Akeredolu lọ fún ìsinmi láti lọ gba ìtọ́jú, gbé ìjọba kalẹ̀ fún igbákejì rẹ̀

Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Richard Olatunde

Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu, ti lọ fun isinmi lati gba itọju, o si ti gbe agabra adele fun igbakeji rẹ, Lucky Aiyedatiwa.

Apapọ iye ọjọ isinmi naa jẹ ọjọ mọkanlelogun.

Abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo, Olamide Oladiji, lo sọ eyii di mimọ ninu atẹjade kan to fi lede.

Oladiji sọ pe gomina Akeredolu lo bẹrẹ isinmi ọlọjọ mọkanlelogun ni ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ti yoo si pada si ẹnu iṣẹ ni ọjọ kẹfa, oṣu Keje ọdun 2023 yii.

Abẹnugan ile naa ni “gomina ti ni ki igbakeji rẹ, Lucky Aiyadatiwa, maa dele bii gomina titi ti oun yoo fi pada bẹrẹ iṣẹ ni ọjọ kẹfa, oṣu Keje, ọdun yii.

“Iwe ti gomina fi ranṣẹ si ile aṣofin ni o bẹrẹ isinmi rẹ ni ọjọ keje, oṣu Kẹfa, to si di ọjọ kẹfa, oṣu Keje ko too pada sẹnu iṣẹ nitori isinmi to wa ni ọjọ kejila, oṣu Kẹfa fun ayajọ ijọba awaarawa ati isinmi ti yoo waye ni ọjọ kejidinlọgbọn ati kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹfa fun ọdun Ileya.”

Ṣaaju ni awuyewuye ti kọkọ waye lori ipo ilera Akeredolu.

Ipo ilera naa mu ki awọn ẹgbẹ alatako, PDP ati SDP maa bere fun ipo ti gomina wa, boya o ṣi ni okun lati tẹsiwaju bii gomina ati pe ko fun igbakeji rẹ laṣẹ lati tẹsiwaju ti agbara tirẹ ko ba gbee mọ.

Lucky Aiyedatiwa ti o jẹ ẹni keji ti yoo ṣe igbakeji fun gomina Akeredolu ni o di igbakeji rẹ lẹyin idibo to gbe gomina naa wọle fun saa keji lọdun 2020.

Ẹwẹ, awọn iroyin ẹlẹjẹ kan gbode lẹnu lọlọ yii pe gomina ọhun ti jade laye.

Amọ agbẹnusọ gomina naa, Richard Olabode Olatunde fi fidio kan lede, nibi ti Akeredolu ti n wo ere bọọlu, to si sọ pe kokoko lara ọga oun wa.