sọ ohun gbogbo tí wọ́n rí.

Obìnrin aláàárẹ̀ kan ní orí bẹ́ẹ̀dì

Oríṣun àwòrán, Getty