Wo ìṣepatàkì àmì ẹ̀yẹ Caf tí Osimhen gbà àtàwọn ọmọ Nàìjíríà tó ti gbàmì ẹ̀yẹ náà sẹ́yìn

Aworan Osihmen ati awọn eekan agbabọọlu Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty

Ẹlẹsẹ ayo Victor Osimhen ati Asisat Oshoale ṣe bẹbẹ fun orilẹede Naijiria nibi ayẹyẹ ifamiẹyẹ danilọla ajọ Caf to waye lorilẹede Morocco lalẹ ọjọ Aje tii ṣe ọjọ Kọkanla oṣu Kejila.

Iṣẹlẹ yi si lapa lẹka ere bọọlu Naijiria pẹlu bi awọn agbabọọlu orileede naa lọkunrin ati lobinrin ti ṣe fakọyọ nibi ayẹyẹ ifami ẹyẹ danilọla ajọ elere bọọlu Afirika taa mọ si Caf.

Niṣe ni orilẹede Naijiria fọwọ rọlẹ nibi ayẹyẹ ifami-ẹyẹ-danilọla ajọ ere bọọlu ilẹ Afirika CAF tọdun 2023 to waye lorilẹede Morocco lọjọ Aje.

Nibi ayẹyẹ naa ti wọn ṣe ni Morocco lalẹ ọjọ Aje lawọn agbabọọlu ọkunrin ati obinrin Naijiria ti fakọyọ ti Victor Osimhen,Super Eagles, si gba ami ẹyẹ agbabọọlu ọkunrin to pegede julọ.

Atamatase ẹgbẹ agbabọọlu Napoli yi fẹyin awọn akẹgbẹ rẹ Ashraf Hakimi ọmọ Morocco ati Mohammed Salah ti Egypt janlẹ.

Igba akọkọ ree ti yoo gba ami ẹyẹ yi.

Osimhen ti wa darapọ mọ awọn eekan agbabọọlu Naijiria mii bi Rashidi Yekini, Emmanuel Amuneke, Nwankwo Kanu ati awọn mii to gba ami ẹyẹ yi ṣaaju.

Akẹgbẹ rẹ Asisat Oshoala,tawọn ololufẹ rẹ mọ si ‘agba baller’ ni wọn dadẹ fun gẹgẹ bi obinrin agbabọọlu to fakọyọ fọdun 2023.

Ki wa ni pataki to rọ mọ iṣẹlẹ yi ati pe ki ni ohun to faa ti inu awọn ọmọ Naijiria fi n dun si bi awọn agbabọọlu yi ti ṣe fakọyọ?

Osimhen da ogo pada fun Naijiria lẹyin ọdun mẹrinlelogun

Aworan Victor Osihmen ni ọdun 2015 ati 2023

Oríṣun àwòrán, Getty

Osimhen pẹlu itu to pa nipa gbigba ami ẹyẹ Caf yi ti di agbabọọlu ọmọ Naijiria ọkunrin akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ yi lẹyin ti Nwankwo Kanu gba kẹyin lọdun 1999.

Eyi tunmọ si pe ọdun mẹrinlelogun sẹyin ni Naijiria ti jẹ adun gbigba ami ẹyẹ yi kẹhin.

Ninu ọdun saa bọọlu kan ṣoṣo yi naa ni Osimehn ti fakọyọ gba ami ẹyẹ agbabọọlu to ta lẹnu julọ ni Italy fun ipa to ko fun ikọ agbabọọlu Napoli.

Napoli lo gba ami ẹyẹ ikọ to pegede julọ ni Serie A lorileede Italy ti Osimehn si jẹ agbabọọlu to gba goolu sawọn julọ ni saa ọdun 2023.

Yatọ si eleyi o ṣe ipo kẹwa nibi ami ẹyẹ Ballon’d’Or to waye lọdun yi.

Ninu ọrọ rẹ lẹyin ti wọn da lọla ti Caf, Osimehn fi ẹmi imoore rẹ han si awọn to sọ pe wọn fi ẹsẹ rẹ sọna lati le de ibi toun de lonii.

Ninu wọn ni o ti fọpẹ fun Didier Drogba, Emmanuel Amuneke, Salomon Kalou ati awọn miran naa.

Aworan Osimehn ati Oshoala

Oríṣun àwòrán, cafonline.com

Agba baller fi itan lelẹ gba ami ẹyẹ fun igba kẹfa

Asisat Oshoala kii ṣe ajọji nidi a n gba ami ẹyẹ obinrin to pegede julọ nidi ere bọọlu ni Africa.

Lalẹ ọjọ Aje o fi itan lelẹ gba ami ẹyẹ yi fun igba kẹfaa.

Ko yi si obinrin to gba ami naa to lati igba ti wọn ti ṣe ifilọlẹ ami naa fawọn obinrin agbabọọlu.

Ohun naa lo gba lọdun to lọ ti Sadio Mane si gba ami ẹyẹ agbabọọlu kunrin to pegede julọ.

Ninu awọn ọmọ Naijiria mii to fakọyọ lalẹ ọjọ Aje ni Nnadozie Chiamaka wa.

Oun ni wọn da lọla aṣọle obinrin to fakọyọ julọ ni Africa.

Igba akọkọ ree ti yoo gba ami ẹyẹ yi.

Aworan Nnadozie to gba ami ẹyẹ aṣọle obinrin to fakọyọ

Oríṣun àwòrán, cafonline.com

Awọn ọmọ Naijiria mii to gba ami ẹyẹ yi ri ṣaaju

Aarẹ Tinubu Naijiria pẹlu awọn ọmọ Naijiria lati nawọ ikini ku oriire si Osihmen, Oshoala ati Nnadozie to gbogo orileede naa ga.

O ṣapejuwe wọn gẹgẹ bi aṣoju rere forileee Naijiria to ssi ni oun kan sara si wọn lori pe wọn ko gbagbe orisun wọn.

Ṣaaju ki awọn ti aarẹ ki ku oriire yi to lala pe awọn le pa iru ita ti wọn n pa lonii, o ti ni awọn agbabọọlu mii to lewaju.

Ninu wọn lasi ti ri awọn taa fẹ ka wọnyi ati ọdun ti wọn gba ami ẹyẹ Caf.

  • Rashidi Yekini 1993
  • Emmanuel Amuneke 1994
  • Nwankwo Kanu 1996
  • Victor Ikpeba 1997
  • Nwankwo Kanu 1999

Nwankwo Kanu lo gba ami ẹyẹ yi kẹyin labala awọn agbabọọlu ọkunrin fun Naijiria

Abala awọn obinrin to gba ami ẹyẹ Caf

Ni abala awọn obinrin, wọnyii lawọn obinrin agbabọọlu Naijiria to ti gba ami ẹyẹ naa sẹyin.

  • Mercy Akide 2001
  • Perpetua Nkwocha 2004
  • Perpetua Nkwocha 2005
  • Cynthia Uwak 2006
  • Cynthia Uwak 2007
  • Perpetua Nkwocha 2010
  • Perpetua Nkwocha 2011
  • Asisat Oshoala 2014
  • Asisat Oshoala 2016
  • Asisat Oshoala 2017
  • Asisat Oshoala 2019
  • Asisat Oshoala 2022

Wọn ko ṣeto ayẹyẹ naa lọdun 2009,2019,2020 ati 2021