Akeredolu bẹ̀rẹ̀ ìsìnmi láti lọ tọ́jú ara rẹ̀, Aiyedatiwa yóò di adelé gómìnà l’Ondo

Aworan Aiyedatiwa ati Akerdolu

Oríṣun àwòrán, Hon. Lucky Orimisan Aiyedatiwa/Facebook

Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa, ni yoo di adele gomina nipinlẹ naa bẹrẹ lati Ọjọru ọjọ kẹtala oṣu kejila, odun 2023.

Akọwe gomina ipinlẹ naa, Richard Olatunde, lo fi eleyi lede ninu atẹjade kan to fi soju opo ibaradọrẹ facebook.

Olatunde wi pe Gomina Akeredolu n lọ fun isinmi lati lọọ tọ ju ara rẹ, leyi ti yoo mu ki igbakeji rẹ o dele fun un.

Atẹjade naa wi pe “Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu, SAN, CON, yoo bẹrẹ isinmi to nii ṣe pẹlu eto ilera ni Ọjọru, ọjọ kẹtala oṣu kejila, ọdun 2023, lati tẹsiwaju nipa itọju ara rẹ.

“Lakoko isinmi yii, Gomina Akeredolu yoo boju to ilera rẹ lati rii pe oun ni alaafia pipe ko too pada sẹnu iṣẹ.

“Iwe apinlẹkọ latọwọ gomina nipa isinmi yii ti yoo si fi fi agbaara silẹ nibamu pẹlu ofin orilẹede Naijiria ni yoo fi ṣọwọ sile aṣofin.

“lakoko ti Gomina Akeredolu ko fi nii si nile, igbakeji gomina, Lucky Orimisan Aiyedatiwa, ni yoo maa ṣe gbogbo ojuṣe gomina bii adele.

“Gomina Akeredolu dupẹ lọwọ awọ eeyan ipinlẹ Ondo fun atilẹyin ti ifẹ wọn. O si n fi dawọn loju pe iṣejọba ohun ko nii jakan lọna idagbasoke ati itẹsiwaju to n tọ.”

Ṣaaju igbesẹ yii ni ariwo ti gba igboro ipinlẹ latọwọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako pe ki Akeredolu o gbejọba silẹ fun igbakeji rẹ, ko si gbajumọ bi yoo ṣe lalaafia.

Bakan naa ni awọn kan ti wọn jẹ alatilẹyin fun igbakeji gomina naa n beere fun igbalaaye labẹ ofin lati sọọ di adele gomina.

Ẹwe, awọn kan to jẹ alatilẹyin Akeredolu ni wọn wi pe ko si ohun ti yoo mu Akeredolu gbe ijọbasilẹ fun igbakeji rẹ nitori pe o ṣi ni alaafia to lati tẹsiwaju gẹgẹ bii gomina ipinlẹ naa.