Wo àtúpalẹ̀ àbá ìsúná N294.5bn fún 2022 tí Seyi Makinde gbé lọ́ sí ilé aṣòfin

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, oyo state government

L’Ọjọru ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde gbe Aba Iṣuna ti akojọpọ rẹ jẹ N294.5bn lọ si ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ fun eto ẹnawo ọdun 2022.

Makinde ti o pe akori Aba Iṣuna naa ni “idagbasoke ati anfani”, ṣe alaye wi pe ijọba oun ni ipinnu lati mu ipinlẹ naa kuro ninu oṣi lọ si inu iṣerere.

Wọnyii ni atupalẹ Aba Iṣuna naa;

Awọn akanṣẹ iṣẹ yoo na ijọba ni N156 billion ti o si jẹ ida 52.97% ninu Aba Iṣuna naa, nigbati eto ẹnawo atigbadegba jẹ N138.5 billion, eleyii too tumọ si ida 47.03%.

Ayẹwo Aba Iṣuna naa fi idi ẹ mulẹ pe ipese awọn ohun elo amayedẹrun yoo gba N96.6 billion, ti o jẹ ida 32.83%, gẹgẹ bi ẹka eto ẹkọ yoo ṣe tẹwọ gba N54.1b ti iṣiro rẹ jẹ ida 18.37%.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Seyi Makinde ati Olori ile asofin ipinlẹ Oyo, Ogundoyin

Oríṣun àwòrán, oyo state government

Ẹka eto ilera ko N17.4b, eleyii ti o jẹ ida 5.9% ninu Aba Iṣuna naa, nigba ti ẹka eto ọgbin yoo tẹwọgba N11.3b ti o jẹ ida 3.84%.

Makinde ni adinku to le ni da mejidinlogun ni Aba Iṣuna ọdun 2022 fi yatọ si ti eleyii ti o waye ni ọdun 2021.

O tẹsiwaju wi pe owo ti yoo gbọ bukata Aba Iṣuna ti ọdun 2022 yoo di wiwa nipasẹ owo ti ijọba ipinlẹ naa ba pa labẹnu, owo to n ti ọwọ ijọba apapọ wọle ati awọn owo to n wọle ni ọna mii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ