A ò jẹ́ Ọba mọ́ o! A ṣetán láti padà sí ipò Olóyè tí a wà tẹ́lẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Olubadan – Lekan Balogun

Awọn oloye Ibadan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ọtun Olubadan to waja Sẹnetọ Lekan Balogun ti sọ pe oun atawọn ẹgbẹ oun ti wọn gbega si ipo Ọba laye ijọba gomina tẹlẹ, oloogbe Abiola Ajimobi yoo pada si ipo ti wọn wa tẹlẹ gẹgẹ bii.

Otun Olubadan naa, ti Ade Olubadan kan lo sọ ọrọ ọhun ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Punch.

Ṣaaju ni Makinde ti kọkọ ni ki awọn Oloye naa pada si ipo ti wọn wa tẹlẹ, ki wọn tun pada si bi eto ifinijoye wọn ṣe wa tẹlẹ lọna ati yanju rogbodiyan to n waye lori ẹni ti ade Olubadan kan.

Olubadan

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Balogun ni “Imọran gomina Makinde tẹ wa lọrun nitori oun naa loun dari ijọba ipinlẹ wa… ohunkohun to ba fẹ ni a oo ṣe nitori itẹsiwaju ipinlẹ Oyo ati ilu Ibadan lo jẹ logun.”

Ṣaaju ni awuyewuye ti kọkọ n waye lori ẹtọ Otun Olubadan lati gori itẹ naa lẹyin iku Ọba Adetunji.

Asiko ijọba oloogbe Abiola Ajimobi ni wọn gbe awọn oloye naa ga si ipo ọba, ti wọn si bẹrẹ si n de ade, amọ Osi Olubadan, sẹnetọ Rashidi Ladoja , to ti fi igba kan jẹ gomina ipinlẹ naa ri, kọ lati gba igbega ọhun.

Olubadan

Oríṣun àwòrán, @Hrh_Olajuwon

Wayi o, lẹyin iku Ọba Adetunji ni agbẹjọro agba nipinlẹ naa tẹlẹ, Miheal Lana kọ lẹta si gomina Seyi Makinde lati má jẹ ki Otun Olubadan, iyẹn Lekan Balogun, de ipo Olubadan.

Lana sọ ninu lẹta naa pe niwọn igba ti awọn Oloye ọhun ti gba ade gẹgẹ bii Ọba, eyii ti Lekan Balogun jẹ ọkan lara wọn, ko bojumu ki wọn de eeyan kan naa lade lẹẹmeji nitori iru rẹ ko tii ṣẹlẹ ri nilẹ Yoruba.

Amọ awọn oloye naa fesi pada pe igbega ti ijọba fun awọn ko ni ki ẹnikẹni lara awọn má gori itẹ Olubadan to ba jẹ pe ẹni naa oye tọ si.

Wọn gvbe igbesẹ naa nibi ipade kan ti wọn ṣe aafin Olubadan lọjọbọ.

Lara awọn to wa nibi ipade naa ni awọn Oooye ti ọrọ naa kan, to fi mọ awọn Mogaji ka.

Osi-Balogun, Oloye agba Tajudeen Ajibola sọ fu awọn akọroyin lẹyin ipade naa gbogbo oun ti gomina Seyi Makinde ba n fẹ ni awọn yoo ṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Wọn fi kun pe Oloye ṣi ni awọn bo tilẹ jẹ pe wọn ti n dade.

Ẹwẹ, nigba ti Makinde lọ ṣabẹwo si ẹbi Olubadan to waja, o ni ko tii si irufẹ rogbodiyan bayii ri lori iyansipo Olubadan tuntun.

Makinde sọ pe ko si ṣaaju akoko yii nitori ilana ti wa nilẹ tẹlẹ nipa bi wọn ṣe n yan Olubadan mii ti ọkan gbesẹ.

O ni igbega ti ijọba Ajimobi fun awọn oloye ọhun lo da wahala ọhun silẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ