Bí Otunba Adebayo Alao Akala ṣe kú rèé, àti ibi tó dákẹ́ sí gangan – Amúgbálẹ́gbẹ́ Alao Akala

Adebayọ Alao Akala

Oríṣun àwòrán, @Otunba_Ogunwuyi

Ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ Ọtunba Adebayọ Alao Akala, Ọmọọba Jimọh Wasiu Olukan, ti fi idi ọrọ mulẹ wipe Akala ko ṣe aisan rara ki o to di oloogbe.

O ni ile igbọnsẹ ni gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri naa wa ki ọlọjọ to de.

O tẹsiwaju pe lọjọ Iṣẹgun ni Akala de lati ilu Abuja ti o ri irinajo lọ ti o si jẹun ni aago mẹrin irọlẹ.

Lẹyin eleyii ni wọn jọ pejupesẹ wo ifẹsẹwọnsẹ idije bọọlu Afcon laarin orilẹede Naijiria ati Egypt ni irọlẹ ọjọ naa.

Olukan tẹsiwaju pe ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ni oun kuro ni ibi ti oloogbe wa.

Adehun ti wọn si jọ ni ni lati pade ni aago mẹwa owurọ Ọjọru ki wọn le jọ rin irinajo lọ si ilu Ibadan nibi ti Ọtunba Akala ti fẹ ṣe ipade pẹlu awọn eeyan kan ti o da akoko naa fun.

Olukan ni ” Bi wọn ṣe pe mi ni nnkan bi aago mẹjọ owurọ ọni, nitori wọn ni ki wọn ba awọn gbe omi kana ti wọn a fi wẹ ni aarọ yii”.

“Wọn gbe omi yẹn kana, wọn ti gbe ounjẹ wọn si ori tabili. Ounjẹ wọn ti wọn gbe si ori tabili yẹn, ti wọn ba si ti gbe ounjẹ si ori tabili wọn a lọ pe wọn”.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Igba ti wọn wa de ibẹ wọn wa ba wọn nile igbọnsẹ ti wọn fi ọwọ lẹran ti ọlọjọ si ti de… Wọn ti fun ọpọlọpọ awọn eeyan ni akoko fun ipade lonii.

Ẹni ti wọn fun ni aago mẹwa, ẹni ti wọn fun ni aago mọkanla”.

Lẹyin eyii ni wọn gbe Ọtunba Adebayọ Alao Akala digbadigba lọ si ile iwosan ẹkọṣẹ iṣẹgun Oyinbo, ‘LAUTECH Teaching Hospital’ to wa ni ilu Ogbomọṣọ, nibi ti ayẹwo awọn Dokita ti fi idi rẹ mulẹ pe ọlọjọ ti de.

Lati owurọ Ọjọru si ni ọgọrọ awọn eeyan ti n ṣe abẹwo si ile oloogbe to n bẹ ni agbegbe Randa nilu Ogbomọṣọ, lati kedun pẹlu ẹbi wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo tẹ́lẹ̀, Adebayo Alao-Akala ti jáde láyé

Otunba Alao Akala

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Adebayo Alao-Akala ti dagbere faye.

Alao-Akala ku lẹyin to pe oṣu kan gbako ti Ṣọun Ogbomoso, Ọba Jimoh Oyewumi lọ darapọ mọ awọn Baba nla rẹ.

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le sọ ohun to ṣokunfa iku rẹ lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, ohun ti a gbọ ni pe o jade laye loju orun.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ fun Gomina tẹlẹ yii lo fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC Yoruba.

Ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun 1950 ni wọn bi oloogbe ọhun niluu Ogbomoso.

Oun si ni gomina ipinlẹ Oyo laarin ọdun 2007 si 2011.

Alao-Akala tun gbe apoti gomina ipinlẹ Oyo ninu eto idibo to waye lọdun 2019 labẹ aisa ẹgbẹ oṣelu ADP.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ