Ìdí tí mo fi ń dé fìlà Abetiaja nì gbogbo ìgbà nìyìí – Alaafin

Alaafin Oyo

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oyo

Ọba Lamidi Adeyemi to jẹ alaafin Oyo ti ṣi aṣọ loju idi to fi jẹ pe fila Abetiaja ti di ami idamọ rẹ nibikibi.

Iku baba yeye ni Ade ko gbudọ jẹ ohun teeyan n de bi ẹni n mu omi ni gbogbo igba nitori ara ọtọ to jẹ ati pataki ẹwa aṣa lara rẹ. Kabiyesi fi kun un pe ọpọ Ọba lo ti sọ Ade wọn di nkan afẹfẹyẹyẹ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti Ọba Lamidi ṣe laipẹ pẹlu iwe iroyin Nigerian Tribune ni oriade naa ti yanana rẹ pe “nkan adiitu ni Ade. Oun ni o jẹ nkan iyebiye julọ ninu gbogbo ifarahan ati imura Ọba.”

Alaafin ni Ade gangan lo n sọ itumọ pataki Ọba. Ọba Yoruba maa n wọ Ade fun eredi aṣa, iṣẹmbaye ati ẹsin. Fun apẹrẹ “lasiko awọn ayẹyẹ, iru iyi ati ẹyẹ to maa n wa fun Ade ko lafiwe”.

Alaafin Oyo

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oyo

Gẹgẹ bi agba ati ọkan pataki ninu awọn Ọba nla ilẹ Yoruba to ti fẹrẹẹ lo aadọta ọdun lori apere, Ọba Adeyemi ni “o yẹ ki awọn araalu maa reti pẹlu inu didun lati ri iru Ade ti Ọba yoo de jade ni.

Bi ẹẹkan ṣoṣo lo yẹ ki ẹlomiran ri ade Ọba soju ni gbogbo aye rẹ amọ wọn lee maa rii nini fọto ti Ọba de Ade sori”.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Alaafin beere pe “igba melo ni wọn n ri alayeluwa Ọbabinrin ti ilẹ Gẹẹsi ko de ade rẹ? Oun tẹẹ ma n ri lori rẹ ni ate. Ko tọ lati maa ri ki olori ilu maa wọ ade wọn lọ si ibi gbogbo ati gbogbo ipade tabi ode”.

Alaafin ni nibi ti awọn Ọba mii sọ ade wọn di yẹyẹ de, ẹ o tun rii ti wọn n gbe ọpa aṣ kiri koda oriṣiriṣi to ni oniruuru awọ lọ ibi gbogbo.

Koda bi awọn ara ilu wọn o ba sọọ ni gbangba, inu wọn o le dun sii.

Alaafin Oyo

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oyo

Nigba to n sọ idi to ṣe maa n tẹra mọ abetiaja, o ni “fila abetiaja jẹ ọna lati fi ọrọ ranṣẹ, ẹ o ri pe wọn ran lọna to fi jọ eti aja. Bi mo dẹ ṣe maa n tẹ eti kọọkan rẹ n fi ọrọ ranṣẹ”.

O ni nkan teeyan n sọ bi eti kanba duro gbọọrọ soke ti ekeji si dubulẹ. Bakan naa bi mejeeji ba jọ duro gbọọrọ soke tabi ti wọn jọ dubulẹ, o ni ọrọ ti ẹni naa n sọ.

“Itumọ awọn ọrọ naa fasin, ẹni ti oye Yoruba ba ye daadaa lo mọ. Eyi jẹ ọkan lara awọn nkan aṣa ajogunba Yoruba”.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ