Àgbàrá òjò gbé ọgọ́fà èèyàn lọ

Aworan awon araalu

Oríṣun àwòrán, EPA

Gomina ipinlẹ Rio Grande do Sul, Eduardo Leite jẹ ko di mimọ pe agbara ojo to ṣẹlẹ nipinlẹ naa buru kọja sisọ, ati pe o n ṣakoba to pọ fun wọn.

Ko din ni ọgọfa eeyan ti agbara ojo tun ti gbe lọ, ti ẹgbẹẹgbẹrun eeyan si tun ti di alai nile lori nitori agbara to n wa lati inu odo Porte Alegre, to wa ni olu-ilu ipinlẹ naa.

Awọn alaṣẹ ipinlẹ naa ti wa sọ fun gbogbo awọn olugbe agbegbe ti agbara ti n ṣọṣẹ lati kuro nibẹ lai fi akoko ṣofo, nitori aabo ati alaafia ara wọn.

Gomina Leite ti wa sọ pe awọn nilo lati ṣe atunkọ ati atunto awọn agbegbe to ni ọla julọ lawọn ilu to wa ni Brazil.

Loni ọjọ Aiku la gbọ pe Aarẹ Luiz Inacio Lula da Silva yoo tun ṣabẹwo si agbegbe naa, nigba ti awọn alakoso sọ pe awọn ti ko din ni aadọrin ni wọn ko ni ile lori mọ.

Niluu Porto Alegre, to jẹ olu-ilu naa, apa kan nibi odo Guaiba lo ya danu, to si fa agbara nla, eyi to ya wọ ọpọlọpọ ile to wa lagbegbe naa.

Agbara naa wo ọpọlọpọ ile to wa nibẹ danu.

Awọn eeyan ti ko din ni miliọnu kan ni wọn n gbe ni agbegbe ti wọn ti n jiya ina mọnamọna, omi to dara, ti igbagbọ si wa pe agbara naa yoo ṣi tubọ maa ya sii.

Ọkunrin ti wọn pe ni Evandro Lucas ni wọn pe alakoso ileeṣẹ to n ri sọrọ eto abo ni ẹkun ọhun.

“A nilo irinṣẹ, awọn kẹmika ti wọn fi n daabo bo omi fun mimu, ati awọn ibusun, nitori pe ọna kan ṣoṣo ree ti a le fi mu awọn eeyan agbegbe yii lọkan le.”

Ajọ kan to n ri si ọrọ oju ọjọ ni Brazil jẹ ko di mimọ pe ko si nnkan meji to fa agbara yii to kọja ojo arọọrọda to rọ.