Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa gbajúgbajà akàròyìn NTA, Aisha Bello tó jáde láyé

Aisha Bello

Oríṣun àwòrán, NTA

Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu ti ṣedaro iku ogbontarigi akaroyin to jade laye, Aisha Bello Mustapha.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Tinubu, Ajuri Ngelale buwọlu, o ni oloogbe naa jẹ okan gboogi lara awọn agbohunsafẹfẹ to lamilaka julọ ni Naijiria.

Atẹjade ọhun ni “O ko ọpọ awọn ọdọbinrin mọra lati tọ wọn sọna nipa iṣẹ igbohunsafẹfẹ latari bi wọn ṣe maa n wo o lori ẹrọ amohunmaworan.”

Ṣaaju ni Zainab Sabo, to jẹ ọrẹ oloogbe ọhun ti kọkọ fidi iroyin iku rẹ mulẹ, to si sọ pe wọn yoo ṣe adura si oku rẹ ninu mọṣalaṣi ijọba apapọ to wa niluu Abuja lọjọ Aje.

Iroyin ni oloogbe naa, to jẹ gbajugbaja akaroyin fun ọpọ ọdun lori ikanni NTA jade laye lẹyin aisan ranpẹ niluu Abuja.

Awọn ohun to yẹ ki omọ nipa Aisha Bello Muistapha ree

Inu oṣu Karun un, ọdun 2022 ni Aisha Bello fẹyinti, lẹyin to ti lo nnkan bii ọdun marundinlogoji nileeṣẹ igbohunsafẹfẹ ijọba apapọ, NTA.

Aisha jẹ ogbontarigi nidi iṣẹ akọroyin, to fi mọ iroyin kika, olootu eto ori tẹlifiṣọn ati bẹẹ bẹẹ lọ, ko to di ọga agba ileeṣẹ NTA Parliament ṣaaju ifẹyinti rẹ.

Ọna ara ti oloogbe naa fi n ka iroyin jẹ ki ọpọ eeyan nifẹ si ati maa wo o lọpọ, eyii to mu ko ni ipa rere nidi iṣẹ naa ni Naijiria.

Aarin ọdun 1990 si ibẹrẹ ọdun 2000 ni irawọ rẹ tan lori ẹrọ tẹlifiṣọn gẹgẹ bii akaroyin.

Aisha kawe gboye ẹkọ imọ akọroyin ‘Mass Communication/Media Studies’ ni fasiti Ahmadu Bello, to wa niluu Zaria, nipinlẹ Kaduna.