Ẹ̀fun n béèdì? Wọ́n so líìgì bọ́ọ̀lù rọ̀ ní Turkey lẹ́yìn tí ààrẹ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù da ẹ̀ṣẹ́ bo rẹfirí lójú

Aworan ibi ti aarẹ ẹgbẹ agbabọọlu ti doju ija kọ rẹfuri

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn adari liigi ere bọọlu ni Turkey ti paṣẹ ki wọn so liigi naa rọ lẹyin ti aarẹ ẹgbẹ agbabọọlu kan da ẹṣẹ bo rẹfiri kan lẹyin ifẹsẹwọnsẹ kan to waye lọjọ Aje.

Refiri naa, Halil Umut Meler ni a gbọ pe aarẹ ẹgbẹ agbabọọlu MKE Ankaragucu Faruk Koca, ṣadeedee sa wọ ori papa ni iṣẹju kẹtadinlọgọrun nigba ti ikọ keji Caykur Rizespor jẹ goolu to pa oju idije naa de.

Gbogbo ifẹsẹwọnsẹ liigi la ti so rọ titi di ọjọ mii taa tun kede rẹ pada”

Bẹẹ ni alaga liigi TFF Mehmet Buyukeks ti ṣe sọ fawọn akọroyin

O tẹsiwaju pe ”Ohun itiju gbaa ni ikọlu si rẹfuri lalẹ yi jẹ fun ere bọọlu ni Turkey.”

Aimọye igba ni wọn ko iya bo Meler nigba to ṣubu silẹ eyi to mu ko farapọ laimọye ọna.

Iṣẹlẹ yi mu ki wọduwọdu waye laarin awọn agbabọọlu ati awọn adari ere bọọlu.

Minisita f’ọrọ abẹle ni Turkey, Ali Yerlikaya, sọ pe Koca gba itọju ni ileewosan ”ṣugbọn a o gbe gbogbo igbesẹ to yẹ lati fi si ahamọ lẹyin to ba gba itọju”

O fikun pe awọn mii lọwọ awọn ti tẹ fun ipa ti wọn ko ninu iṣẹlẹ yi to sọ pe ”patpata la bẹnu atẹ lu u”

Refuri Meler,ẹni ọdun mẹtadinlogoji, wa lara awọn rẹfuri to lewaju ni Turkey to si maa n dari ifẹsẹwọnsẹ fun ajọ ere bọọlu Fifa.O lo wa lara awọn eekan rẹfuri fun ajọ Uefa.

Wọn ni lati ṣeto itọju fun Meler ti dokita agba nileewosan ti wọn gbe lọ Dokita Mehmet Yorubulut si sọ pe ”ko si ohun to le fa ewu fun lasiko yi.Ẹjẹ kan jade lẹgbẹ oju osi rẹ ni to si farapa diẹ”

”A o fi sabẹ ayẹwo titi di aarọ tori pe o fi ori gba. Lẹyin ayẹwo to yẹ, a o faaye gba a lati pada sile ti ilẹ ba mọ’

Aworan rẹfuri Halil Meler ti oju rẹ wu

Oríṣun àwòrán, Getty

Aarẹ Turkey naa da si ọrọ yii

Ninu esi rẹ si iṣẹlẹ to waye yi, aarẹ orileede Turkey, Recep Tayyip Erdogan sọ ṣapejuwe iṣẹlẹ yi gẹgẹ bi ohun to ṣe ni ni kayeefi.

Mo koro oju si iklu ti wọn ṣe si adari ere bọọlu Halil Umut Meler lẹyin ifẹsẹwọnṣẹ to waye nirọle yi laarin MKE Ankaragucu ati Çaykur Rizespor.Mo si gbadura ki ara rẹ tete ya”

Aarẹ tẹsiwaju pe ”Ere idaraya tunmọ si alaafia ati ijẹ ọmọ iya.Ko ni nkankan ṣe pẹlu iwa janduku. A o ni gba ki iru nkan bayi waye ninu ere idaraya lorileede Turkey”

Ikọ MKE Ankaragucu fi atẹjade sita nibi ti wọn ti fi ẹmi abamọ han pe ”Iṣẹlẹ to waye ni irọlẹ yi bawa ninu jẹ pupọ”

”A tọrọ aforijin lọwọ awọn ololufẹ ere bọọlu ni Turkey ati gbogbo eeyan to niẹ ere idaraya pata lori iṣẹlẹ to waye lẹyin ifẹsẹwọnsẹ MKE Ankaragucu ati Çaykur Rizespor to waye ni papa iṣere Eryaman.”

Ikọ Caykur Rizespor naa fi ọrọ ibanikẹdun si rẹfuri Meler ti wọn si ni ”patapata la bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ to waye lẹyin ifẹsẹwọnsẹ wa pẹlu Ankaragucu to waye lonii”

Ijiya nla n duro de Ankaragucu ati aarẹ ẹgbẹ wọn-TFF

Ajọ ere bọọlu Turkey TFF gbe igbesẹ ti wọn lawọn lero pe yoo mu ki alaafia jọba ni ere bọọlu ni Turkey.

Alaga TFF Buyukeksi sọ pe ”Ifẹsẹwọnsẹ ere bọọlu kii ṣe ogun,ko si pe boo ba o pa nibẹ.Kii ṣe gbogbo ẹgbẹ agbabọọlu ni fakọyọ nigba kannna.O yẹ ki ọrọ yi ye gbogbo wa.Gbogbo wa naa la ni lati ṣe ojuṣe wa.”

O fi kun pe ”Ankaragucu ati awọn oludari rẹ yoo jẹiyan wọn niṣu.”

O ni awọn yoo jiroro lori iru ijiya ti wọn yoo fi jẹ ikọ naa nibi ipade tawọn ba ṣe lọjọ Iṣẹgun.

Galatasary, ẹgbẹ agbabọọlu kan to gbajugbaja ti ṣaaju pe fun ipade pajawiri ti yoo fawọn ẹgbẹ agbabọọlu lanfaani lati koju nkan ti wọn ṣapejuwe gẹgẹ bi ”ọrọ to n rugbo bọ” lagbo ere bọọlu Turkey.

”Gbogbo wa la gbọdọ pawọpọ lati yanju iṣoro ti o kan gbogbo wa”

Bẹẹ ni Galatasary sọ ninu atẹjade kan ti wọn fi sita.

Ẹgbẹ awọn rẹfuri ni Turkey naa sọ pe ki awọn rẹfuri ma ṣe kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ kankan to si fi kun pe ”Ikọlu ti wn ṣe si Meler ko da lori oun nikan bi kii ṣe pe gbogbo awa rẹfuri ni wọn doju ija kọ”