Èmi kìí mu oògùn olóró tàbí ọ̀tí àmọ́ wèrè gidi ń bẹ lára mi – Portable Zazzu

Aworan Portable

Oríṣun àwòrán, Instagram/portablebaeby

Gbajugbaja olorin Fuji to tun ni Takansufe ninu (Hip Hop Fuji) Okikiola Badmus Abeeb, ti ọpọ eeyan mọ si Portable Wèrè olorin, ti salaye bi irin ajo aye rẹ se ri.

Portable, ẹni to di ilumọọka nitori orin Zazzu Zeh to kọ, eyi to jẹ itẹwọgba laarin awọn ọdọ lo salaye nipa igbe aye rẹ, ati bo se di gbajumọ olorin.

Portable lo sisọ loju ọrọ yii ninu ifọrọwerọ kan ti fidio rẹ gba ori ayelujara eyi ti oju opo Jahbless se fun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Olorin Zazzu naa, to ni Sango-Ota ni wọn bi oun si amọ to gbe Mushin-Olooṣa dagba salaye pe ilu Abuja ni oun ti bẹrẹ isẹ orin kikọ, ti oun si gbe ibẹ fun ọdun mẹwa.

Portable ni iya jẹ oun pupọ pupọ, koda nnkan le pupọ fun oun lasiko igbele Coronavirus, ti oun si dagba soju popo, ki Ọlọrun to mu ki ogo oun bu jade nidi isẹ orin kikọ.

Emi kii mu ọti tabi oogun oloro amọ were gidi wa lara mi:

Nigba to n salaye idi to se maa n binu, ja tabi sọrọ fata fata, eyi to mu ki ọpọ eeyan ro pe o n mu oogun oloro ni, akọrin Fuji-Hip PoP naa ni oun kii mu oogun oloro tabi ọti rara.

“Musulumi gidi ni mi, mo maa n gbadura lojoojumọ si Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ pe igboro ni mo gbe dagba, amọ n ko mu oogun oloro ri tabi mu ọti.

Emi ni mo ni orin Zazzu Zeh bi o tilẹ jẹ pe wọn fẹ yi mọ mi lọwọ, amọ were ara mi ni mo fi gba ara mi silẹ.”

Mo fi ile ẹkọ silẹ nitori orin kikọ to n mu owo wa fun mi, mo si ni orin to to irinwo nilẹ, ti mo fẹ kọ:

Bakan naa ni Portable ni oun ko ni iwe ẹri kankan lọwọ nitori pe oun ko jade nile ẹkọ rara nitori isẹ orin kikọ.

O fikun pe ile ẹkọ ni oun ti n kọrin gba owo, idi si ree ti oun se fi ẹkọ kikọ silẹ, ti Ọba Oke si jẹ ki ogo oun buyọ nidi isẹ naa.

Aworan Portable

Oríṣun àwòrán, Screen shot

“Owo wa nidi orin kikọ, a si le ri isẹ orin kikọ bii okoowo nla. Gbogbo were si ni mo be lọ sidi isẹ orin kikọ nitori iyanjẹ wa nibẹ.”

”Koda, orin to wa nilẹ ti n ko ti kọ to irinwo, mo si setan lati maa ko wọn sita bayii nitori nibayi ti mo ti di ilumọọka, ti orin kan si ti gbe ogo mi jade.”

Ọpọ obinrin lo n le mi kiri pe awọn nifẹ mi, mo si ni ọmọkunrin meji lati ọdọ iya ọtọọtọ:

Olorin Zazzu Zeh yii tun fikun pe bi o tilẹ jẹ pe oun ko tii ni iyawo nile bayii amọ oun ti bi ọmọkunrin meji lati ọdọ iya ọtọọtọ.

Aworan Portable

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

O fikun pe oun ni ọmọbinrin kan ti awọn ti dijọ n bọ ko to di pe ogo oun bu sita sugbọn obinrin naa ti n siwahu nibayii ti oun di ilumọọka, ti ogo oun si tan.

“Ọpọ awọn obinrin lo n le mi kiri pe awọn nifẹ mi, i love you, i love you ni nibi gbogbo, ko to di pe mo di ilumọọka ati lasiko ti mo di gbajumọ, to tiẹ wa su mi.

Idi si ree ti ọpọ wọn se n ba ọkan jẹ, ti wọn n ja ara wọn ni tanmọ, kii se emi ni mo n ja wọn kulẹ o, awọn ara wọn lo n ja ara wọn kulẹ.

Ohun to sokunfa bi wọn se ja mi si ihooho goloto ninu fidio kan ree:

Ninu ifọrọwerọ ninu fidio ori ayelujara naa ni Portable tun ti salaye nipa fidio kan to gba ori ayelujara kan, ninu eyi to ti wa ni ihooho ọmọluabi.

Fidio yii si lo ti lu ori ayelujara pa nibi ti ẹnikan ti n salaye pe ki wọn wo Portable olorin to ji kẹkẹ Maruwa.

Portable, ninu fidio naa lo wa ni ihooho bi Ọlọrun se sẹda rẹ, ti wọn si gbe kẹkẹ Maruwa ti wọn lo ji tii ni ẹgbẹ.

Aworan Portable

Oríṣun àwòrán, InSTAGRAM/portablebaeby

Nigba to salaye ohun to sokunfa isẹlẹ naa, akọrin Zazzu ọhun ni alagbata orin kan ti oun wa lọdọ rẹ nigba naa lo sisẹ laabi yii.

Bi o tilẹ jẹ pe ko darukọ ẹni naa amọ Portable ni alagbata orin naa lo sokunfa bi wọn se we irọ nla yii mọ oun lẹsẹ nitori pe oun tako asẹ rẹ.

“Mo maa n tẹle ọkunrin yii kaakiri, fun ọpọ ọdun, ti ko si se ohunkohun lati gbe orin mi larugẹ.Mo ni ko fi mi han awọn olorin nla nla to fi mọ Pasuma amọ ko se bẹẹ, ti gbogbo rẹ si su mi bi mo se n tẹle lẹyin.”

”Gẹgẹ bẹẹ se mọ pe were gan wa lara emi naa tẹlẹ, mo ba fa ibinu yọ lọjọ kan, ti mo si sọrọ buruku si, ibẹ lo si ti pe awọn ọdọ bii ọọdunrun jọ lati na mi.

O tẹsiwaju pe ”Wọn ja mi si ihooho goloto ti lọrun se ẹda mi, ti wọn si gbe kẹkẹ Maruwa kan si ẹgbẹ mi pe emi ni mo ji kẹkẹ naa. Wọn lu mi pupọ, Ọlọrun nikan lo yọ mi, ti n ko ba isẹlẹ naa lọ.”

Gbajumọ olorin naa wa parọwa si awọn eeyan to maa n se agbelarugẹ awọn olorin, ki aye le tete mọ wọn pe ki wọn se adinku bi wọn se maa n seto afihan ara wọn, yatọ si ohun ti akọrin n fẹ.