Wo kókó pàtàkì mẹ́fà nípa ìtàn ayé Godswill Akpabio, ààrẹ ilé aṣòfin àgbà tuntun

Aworan Sẹnẹtọ Akpabio

Oríṣun àwòrán, Sẹnẹtọ Akpabio

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kẹtala oṣu Kẹfa ni ile aṣofin agba Naijiria dibo yan Sẹnẹtọ Godswill Akpabio gẹgẹ bi aarẹ ti yoo dari eto ile naa fun saa mii.

Ni agbo oṣelu Naijiria, odu ni Godswill Akpabio, kii ṣe aimọ.

O wa lara awọn oludije ti o jade labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC lati dije ipo aarẹ to si pada fi ibo bori akẹgbẹ rẹ Sẹnẹtọ Abdulaziz Yari.

Akpabio ti fi igba kan jẹ Ṣẹnẹtọ nile aṣofin agba Naijiria, bẹẹ naa lo si ti ṣe Gomina ri ni ipinlẹ Akwa Ibom fun ọdun mẹjọ.

Awọn nkan mii ree to yẹ ki o mọ nipa aarẹ ile aṣofin agba Naijiria tuntun yii

Iṣẹ tiṣa ni Akpabio fi bẹrẹ irinajo aye rẹ

Ọdun 1962,oṣu Kejila ọjọ Kẹsan ni wọn bi Godswill Akpabio.

Loni wọn a juwe rẹ gẹgẹ bi agbẹjọro,oloṣelu ati alakoso.

Amọ ninuitan igbesi aye Akpabio, o fi igba kan ṣe iṣẹ olukọ bo ti lẹ jẹ wi pe ko pẹ pupọ lẹnu iṣẹ ogunmẹfun to fi tẹ siwaju nidi iṣẹ agbẹjọro.

Akpabio ko ṣẹṣẹ bẹrẹ irinajo rẹ nidi ọrọ ofin.

Nigba to wa ni fasiti Calabar wọn yan sipo olori ile aṣofin awọn akẹkọọ nigba naa lọhun.

Bakna naa ni ẹka ẹrọ ibaraẹnisọrọ, Akpabio ni iṣẹ ati ipa to ko.

O ba ileeṣẹ EMIS Telecoms Limited ṣiṣẹ

Lọdun 2012 o di ọga agba ileeṣẹ naa ti wọn si lo kopa ribi nidi agbekalẹ ilana ni ẹka ẹrọ ibaraẹnsọrọ ni Naijiria.

O ṣe kọmiṣana ni ileeṣẹ ijọba mẹta ọtọọtọ ri

Laarin ọdun 2002, wọn yan Akpabio sipo Kmisana feto alumọni epo rọbi labẹ ijọba Gomina Victor Attah ni Akwa Ibom.

Laarin 2002 si 2006 o di ipo kọmisana mẹta ọtọọtọ mu ni ipinlẹ naa.

Ni ẹka alumọni epo rọbi, Ijọba ibilẹ ati ileeṣẹ to n risi ọrọ ilẹ ati ile igbe.

Ni 2006 o jade lati du ipo Gomina to si wọle gẹgẹ bi oludije labẹ aisa ẹgbẹ PDP ni ọdun 2007.

Ko tan sibẹ, o tun gbe apoti ibo to si wọle ni Gominaa fun saa keji lọdun 2011.

Ni ọdun 2023 wọn dibo yan gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ awọn Gomina labẹ asia PDP.

Nigba to pari saa rẹ gẹgẹ bi Gomina, o gba ile aṣofin agba lọ labẹ asia PDP bakan naa.

Nibẹ ni wọn ti yan sipo olori ọmọ ile to kere julọ ni ile aṣofin agba .

Ko sẹyin bi ẹgbẹ PDP ti ṣe fidirẹmi lọwọ ẹgbẹ APC ninu idibo ọdun 2015.

Labẹ ipo yi ni Akpabio wa to fi kede pe oun yoo kuro ninu ẹgbẹ PDP lọ si APC.

O pada kọwe fi ipo yi silẹ ṣugbọ́n ọpọ awuyewuye lo tẹhin rẹ wa.

Akpabio jẹ Minisita fọrọ agbegbe Niger Delta lasiko isejọba aarẹ ana, Muhammadu Buhari

Ni oṣu Keje ọdun 2019, aarẹ tẹlẹ, Buhari yan sipo gẹgẹ bi Minisita fọrọ agbegbe Niger Delta.

Ipo Minisita yi lo dimu titi di ọdun 2022 nigba to loun fẹ du ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣlu APC.

Lọjọ ti wọn yoo dibo abẹle lo kede pe oun juwọ silẹ fun Bola Ahmed Tinubu to pada wa di aarẹ loni labẹ asia APC.

Lẹyin ọjọ diẹ ti wọn ṣe eto idibo abẹnu ẹgbẹ yi tan ni Akpabio jaweolubori gẹgẹ bi oldije fun ipo Sẹnetọ ti yoo ṣoju Akwa Ibom North-West Senatorial District.

Ariwo pọ lori ijaweolubori rẹ yi ṣugbọn o tẹsiwaju lati dije ipo Sẹnẹtọ to si fi ẹyin alatako rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party Emmanuel Enoidem janlẹ.

Ibo 115,401 ni Akpabio ni to fi lewaju alatako rẹ to ni ibo 69,838.

Ipo Sẹnetọ yi lo pada fi dije wọle lọjọ Kẹtala oṣu Kẹfa gẹgẹ bi aarẹ ile aṣofin agba Naijiria.

EFCC ti ṣe iwadii lori Akpabio ri

EFCC toju bọ ọrọ Akpabio nigba kan ri lori ẹsunpe o lu owo ọba ni ponpo lasiko to jẹ Gomina AkwaIbom laarin ọdun 2007-2015.

Owo ti wọn fura si pe o ṣe kumọkumọ nigba naa gẹgẹ bi EFCC ṣe sọ jẹ nkan bi ọgọrun biliọnu Naira.

Amọ ṣa titi di asiko yi, wọn ko pe lẹjọ lori ẹsun yi koda agbẹjọro kan Leo Ekpenyong to fẹsun ajẹbanu kan Akpabio ni awọn ọlọpaa gbe lọ si ileẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ.

Ni ọdun 2020 ile aṣojusofin Naijiria ni ki Akpabio wa kawọ pọnyin rojọ lori nina owo ogoji biliọnu Naira ni inakuna.

Godswill Akpabio di ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, ó fẹ̀yìn Abdulaziz Yari janlẹ

Godwin Akpabio

Oríṣun àwòrán, Godwin Akpabio

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ti fihan pe Sẹnatọ Godwin Akpabio ti jawe olubori gẹgẹ bii aarẹ ile asofin agba nilẹ wa.

Akpabio lo fi ẹyin alatako rẹ, Abdulaziz Yari janlẹ ninu eto idibo naa to waye laarọ oni nile asofin apapọ ilẹ wa nilu Abuja.

Ibo mẹtalelọgọta ni Akpabio ni , to se fi ẹyin Yari janlẹ, ẹni to ni ibo mẹrindinlaadọta.

Apapọ ibo ti wọn di si jẹ mọkandinlaadọfa.

Ọpọ awọn oloselu ati lookọ lookọ lo waye peju sile asofin apapọ naa, to fi mọ awọn gomina atawọn oloselu kanka.

Se ni ọpọ awọn asofin fo fun ayọ nigba ti wọn kede pe Akpabio lo moke ninu eto idibo naa.

Bẹẹ ba gbagbe, awuyewuye ti gbalẹ kan lati bii ọjọ melo sẹyin lori ẹni ti yoo di aarẹ ile asofin agba ati olori ile asoju sofin.

Nibayi na, wọn ti n se ibura fun Senatọ Godwin Akpabio gẹgẹ bii aarẹ ile asofin agba kẹwa.

Ile asofin apapọ

Ki lo ti waye saaju?

Awuyewuye lori ta ni yoo di aarẹ ile asofin agba lo n waye lẹyin ti awọn aṣofin saa kẹsan an ṣe isin idagbere ni Ọjọ Satide.

Ki o to di oni, aarẹ Bola Tinubu ni iroyin gbe pe o ṣe atilẹyin fun ṣẹnetọ Godswill Akpabio lati di aarẹ ile igbimọ Aṣofin agba.

Bakan naa ni wọn ni aarẹ buwọlu Tajudden Abbas ati Ben Kalu lati di abẹnugan Ile Igbimọ aṣojusọfin ati igbakeji rẹ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Facebook/Twitter

Awọn wo lo dije du ipo?

Bi o tilẹ jẹ pe aarẹ Tinubu ati awọn aṣofin miran ṣe atilẹyin fun Godswill Akpabio ati Barau Jibrin, ati Tajudeen Abbas ati Ben Kalu fun Ile Igbimọ asọjuṣofin, o ṣeese ki ọrọ bẹyin lọ.

Amọ nigba miran kii ṣe gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ APC lo buwọlu ẹni ti ẹgbẹ yan laayo.

Gomina ipinlẹ Zamfara tẹlẹ, Sẹnetọ Abdulaziz Yari naa n fi ero rẹ han lati sije du ipo adari naa ti Idris Wase si n dije fun ipo igbakeji.

Bakan naa ni Sani Jaji ni oun naa yoo dije du ipo.

Ẹni to di ipo Chief Whip mu, Orji Uzor Kalu lati ipinlẹ Abia ti gba lati jawọ ninu idije naa.

Awọn aṣofin ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan jẹ 109, nigba ti awọn ṣẹnetọ ti wọn dibo yan jẹ 360, ti wọn yoo si maa burawọle fun wọn loni lati bẹrẹ iṣẹ.