Ìjọba yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní wó àwọn ilé tó wà lójú ọ̀nà mọ́rosẹ̀ Eko sí Calabar tí iṣẹ́ ń lọ lórí rẹ̀

Aworan iṣẹ ọna to n lọ lọwọ

Oríṣun àwòrán, Federal Ministry of Works/X

Ijọba apapọ orilẹ-ede yii ti sọ pe ọjọ Satide ni wiwo awọn ile to wa loju ọna, ti wọn ti fi àmì si lati wo fun ọna marosẹ Eko si Calabar yoo bẹrẹ.

Korede Keisha, alakooso iṣẹ ode nipinlẹ Eko, sọ eyi di mimọ l’Ọjọbọ niluu Eko.

Alakooso naa rọ gbogbo awọn tijọba ti sami sile wọn lati wo lulẹ, pe ki wọn tete lọ si ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko, lati pari eto gbogbo to yẹ

Aṣoju ijọba naa ṣalaye pe Satide yii ni ikọ ti yoo wole naa yoo de lati bẹrẹ iṣẹ wọn.

Lori iye ti wọn yoo fi pari ọna yii, minisita fun ọrọ iṣẹ ode, Dave Umahi, sọ laipẹ yii pe yoo to biliọnu mẹrin ti yoo pari kilomita kan.

Ẹẹdẹgbẹrin kilomita(700) ni ọna marosẹ Eko si Calabar yii, tiriliọnu mẹẹẹdogun (15 trillion) ni ijọba apapọ sọ pe yoo pari rẹ.

Ọna to bẹrẹ lati Eko naa yoo gba Cross River, Ogun, Ondo, Delta, Rivers, Bayelsa ati ipinlẹ Akwa ibom.

Àwọn èèyàn kan korò ojú sí ṣíṣe ọ̀ná ńlá ọ̀hún

Dave Umahi, Alakooso ọrọ iṣẹ ode ni Naijiria

Ọpọlọpọ eeyan lorilẹ-ede yii ni wọn ko nifẹẹ si ọna nla tijọba apapọ fẹẹ ṣe yii, wọn ni bii ẹni n sun owo nina ni.

Koda, Peter Obi to dupo aarẹ Naijiria ni 2023, sọ pe ai mọ eyi to kan lo jẹ kijọba ronu ati ṣe ọna yii.

Bakan naa ni Atiku Abubakar toun naa dupo aarẹ lọdun to kọja, sọ pe jibiti ni.

Ṣugbọn ijọba apapọ ti tako eyi pe ko ri bẹẹ.

“ Umahi ti iṣẹ ọna naa wa lọwọ rẹ sọ pe Atiku ko mọ iṣiro ni.

O loun yoo fi ounka han an, yoo si ye e bi ijọba Aarẹ Bọla Tinubu ṣe n ṣọwọ na to.