Wo bí afurasí ọmọ Nàìjíríà ṣe lu ìlú kan ní Canada ní jìbìtì $500,000

Aworan afihan ọdaran ti wọn so okun mọ lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ilé-ẹjọ́ kan lorilẹede Canada ti fẹsun jibiti owo to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta owo dọla, $500,000, kan ọmọ Naijiria kan, Ayoola Ajibade.

Ilé-ẹjọ́ naa salaye bi afurasi ọhun to n wa ọkọ Uber, ṣe gbiyanju lati lu ilu Bridgewater ni Nova Scotia ni jibiti $500,000.

Ileẹjọ ni Ajibade fi ara rẹ pe ọga agba ileeṣẹ kan nilu Nova Scotia.

O wa gba ilu naa lamọran lati san $490,930 sí ẹkun ile ifowopamọ Scotia kan to wa ni Brampton.

Gẹgẹ iṣẹ iwadii ṣe sọ, banki Scotia wa tọpasẹ rẹ lọ si ilu Bridgewater ati ileeṣẹ Dexter Construction ti Ajibade ní ibẹ loun ti n ṣiṣẹ.

Wọn ní Ajibade lo ni apo asunwọn to ni ki wọn sanwo si ni banki naa amọ kii ṣe oṣiṣẹ ileeṣẹ Dexter Construction, gẹgẹ bo se sọ.

Ajibade fún ra rẹ sọ fun ileẹjọ pe ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Andrew ni Naijiria lo ni ki oun ṣe iranwọ fun oun lori ati ra okoowo ni China.

Ileẹjọ ni Andrew jẹ ọrẹ Joshua, to jẹ ọkunrin kan ti Ajibade ti ba ṣiṣẹ pọ ri.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Sugbọn Ajibade ko mọ orukọ baba Joshua, bẹẹ ni ko mọ adiresi ile rẹ.

Ajibade jẹri pe lootọ ni oun fun Andrew ni apo asunwọn owo oun lai mọ ohun to fẹ fi se.

Leyin naa ni Andrew ni kí oun yẹ akaunti oun wo ki oun si fi $180,000 ranṣẹ si China ko le fi ra àwọn irinṣẹ kan.

Ajibade bu s’ẹkun nile ẹjọ, o ni oun ko mọ pé jibiti ni ọrọ naa yoo jasi.

Pẹlu gbogbo awijare rẹ, agbẹjọro olupẹjọ ni iwa jibiti nla ni Ajibade ju.

Ile ẹjọ yoo dajọ lori iru ijiya to tọ si Ajibade laipẹ.