Ẹ kú oríire oo! Ìjọba Nàìjíríà buwọ́lù ìsinmi ọwọ́ lómi ọlọjọ́ 14 fáwọn bàbá ikoko tuntun

Babalọmọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìjọba Nàìjíríà buwọ́lù ìsinmi ọlọjọ́ mẹrinla fawọn bàbá ikoko tuntun

Paternity leave in Nigeria for men:Wò bí o ṣé lè jẹ́ anfààní ìsinmi ọjọ mẹ́rìnlá tí ìyàwó rẹ̀ bá bímọ tuntun

Iroyin ayọ leleyi fawọn baba ikoko tuntun to ti n beere fun isinmi irufẹ eleyi ti awọn iyawo wọn maa gba lẹyin ti wọn ba bimọ.

Ijọba apapọ Naijriia ti buwọlu ọjọ mẹrinla isinmi fawọn baba ikoko ki awọn naa le ribi tọju ọmọ.

Igbimọ alaṣẹ Naijiria ti igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo dari lo faṣẹ si isinmi yi fawọn oṣisẹ ijọba apapọ.

Olori awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ Folasade Yemi-Esan lo fidi ọrọ yi mulẹ fawọn akọroyin ni Abuja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Arabinrin Yemi-Esan ni wọn yoo ka ounka ọjọ yi pẹlu iye ọjọ ti wọn lo lẹnu iṣẹ dipo lilo ounka kalẹnda oṣu.

Pataki igbesẹ yi bo ti se ṣalaye ni pe yoo fun awọn baba ikoko lanfaani lati ribi fifẹ rinlẹ laarin awọn ati ọmọ wọn ba bi tabi eleyi ti wọn gba tọ.

Amọ ni ti ọmọ ti wọn ba gba tọ yi, anfaani yi yoo kan eyikeyi baba ti ọmọ naa ko ba kọja oṣu mẹrin lọ.

Awọn ijọba ipinlẹ Naijiria lo maa n da iye ọjọ isinmi fawọn baba ikoko ti eleyi ko si kọja ọjọ mẹwaa lọ.

Bawo ni Naijiria ṣe n ṣeto isinmi fawọn baba ikoko tẹlẹ

Loṣu Karun ọdun 2018 awọn aṣofin ile aṣojuṣofin wọgile abadofin kan eleyi ti yoo fun awọn ọkunrin lẹka aladani ati awọn to n ba ijọba ṣiṣẹ ni anfaani isinmi lẹyin ti iyawo wọn ba bimọ.

Ọkan lara awọn nkan ti wọn n mẹnu ba ni pe bawo ni wọn ṣe fẹ ṣe fawọn ọkunrin to ba ni iyawo pupọ.

Ko fẹẹ ju ipinlẹ meji lọ ni Naijiri to ni ofin isinmi ibimọ fawọn baba ikoko tuntun.

Lọdun 2014,ipinlẹ Eko buwọlu isinmi ọlọjọmẹwa fawọn oṣiṣẹ ijọba baba ikoko tuntun.

Awọn orileede mi ti ofin paternity leave fẹsẹ rinlẹ

Ajọ oṣiṣẹ lagbaye ILO sọ pe isinmi fawọn baba ikoko tuntun wa ninu ofin awọn orileede mọkandinlọgọrin.

Ninu awọn taa n wi yi, mọkandinlọgbọn wa lati ilẹ Afrika.

Ni Tunisia, isinmi ọjọ kan ni baba ikoko yoo jẹ lanfaani nigba ti Morocco ati Tanzania fi aaye isinmi ti ko pe ọsẹ kan kalẹ fawọn baba ikoko tuntun.

Benin a maa fun baba ikoko ni ọjọ mẹwaa ti Kenya si ya ọsẹ meji silẹ lọjọ isinmi