Bàbá mi Ogunjimi ti máa ń fi gbogbo ìgbà múra sílẹ̀ de ikú- Ismailia ọmọ olóògbé

Aworan Ogunjimi

Oríṣun àwòrán, City Mirror

Ismailia Akinpelu to jẹ akọbi oloogbe Ganiyu Akinpelu ẹni tí ọpọ eeyan mọ sí Ogunjimi ti se apejuwe Baba rẹ gẹgẹ bi eeyan rere ati ẹni to ni ifẹ ẹbi ati gbogbo eeyan.

“Baba mi Ganiyu Akinpelu jẹ eeyan takuntakun ninu ẹgbẹ osere tiata ati ninu ilu.

Bakan naa ni baba mi jẹ ẹni ń to maa n fi igba gbogbo mura silẹ de ọjọ iku.

Mi ko mọ wi pe iku le pa baba mi Ogunjimi lakooko yi rara.

O ti to osu Mẹta ti Baba mi ti wa lori idubulẹ aisan sugbọn ti ara wọn ti ya ki awẹ musulumi ko to bẹrẹ awẹ.

Sugbọn ọsẹ meji sẹyin ni aisan naa tun bere ti a si gbe wọn pada lọ sile iwosan.

A fi bi mo se gbọ iku Baba mi loni ọjọ kẹrindinlogbon osu Kerin ọdun 2024 yii,” Ismaila lo sọ bẹẹ.

Adijatu Akinpelu iyawo akọkọ fun ologbo Ogunjimi ti salaye iru eeyan ti ọkọ wọn jẹ, o ni Ogunjinmi jẹ eeyan daada ati ẹni to mọ itọju obinrin gidigidi ati oni suuru eeyan.

“Bi mo ba tun aye wa, eeyan bi ọkọ mi Ganiyu Akinpelu Ogunjimi ni mo ma tun yan bi ọkọ.”

Adijatu tun ṣe apejuwe oloogbe Akinpelu gẹgẹ bi eni to ni ifẹ ati inu rere si gbogbo ẹbi, ọrẹ ati awọn ẹgbẹ osere tiata lapapọ.

“Iku ọkọ mi jẹ ọfọ ati adanu nla fun mi ati awọn ọmọ to fi silẹ lọ.”

Rufia Oyeyemi Akinpelu to jẹ ẹgbọn fun Ologbe Ogunjimi naa se apejuwe iru eeyan ti oloogbe naa jẹ.

Rufia Oyeyemi ni adanu ni iku aburo oun Ogunjimi jẹ fun oun ati awọn to ku lẹyin oun patapata.

“Aburo mi jẹ akinkanju ati oni suuru eeyan ati ẹni to ko ẹbi mọra to si ni otitọ ni gbogbo irinajo rẹ.

O ni kii se osere tiata nikan ni iku n pa rara. Maruf Olayiwola ẹni to jẹ gomina fun ẹgbẹ osere TAMPAN ni Ìpínlẹ̀ Osun, Maruf Olayiwola ti salaye wi pe, ki se ẹgbẹ osere tiata nikan ni iku ń pa, sugbọn “a bẹ Ọlọrun ko ba wa da ọwọ rẹ iku duro lori ọmọ ẹgbẹ osere tiata lapapọ.”

Olayiwola wa rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ osere tiata lapapọ lati maa fi aye silẹ fun ìsinmi ara wọn ki wọn si maa se ayewo ara wọn deedee.

Ologbe Ganiyu Akinpelu Oyeyemi ẹni ti gbogbo eeyan mọ sí Ogunjimi lo ọdun mẹrindinladorin laye.

Ologbe naa fi aya meji ati awọn ọmọ saye lọ.

Gbajúgbajà òṣèré tíátà Ogunjimi Ajagajígì oògùn jáde láyé

Aworan Ogunjimi

Oríṣun àwòrán, Kunle Afod/Instagram

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajo yajo lo sọ pe gbajugbaja oṣere tiata un ni, Ganiyu Oyeyemi ti ọpọ mọ si Ogunjimi ti jade laye.

Ọkan lara awọn ilumọọka oṣere tiata, Kunle Afodu lo fi iroyin naa lede loju opo Instagram rẹ.

Skip Instagram post

Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Content is not available

View content on InstagramBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

Afod sọ ninu ọrọ to kọ soju opo Instagram rẹ pe ‘’a gbiyanju agbara wa, ṣugbọn Ọlọrun fẹ ọ ju.

Ki Eleduwa tẹ ẹ si afẹfẹ rere, Baba Ogunjimi, sun un re ooo.’’

A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin laipẹ.