Wo àwọn èèkàn mẹ́rin tí Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pàdánù láàárín oṣù kan

Awọn eekan ilu Oyo to dagbere faye

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àwọn Ọba onípò kìíní mẹ́ta laarin Ọba ilẹ Naijiria àti èèkàn olóṣèlú kan ni ikú já gbà mọ́ àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọ́wọ́ láàárín oṣù kan ṣoṣo síra wọn.

Eyi ti n mu ki ọpọlọpọ maa bere lori ayelujara pe ki lo ṣẹlẹ gan.

Bo tilẹ jẹ pe awọn to dagbere faye yii kii ṣe ọmọ ikoko, sibẹ sibẹ, awọn Yoruba maa n fẹ woye ki lo ṣẹlẹ ti iku ba ti n di ọwọọwọ paapaa julọ ilu kan ṣoṣo ni awọn mẹrin yii ti wa ti iku si mu wọn lọ laarin oṣu kan ni ipari ọdun 2021 si ibẹrẹ ọdun 2022.

Àwọn nìyí :

Ṣọ̀ún Ògbómọ̀ṣọ́ (Oba Jimoh Oladunni Oyewumi (JP, CON, CFR) Ajagungbadé III) – December 12, 2021

Soun Ogbomoso

Ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kejìlá ọdún 2021 ni ṣọ̀ún Ògbómọ̀ṣọ́ jáde láyé lẹ́ni ọdún márùndínlọ́gọ̀rún. Ajagungbadé lo ọdún méjìdínláàdọ́ta lórí ìtẹ́ lẹ́yìn tí ó gorí oyè ní ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù kẹwàá ọdún 1973.

Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù karùn-ún, ọdún 1926 ni wọ́n bí i sí ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ sínú ẹbí Ọba Bello Afolabi Oyewumi, Ajagungbadé ll àti Ayaba Seliat Olatundun Oyewumi.

Asigangan ti Igangan, Oba Abdul-Azeez Adewuyi, Aribiyan II – December 21, 2021

Asigangan ti ilu Igangan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Kò tó ọjọ́ mẹ́wàá tí ṣọ̀ún Ògbómọ̀ṣọ́ darapọ̀ mọ́ àwọn babańlá rẹ̀ tí Asigangan tí ìlú Igangan ní Ìpínlẹ̀ Oyo bákan náà, Oba Abdul-Azeez Adewuyi, Aribiyan II, kí dúnìyàn pódìgbà.

Ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù Kejìlá, ọdún 2021 ni Asigangan wàjà.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Olubadan ti Ìbàdàn, Oba Saliu Adetunji, Ogunguniso 1 – January 02, 2022

Olubadan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Olubadan ti ìlú Ìbàdàn, Oba Saliu Adetunji, Ogunguniso 1 tó gorí ìtẹ́ bàbá rẹ̀ lọ́jọ́ kẹrin, oṣù kẹta, ọdún 2016 re ìwàlẹ̀ àṣà lẹ́ni ọdún mẹ́tàléláàdọ́rùn-ún.

Ọba onípò kìíní ọ̀hún ni wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹjọ, ọdún 1928 sínú ìdílé Raji Olayiwola àti Suwebat Amope Adetunji ní ilé Alusekere, Popoyemoja, Ibadan.Òun ni àkọ́bí nínú ọmọ mẹ́tàdínlógún tí bàbá rẹ̀ bí.

Otunba (Dr) Adebayo Alao-Akala – January 12, 2022

Aworan Alao Akala

Oríṣun àwòrán, Facebook/Otunba Adebayo Alao Akala

Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ Kejìlá, oṣù kìíní ni ìkéde ikú gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀ rí, Otunba Adebayo Alao-Akala da omi tútù sí ọkàn àwọn ènìyàn.

Àlàó-Akala tí wọ́n bí sí ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ lọ́jọ́ kẹta oṣù kẹfà, ọdún 1950, dágbére fáyé lẹ́ni ọdún mọ́kànléláàdọ́rin.Ó ti fi ìgbà kan ṣe iṣẹ́ ọlọ́pàá kí ó tó di igbákejì gómìnà sí Olóyè Rashidi Ladoja.

Ó di gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lẹ́yìn tí wọ́n rọ Ọgbẹni Abdulrasheed Ladoja lóyè. Ó díje fún ipò gómìnà lábẹ́ àsíá egbe òṣèlú ADP lọ́dún 2019 kí ó tó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.