Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ṣàlàyé ìdí tó fi fẹ́ wó ọgọ́rùn-ún ilé abẹ́ afárá Adeniji Adele lónìí

Aworan Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Tokunbo Wahab/X

Ijọba ipinlẹ Eko yoo wo ọgọrun un ile abẹ afara Adeniji Adele lonii ọjọ Aje ti i ṣe ọjọ kẹfa oṣu Karun un ọdun 2024.

Kọmiṣọna fun ọrọ eto ayika ati alumọni inu omi nipinlẹ Eko, Tokunbo Wahab lo fọrọ yii lede loju opo X rẹ.

Kómiṣọna ni igbesẹ yii yoo waye lonii lẹyin ti ijọba ti fun awọn to n gbe ninu awọn ile ọhun ni ọjọ meji lati ko kuro nibẹ.

Ọgbẹni Wahab tun fidi ọrọ yii mulẹ fawọn akọroyin lana ọjọ Aiku niluu Eko.

”Idi ree ti a fi fẹ awọn ile abẹ afara Adeniji Adele”

Kọmiṣọna ọrọ ayika ati alumọni inu omi ṣalaye pe ninu awọn ile yii lawọn janduku to n ṣọṣẹ lagbegbe Adeniji Adele maa n sa pamọ si.

Bakan naa ni Ọgbẹni Wahab ṣalaye pe awọn janduku yii tun maa n fa igbo atawọn egboogi oloro mii eyi to n ṣakoba fawọn to n gbe lagbegbe naa.

”Eleyi to tun dabi rẹ ni pe ninu idọti ati ẹgbin ni awọn eeyan to n gbe ninu awọn ile yii wa eleyi to tabuku ipinlẹ Eko ti ko si tun dara fun alaafia ayika.

Atipe igbesẹ yii jẹ ọkan lara ipinnu ijọba Gomina Babajide Sanwo-Olu lati gba gbogbo aye ati ilẹ tawọn eeyan kan wa lori rẹ lọna aitọ.

Iru awọn ile to dọti bayii maa n tabuku ọrukọ ati irisi ipinlẹ Eko eyi ti ko si dara fun ilu nla ti Eko jẹ.

Fun idi eyi, mo rọ gbogbo awọn to n gbe labẹ afara yii lati ko kuro nibẹ fun ra wọn, ki wọn ṣi ko ẹru wọn jade ki ijọba to de de ibẹ lonii.

Awọn agbofinro yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn oṣiṣẹ ajọ KAI to n gbogun ti iwa ibajẹ nipinlẹ Eko atawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ayika ati alumọni inu omi lọjọ Aje lati wo awọn ile abẹ afara Adeniji Adele,” Kọmiṣọna fun ọrọ eto ayika ati alumọni inu omi nipinlẹ Eko lo sọ bẹẹ.

Skip Twitter post

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.