Wo ìdí tí ìjọba Naijiria ṣẹ̀ṣẹ̀ gbẹ́sẹ́ kúrò lórí òfin tó fi de Twitter lẹ́yìn oṣù Méje

Twitter ban

Oríṣun àwòrán, @Naija_PR

Ijọba apapọ ti gbẹsẹ kuro lori ẹrọ Twitter ni Naijiria lẹyin oṣu Meje to fofin de oju opo naa.

Ikede yii lo waye ninu atẹjade kan ti alaga igbimọ to n ri si ọrọ naa, Kashifu Inuwa Abdullahi fi lede niluu Abuja.

Atẹjade naa ni “Ijọba apapọ ti ran mi lati kede fun awọn araalu pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ ki wọn ka ofin ti won fi de Twitter nilẹ, lati aago mejila oru, ọjọ kẹtala, oṣu Kinni, ọdun 2022 yii.”

“Aṣẹ yii waye lẹyin lẹta kan ti minisita to n ri si eto ibaraẹnisọrọ ati eto ọrọ aje ori ayelujara, Ọjọgbọn Isa Ali Ibrahim, kọ si Aarẹ”.

“Ninu lẹta naa ni minisita ọhun ti jabọ fun Aarẹ ibi ti igbimọ ti wọn gbe kalẹ ba isẹ de, to si tun bere fun aṣẹ lọwọ Aarẹ pe ki wọn wọgile ofin ti wọn fi de Twitter”.

Ṣaaju akoko yii ni ijọba aapọ ati Twitter ti kọkọ n fọrọjomitooro ọrọ lori bi wọn yo gbẹsẹ kuro lori ikanni naa, lori awọn idi kan.

Gẹgẹ bii ohun ti Ali Ibrahim sọ, ileeṣẹ Twitter ti gba lati ṣe ohun ti ijọba Naijiria n fẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni “Adehun wa pẹlu Twitter yoo ran Twitter lọwọ lati le gbooro si ni Naijiria, ati pe ijọba apapọ yoo pese anfani to yanranti fun Twitter lati tunbọ ṣe aṣeyọri ni Naijiria”.

Inu oṣu Kẹfa, ọdun 2021 ni Aarẹ Muhammadu Buhari gbẹsẹle Twitter ni Naijiria lẹyin ti ileeṣẹ naa yọ ọrọ to kọ lori ikanni ọhun bi ẹni yọ jiga.

Twitter ban

Oríṣun àwòrán, @ulxma

Twiiter sọ lasiko naa pe ọrọ kobakungbe ni Aarẹ Buhari kọ loju opo naa, ati pe irufẹ ọrọ naa ko ba ofin ileeṣẹ awọn mu.

Amọ ijọba apapọ fesi pe igbesẹ awọn lati fofin de Twitter ni Naijiria ko ni nnkan lati ṣe pẹlu bi Twitter ṣe fa ọrọ Aarẹ yọ lori ikanni naa.

Lẹyinorẹyin, ọpọ awọn ọmọ Najjiria lo n gba ọna ẹyin wọle sori ikanni Twitter pẹlu iranlọwọ “VPN.”

Nigba ti awọn kan ninu ijọba Buhari n lo Twitter lasiko ti wọn ba tẹkọ leti lọ si orilẹ-ede mii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ