Tinubu, Oluwo kẹ́dùn ikú Olubadan, Oba Lekan Balogun

Aworan Olubadan

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti fi ọrọ ibanikẹdun sita lori ipapoda Olubadan ti ilu Ibadan, Oba Lekan Balogun.

Ọjọ́bọ, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun 2024, ni Oba Balogun waja lẹ́ni ọdun mọkanlelọgọrin.

Tinubu sọ pe pẹlu ibanujẹ ni oun gba iroyin iku kabiyesi.

Ninu atẹjade to fi sita lati ọwọ agbẹnusọ rẹ, Ajuri Ngelale, Aarẹ Tinubu ṣapejuwe kabiyesi gẹgẹ bi ọba to tayọ, to si lo ìtẹ́ atayebaye rẹ fun sísin ọmọniyan.

“Ẹlẹyinju aanu, akinkanju, ati ẹni to polongo alaafia, otitọ ati iṣọkan ni Olubadan. Ao ṣe afẹri imọran ọlọgbọn rẹ niru akoko bayii lorile-ede wa.”

O ni oun ba ẹbi Olubadan, ijọba ipinlẹ Oyo, igbimọ Olubadan, to fi mọ awọn ọmọ bibi ilẹ Ibadan ati gbogbo ipinlẹ Oyo kẹdun lori adahun nla naa.

Ninu ọrọ tìrẹ naa, Oluwo ti Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, sọ pe adanu ti ko ṣe e gbagbe ni iku Oba Lekan Balogun, jẹ́ laarin awọn ọba, paapaa nilẹ Yoruba.

Oluwo sọ pe “ẹni amuyangan ati awokọṣe rere, to ṣojú ẹbi ati ilẹ Ibadan kárakára ni Ọba Balogun.

Seyi Makinde kéde pé Oba Lekan Balogun wàjà, wọn yòó sin-ín ní ìrọ̀lẹ́ òní

Aworan Olubadan

Oríṣun àwòrán, Oba Moshood Lekan Balogun

Gomina Ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ti kede ipapoda Olubadan kejilelogoji ti ilẹ Ibadan, Kabiyesi alayeluwa, Oba Dr. Moshood Lekan Balogun Alli Okunmade Keji.

Gomina Makinde kede eyi ninu atẹjade kan ti o buwọlu ni alẹ Ọjọbọ ọjọ kẹrinla oṣu kẹta ọdun yii.

Atẹjade naa ṣalaye wi pe Kabiyesi darapọ mọ awọn baba nla rẹ ni irọlẹ Ọjọbọ ni ile iwosan UCH ti ilu Ibadan.

Gomina Makinde ṣapejuwe Oba Balogun gẹgẹ bi eeyan ti iwa rẹ wu ni lori.

Bakan naa lo ni ba Balogun ṣe iṣẹ to laami-laaka ni ilẹ Ibadan laarin Ọdun meji to lo lori aleefa gẹgẹ bi Olubadan.

Makinde ninu iwe ikedun rẹ́, kí igbimọ apapọ oloye Olubadan (Olubadan-in-Council) Igbimọ lọba lọba ipinlẹ Oyo, awọn ara ilu Ibadan ati ipinlẹ Ọyọ lapapọ.

Ninu ọrọ ibanikẹdun rẹ, Makinde ṣapejuwe ipapoda Ọba Balogun gẹgẹ bi Iroko nla to ṣubu.

O ni iṣejọba rẹ fihan wi pe o ni iriri pupọ eleyii ti o si jẹ ko tayọ ninu awọn Ọba to ti jẹ ṣaaju ni ilẹ Ibadan.

O kí idile Ọba Mashood Lekan Balogun ku ara fẹ́raku, to si gbadura wi pe ki Ọlọrun fori jin aṣiṣe Kabiyesi ọhun.

Ọdun mọkanlelọgọrin ni Kabiyesi lo laye, kí wọn to gbeṣẹ̀`.

Isinku yoo waye lọjọ Ẹti

Aworan ayẹyẹ ibi ti Gomina Makinde ti gbe ọpa aṣẹ fun Olubadan

Oríṣun àwòrán, Oyo State Govt

Ẹwẹ, a ti gbọ pe isinku Ọba Balogun yoo waye ni ilana ẹlẹsin musulumi lọjọ Ẹti.

Olubadan ṣẹṣẹ lo ọdun meji lori aleefa ni ki ọlọjọ to de.

Mọlẹbi kan to fi ọrọ to awọn akọroyin leti sọ pe, ni agboole Olubadan ni Alli-Iwo, ni isinku naa yoo ti waye laago mẹrin ọsan.

Ọpọ ọmọ, iyawo ati ọmọ ọmọ lo gbẹyin Olubadan.