Aminat, akẹ́kọ̀ọ́ táwọn ọlọ́pàá yin tajútajú fọ́ lójú ṣàlàyé bí ọlọ́pàá ṣe jáa jù sílẹ̀ nílé ìwòsàn

Aminat Alege

Awọn ẹbi Aminat Alegẹ, ọmọ ọdun mejila ti agolo afẹfẹ tajutaju tear gas ti ọlọpaa yin ba loju to si fọ oju naa ti pariwo ba BBC News Yoruba ni gbolohun lori rẹ.

Aminat Alegẹ jẹ akẹkọọ ipele kẹta girama ni ile ẹkọ girama Adam Yakub Memorial High School lagbegbe Agege ni ipinlẹ Eko. Ile ẹkọ lo si lọ ni ọjọ kẹsan an oṣu keji ọdun 2024 nibi ti agolo ibọn tajutaju ọlọpaa ti ba a.

“Awọn ile ẹkọ to wa lẹgbẹ wa ma a n ja ni gbogbo ọjọ Ẹti, nibi ti mo ti nlọ ti mo fẹ wọ inu mọṣalaṣi pe ki n fi ara pamọ fun wọn ni awọn ọlọpaa wa yin afẹfẹ tajutaju si mi loju.”

Amina ni awọn ọlọpaa naa, ti wọn wa lati agọ ọlọpaa to wa ni agbegbe Dọpẹmu, gbe oun lọ si agọ wọn.

Igbakugba ti mo ba wo oju ọmọ mi ti ko fọ ni mo maa n ranti ẹwa rẹ ti wọn fẹ bajẹ – Iya Aminat

Aminat pẹlu iya rẹ ninu ọja

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe awọn akẹkọọ kan lo lọ fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa pe awọn akẹkọọ ile ẹkọ meji ọtọọtọ kan n ja lagbegbe naa, eleyi lo mu ki wọn ran awọn ọlọpaa mẹrin lati wa pa ina rogbodiyan ti awọn akẹkọọ naa da silẹ.

Aminat ni, “ nigba ti a de ile iwosan Ile epo, mo sun, awọn ọlọpaa naa wa salọ.”

Sisun ti ọmọdebinrin naa sun ni ileewosan ile epo, eyi ti awọn awọn ọlọpaa naa fi silẹ si ti wọn fi salọ, ile iwosan nla LASUTH lo ti ji saye pada.

Iya Aminat ṣalaye pẹlu omije loju pe nigbakugba ti oun ba n wo oju apa ọtun rẹ ti wọn yin tajutaju fọ, omije maa n gba oju oun, ọkan oun pẹlu a si gbọgbẹ. Amọṣa nidakeji, bi oun ba tun wo oju osi rẹ, oun a ri ẹwa ti wọn fẹ bajẹ lara ọmọ oun.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí