Davido láhùn fún ìgbà àkọ́kọ́ lórí ikú Ifeanyi ọmọ rẹ̀

Davido

Oríṣun àwòrán, Davido

Gbajugbaja olorin takasufe, David Adeleke, ti ọpọ eeyan mọ si davido ti sọ pe ojojumọ loun maa n saaro ọmọ oun, Ifeanyi Adeleke, to di oloogbe.

Davido lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ kan ti orukọ rẹ n jẹ “Million Dollaz Worth of Game.”

O ni ko rọrun fun oun lati tun gbe awo orin “Timeless” jade lẹyin iku ọmọ oun naa amọ oun ṣe bii ọkunrin.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọpọ awọn ololufẹ rẹ lo n reti ki o kọ orin idaro ninu awo orin tuntun naa amọ o ni oun fun awọn eeyan oun ni orin ti wọn yoo gbadun dipo orin ọfọ.

Ojumọ kan kii mọ ki omije ma bọ loju mi

Davido ṣalaye pe ojumọ kan kii mọ ki omi ma bọ loju oun nitori iku ọmọ naa amọ oun maa n ṣe ara giri.

Ninu alaye rẹ, Davido ni oun gbagbọ pe iya oun ati ọmọ oun wa lajule ọrun ti wọn n gbadun orin ti oun n kọ ni ko jẹ ki oun ba ọkan jẹ.

OBO sọ siwaju si pe bo tilẹ jẹ pe oun n gbiyanju lati ma ba ọkan jẹ, gbogbo igba ni oun maa n saaro ọmọ naa.

O ni “Ti mo ba wo ara mi ninu digi, mo mọ pe ọpọ eeyan lo fi ireti wọn sinu mi.”

“Ojojumọ ni mo maa n saarọ ọmọ mi.”

“Ojojumọ ni omije maa n bọ loju mi nitori iku ọmọ mi ṣugbọn ọpọ eeyan ni ko mọ.”

“Mo mọ pe ọmọ mi n wo mi lati ajule ọrun, yatọ si pe ọmọ naa ko ni fẹ ki n ba ọkan jẹ nitori iya rẹ, mo ni lati ṣara giri nitori awọn ololufe mi kakiri agbaye.”

Ọjọ kinni, oṣu Kọkanla, ọdunn 2022 ni Ifeanyi jade laye lẹyin to ri sinu adagun omi ‘swimming pool’ ile wọn to wa lagbegbe Banana Island, niluu Eko.

Davido

Oríṣun àwòrán, davido