Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo tẹ babaláwo àtàwọn tó ń fi ẹ̀yà ara èèyàn gún ọṣẹ

Ondo Police

Oríṣun àwòrán, Funmi Odunlami

Ọjọ gbogbo ni tole ọjọ kan ni tolohun ni awọn agba wi, bẹẹ lo ri fun oluawo kan ati awọn meji mii ti wọn n fi ẹya ara eniyan gun ọṣẹ fun etutu ọla nipinlẹ Ondo.

Komisona Ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abayomi Peter Oladipo lo foju awọn afunrasi naa lede niluu Akure.

Ọkan ninu awọn afunrasi ọhun, Dolapo Babalola to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogoji jẹwọ pe ṣe lawọn n pa awọn eniyan lati fi gun ọsẹ.

Babalola lasiko to n jẹwọ ẹsẹ rẹ sọ pe oun ti pa eniyan marun un to fi mọ ọmọ egbọn rẹ ati ọrẹ timọtimọ rẹ kan.

Babalola to jẹ oniṣowo ẹsọ ara ṣalaye pe oun maa n gba ọkada lọwọ awọn eniyan ti yoo si pa wọn ni kete ti wọn ba ti daa mọ.

O ni lẹyin iku awọn eeyan naa ni yoo yọ ẹya ara awọn lati ko fun Babalawo Quadri Lawal, to jẹ ẹni ọdun marunlelọgbọn lati fi gun ọṣẹ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, wọn ti wa ninu isẹ naa lati ọdun 2021 ti wọn si n ṣọsẹ nipinlẹ Ondo ati agbegbe rẹ.

Ondo

Oríṣun àwòrán, bbc

Lasiko to n awọn akọroyin sọrọ, babalawo Quadri Lawal sọ pe wọn ma n lo eya ara awọn eniyan lati fi gun ọsẹ fun awọn to ba nilo rẹ, to si jẹ pe eya ara ti awọn onibara wọn ba bere fun lawọn ma n wa kiri.

Komisona ọlọpaa sọpe awọn ti gba ọkada meje lọwọ awọn afunrasi naa pẹlu awọn oogun abẹnugọngọ, to fi mọ ọṣẹ dudu ti wọn fi ẹya ara awọn eniyan ṣe.

Bakanna ni Komisona Oladipupo fi oju awọn afunrasi ọdaran marundinblogun miran lede pẹlu oniruru ẹsun to fi mọ ipaniyan, ijinigbe, idigunjale ati ṣiṣe ẹgbẹ okunkun.

O ṣeleri pe wọn yoo ko gbogbo awọn ọdaran ọhun lọ ile ẹjọ pẹlu ileri pe wọn yoo fọ gbogbo kọrọkọndu ipinlẹ Ondo mọ patapata lọwọ iwa ọdaran.