Awuyewuye lórí ìgbéyàwó Taiwo Cole, ìyàwó Wofai ní òòyà ò le ya àwọn, ẹbí ọkọ ‘fàáké kọ́rí’

Aworan Taiwo Cole ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, wofaifada/Instagram

Ọrọ ifẹ bi adanwo ni, bayii gan an lọrọ ṣe ri pẹlu Taiwo Cole to wa lati idile gbajumọ lagbegbe Victoria Island niluu Eko ati oṣerebinrin, Wofai Fada.

Ori ayelujara sọkutu wọwọ lopin ọsẹ nigba ti Wofai fi fọto ayẹyẹ igbeyawo wọn soju oju opo Instagram rẹ.

Bi Taiwo ati Wofai ṣe nifẹ ara wọn ti wọn ṣi pinnu lati ṣe igbeyawo, ẹbi Cole ti Taiwo ti wa ko fọwọ si igbeyawo awọn mejeeji.

Ki lo fa awuyewuye lori igbeyawo Taiwo ati Wofai?

Aworan Taiwo Cole ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, Wofai Fada/Instagram

Lẹyin ti fọto igbeyawo Taiwo ati Wofai lu ori ayelujara pa tan lọjọ Aiku ọjọ karun un oṣu Karun un ni ẹbi Cole fi atẹjade kan sita ninu eyi ti wọn ti sọ pe awọn ko fọwọ si igbeyawo laarin awọn mejeeji.

Atẹjade ọhun ti wọn fi sita lorukọ olori ẹbi, Kunle Cole, sọ pe ”a fẹ fi asiko yii sọ fun gbogbo ẹbi, ọrẹ, ati ojulumọ wi pe awa ẹbi Cole lati agbegbe Victoria Island niluu Eko ko mọ nipa igbeyawo ọmọ wa, Taiwo Olakitan Cole.

Bakan naa, a ko fun un ni iyọnda lati ṣe igbeyawo pẹlu ẹnikankan.

Nitori naa, awọn ti wọn n pe ara wọn ni ọmọ idile Cole tuntun nipasẹ ayẹyẹ igbeyawo to waye yii ki i ṣe ara wa.

A tun fi akoko yii rọ ẹnikẹni lati ma gba akọsilẹ tabi iwe kiwe ti wọn ba ti le tọwọ bọ nipasẹ igbeyawo yii.”

Wofai kede igbeyawo rẹ pẹlu Taiwo lori ayelujara

Bo tilẹ jẹ pe ẹbi Cole fi atẹjade sita eyi ti wọn tako igbeyawo Wofai ati Tawio, gbajumọ oṣere naa ko beṣu bẹgba lati pin fọto igbeyawo rẹ pẹlu Taiwo loju opo Instagram rẹ.

Koda, Wofai fi orukọ igbeyawo ti Taiwo fun un ṣako ninu ọkan lara awọn fọto to pin lori ayelujara.

Ẹwẹ, awọn ilumọọka oṣere bii Funke Akindele, Ayo Makun, Toke Makinwa, Kemi Adetiba, Shaffy Bello, Chioma Akpotha ati Ric Hassani ti ki Wofai ati Taiwo ku oriire ayẹyẹ igbeyawo wọn.

Bakan naa ni Wofai tun ṣafihan fidio kan ninu eyi ti o ti wọ aṣọ ibilẹ ati ọkọ rẹ eyi to fihan bi wọn ṣe ṣe eto idana.

Wofai tun kọ nnkan si isalẹ fidio naa pe ”ifẹ ni ẹ jẹ ko ṣiwaju.”

Wofai tun sọ ninu fidio mii pe ”’mo ti ri idunnu mi, mo ṣi da a lohun pe oun ni mo maa ba lọ, ifẹ dun gan an ni tootọ.”

Skip Instagram post

Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Content is not available

View content on InstagramBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

Taiwo fun ra rẹ naa ko gbẹyin, niṣe lo kọ ọ soju opo tiẹ naa pe ”mo ti ri iyawo rere, a gbọdọ fẹ ara ni.”

Aworan ọrọ Taiwo Cole

Oríṣun àwòrán, Wofaiada/INtagram

Ta ni Wofai Fada gan an?

Aworan Wofai fada

Oríṣun àwòrán, Wofai fada/Instagram

Wofai Fada jẹ obinrin kan to n ṣe oriṣiiriṣii nnkan.

Yatọ si pe o jẹ oṣerebinrin ni Naijiria, Wofai tun jẹ adẹrinpoṣonu.

Ti a ba n sọ nipa awọn sọrọsọrọ lori ẹrọ anohunmaworan, Wofai jẹ ọkan lara wọn bakan naa.

Ọkan ninu awọn alenulọrọ lori itakun ayelujara ni Wofai tun jẹ, bakan naa lo tun maa n ṣe fidio ipanilẹrin ti wọn n pe ni sikiiti.

Ki o to bọ sagbo awọn sọrọsọrọ, Wofai ti ṣe owo ounjẹ ati nnkan mimu naa ri.

Onkọwe tun ni Wofai to jẹ ọmọbibi ipinlẹ Cross River lẹkun guusu orilẹede Naijiria.