‘Ìjọba Saudi fún àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láṣẹ láti máa pa ènìyàn torí ìlú tuntun tí wọ́n fẹ́ kọ́’

The Line

Oríṣun àwòrán, Shutterstock

  • Author, By Merlyn Thomas & Lara El Gibaly
  • Role, BBC Verify and BBC Eye Investigations

Àwọn aláṣẹ orílẹ̀ èdè Saudi Arabia ti pàṣẹ lílo ọwọ́ agbára láti fi gba ilẹ̀ kan èyí tí wọ́n fẹ́ fi kọ́ ìlú kan.

Òṣìṣẹ́ ètò ààbò tẹ́lẹ̀ rí kan ní Saudi sọ fún BBC pé àwọn iléeṣẹ́ ńlá ilẹ̀ òkèrè ló fẹ́ ṣe agbátẹrù kíkọ́ ìlú náà.

Ọ̀gágun Rabih Alenezi ní wọ́n pàṣẹ fún òun láti lé àwọn ará ìlú ẹ̀yà kan kúrò ní ìpínlẹ̀ Gulf láti fi ààyè gba kíkọ́ ìlú náà, tó jẹ́ ọ̀kan lára iṣẹ́ àkànṣe Neom eco-project.

Ọ̀kan lára àwọn ará ìlú náà tó yarí pé òun kò ní kúrò ní ilé òun ni wọ́n yìnbọn fún tó sì pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lójú ẹsẹ̀.

Ìjọba Saudi Arabia àti àwọn aláṣẹ Neom kọ̀ láti sọ ohunkóhun lórí ẹ̀sùn yìí.

Neom, ìlú kan tí ìjọba Saudi Arabia ń gbèrò láti fi $500bn kọ́, wà lára èrò Saudi láti gbé ètò ọrọ̀ ajé gba ibòmíràn kúrò ní epo rọ̀bì tó bá máa fi di ọdún 2030.

Ìlú náà, tí èrò wà pé wọn kò ní máa lo ọkọ̀ níbẹ̀, máa fẹ̀ ní igba mítà tó sì máa gùn ní kìlómítà àádọ́sàn-án.

Kìlómítà 2.4 ni ìjọba Saudi ní ó máa parí ní ọdún 2030.

Aworan to n safihan bi ilu naa yoo se ga ati gun to

Àwọn iléeṣẹ́ ńlá ńlá, tí ọ̀pọ̀ wọn jẹ́ iléeṣẹ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ló lọ́wọ́ nínú kíkọ́ Neom.

Ọmọọba Saudi, Mohamed bin Salman júwe ibi tí wọ́n fẹ́ kọ́ Neom sí gẹ́gẹ́ bí ààyè tó dára jùlọ fún iṣẹ́ àkànṣe náà.

Ìjọba ní ènìyàn tó lé ní 6,000 ni wọ́n ti kúrò ní agbègbè tí wọ́n fẹ́ kọ́ ìlú náà sì àmọ́ ikọ̀ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn UK kan, ALQST ní àwọn ti àkànṣe iṣẹ́ náà ṣe ìpalára fún jù bẹ́ẹ̀ lọ.

BBC ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn abúlé mẹ́ta tí wọ́n ti wó – al-Khuraybah, Sharma àti Gayal. Ilé ìgbé, ilé ẹ̀kọ́ àtàwọn ilé ìwòsàn ni wọ́n ti parun fún ìlú tuntun náà.

Ọ̀gágun Alenezi tó ń ṣe àtìpó ní UK láti ọdún tó kọjá ní ìlú al-Khuraybah tó wà ní kìlómítà 4.5 ẹkùn gúúsù ìlú náà ni ìjọba pàṣẹ pé kí àwọn ló ọwọ́ agbára láti lé kúrò. Àwọn ẹ̀yà Huwaitat, tó ń gbé ní ẹkùn Tabuk fún ọ̀pọ̀ ọdún ló pọ̀ jù níbẹ̀.

Ó ní àṣẹ tí ìjọba fún àwọn ní oṣù Kẹrin ọdún 2020 ní àwọn Huwaitat ló kún fún ọlọ́tẹ̀ àti pé ẹnikẹ́ni tó bá kọ̀ láti kúrò ní ilé rẹ̀ ni kí wọ́n pa.

Ó ní òun kò lọ fún iṣẹ́ pẹ̀lú àlàyé pé òun ní ìpèníjà ìlera àmọ́ iṣẹ́ náà lọ nítorí ẹlòmíràn ló lọ ṣe é.

Abdul Rahim al-Huwaiti kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn ìgbìmọ̀ láti iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ wọn iye tí ilé rẹ̀ tó wò, àwọn aláṣẹ Saudi sì yìnbọn pá ní ọjọ́ kejì nígbà tí lọ wó àwọn ilé níbẹ̀.

Abdul Rahim ti ṣáájú fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ fídíò sórí ayélujára láti fi tako bí wọ́n ṣe fẹ́ lé wọn kúrò ní ilé.

Àtẹ̀jáde tí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò Saudi fi síta nígbà náà ní Abdul Rahim gbèrò láti yìnbọn mọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ni kí wọ́n tó yìnbọn fún un láti dá ààbò bo ara wọn àmọ́ àwọn Ajàfẹ́tọ̀ọ́ àti àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN ní nítorí pé Abdul Rahim kò fẹ́ kí wọ́n lé òun nílé ni wọ́n ṣe yìnbọn pá.

BBC kò ríbi fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ ni nǹkan tí Ọ̀gágun Alenezi sọ lórí lílo ipá fi mú àwọn ènìyàn.

Àmọ́ ènìyàn kan tó mọ̀ nípa ìdarí iléeṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Saudi ní nǹkan tí Ọ̀gágun Alenezi sọ kò yàtọ̀ sí ohun tí àwọn mọ̀.

Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé àti ALQST ní àwọn ará ìlú 47 míì tí kò fẹ́ fi ilé wọn sílẹ̀ ni wọ́n fi sí àhámọ́, tí wọ́n sì ka àwọn ẹ̀sùn tó rọ̀ mọ́ ìgbéṣùmọ̀mí sí wọn lọ́rùn.

ALQST ní àwọn márùn-ún ni wọ́n ti dájọ́ ikú fún báyìí, tí àwọn ogójì ṣì wà ní àhámọ́.

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ní àwọn mìíràn ni fi sí àhámọ́ pé wọ́n ṣe,ìdárò ikú Abdul Rahim lórí ayélujára.

Ìjọba Saudi ní gbogbo àwọn tí wọ́n kúrò ní ìlú náà ni àwọn ti fún ní owó gbà má bínú ṣùgbọ́n ALQST ní owó tí wọ́n fún wọn kéré sí iye tí wọ́n ṣèlérí láti fún wọn.

Ọ̀gágun Alenezi ní Mohamed Bin Salman ló ni èrò láti kọ́ Neom, pé ìdí nìyí tó fi fọwọ́ líle mú àwọn Huwaitat.

Col al-Enezi

Ọ̀gá àgbà tẹ́lẹ̀ rí níbi iṣẹ́ àkànṣe Neom sọ fún BBC pé òun ti gbọ́ nípa ikú Abdul Rahim al-Huwaiti ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn kí òun tó gba iṣẹ́ náà ní ọdún 2020. Andy Wirth ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni òun béèrè lọ́wọ́ àwọn tó gba òun síṣẹ́ nípa àwọn tí wọ́n lé kúrò ní ilé wọn àmọ́ òun kò gbọ́ èsì gidi kankan.

Kò pé ọdún kan tó fi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ náà.

Adarí iléeṣẹ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan, Solar Water PLC ní kò yẹ kí wọ́n lé àwọn àwọn ará ìlú náà kúrò pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé àwọn ni wọ́n mọ àludé àti àpadé gbogbo àgbègbè náà.

Àwọn ará ìlú tí wọ́n lé kúrò ní ilé wọn kò fẹ́ bá akọ̀ròyìn wá sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù pé ó lè ṣàkóbá, pàápàá fún àwọn ènìyàn àwọn tó ṣì wà ní àhámọ́.

Ṣùgbọ́n a bá àwọn ènìyàn míì tí wọ́n kò kúrò ní ìlú ti wọn náà lọ sí ibòmíràn lórí àkànṣe iṣẹ́ míì tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́.

Kò dín ní mílíọ̀nù kan èèyàn tí wọ́n kó kúrò ní ilé wọn láti fi ààyè gba àkànṣe iṣẹ́ Jeddah Central Project.

Nader Hijazi [kìí ṣe orúkọ rẹ̀ gangan] dàgbà sí ìlú Aziziyah, ọ̀kan lára àwọn ìlú 63 tí wọ́n wó náà. Ó ní kò pé oṣù kan tí wọ́n sọ fún àwọn pé àwọn máa wó ilé náà tí ìjọba fi wo lọ́dún 2021.

“Wọ́n ń gbógun ti àwọn ènìyàn, wọ́n ń gbógun ti ẹ̀yà wa.”

Àwọn Ajàfẹ́tọ̀ọ́ Saudi ní èèyàn méjì ni wọ́n fi sí àhámọ́ ní ọdún tó kọjá lórí ilé wíwò ní Jeddah – ọ̀kan nínú wọn pé kò fẹ́ kí wọ́n wó ilé òun, èkejì pé ó ń fi àwọn àwòrán tó lòdì sí wíwò àwọn ilé náà sórí ayélujára.

ALQST ní nínú èèyàn 35 tí wọ́n wó ilé wọn ní Jeddah ní ìjọba kò ì tíì fún àwọn ní àjẹmọ́nú kankan, àti pé àsìkò tí wọ́n fún àwọn láti kúrò kéré púpọ̀, wọ́n ní ó dàbí pé wọ́n fi ipa lé àwọn nílé àwọn ni.

Aworan to n safihan The Line

Ní orílẹ̀ èdè UK ni Ọ̀gágun Alenezi ń gbé báyìí àmọ́ tó ṣì ń páyà lórí ààbò rẹ̀. Ó ní òṣìṣẹ́ ààbò kan pé òun láti kópa níbi ìpàdé kan pẹ̀lú Mínísítà fọ́rọ̀ abẹ́lé Saudi ní iléeṣẹ́ Saudi to wá ní ìlú London pé wọ́n máa fún òun ní $5m àmọ́ ó kọ̀ láti lọ.

Ìjọba Saudi kọ̀ láti sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn yìí nígbà tí a bi wọ́n.

Ṣíṣe ìkọlù sí àwọn tó bá ń tako ìjọba Saudi kìí ṣe ohun tuntun, àwọn òṣìṣẹ́ Saudi ṣekúpa akọ̀ròyìn tó ń gbé ní Amẹ́ríkà, Jamal Khaahoggi sí iléeṣẹ́ Saudi tó wà ní Instabul lọ́dún 2018.

Ìjábọ̀ US kan ní Mohamed Bin Salman ló ní kí wọ́n lọ pa akọ̀ròyìn náà àmọ́ ó ní òun kò lọ́wọ́ nínú rẹ̀.

Ọ̀gágun Alenezi ní òun kò kábàámọ̀ pé òun kọ̀ láti mú àṣẹ tí wọ́n pa fún òun ṣẹ.

“Mohamed Bin Salman kò ní jẹ́ kí nǹkankan dí òun lọ́wọ́ láti kọ́ Neom… Mo sì ń kọminú lórí àwọn nǹkan tí wọ́n máa ní kí n ṣe fún àwọn ènìyàn mi.”

Àfikún ìròyìn láti ọwọ́ Erwan Rivault.