Ọ̀pọ̀ èèyàn farapa níbi ìkọlù sí ọba alayé Àgọ́ṣàṣá ní ìpínlẹ̀ Ògùn

Aworan ẹkùn mẹta ijọba ipinlẹ Ogun

Rogbodiyan kan bẹrẹ lọjọ Aiku, ọjọ kẹwaa oṣu kẹta ọdun 2024 yii niluu Agọṣaṣa, ijọba ibilẹ Ipokia, ipinlẹ Ogun, latari ikọlu tawọn kan ṣe si Ọba Azeez Akinpẹlu ti i ṣe ọba ilu naa.

Gẹgẹ bi alaye awọn eeyan tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn, wọn ni awọn kan kọlu Kabiesi naa laipẹ yii, nitori ariyanjiyan to waye lori ọdun ibilẹ tawọn eeyan naa n ṣe.

Itosi Aafin Ọba Akinpẹlu ni awọn to n ṣe eto ibilẹ naa ti n ṣe e ba a ṣe gbọ, wọn ko si gbaṣẹ lọwọ Kabiyesi ki wọn too bẹrẹ.

Eyi ni wọn lo bi ọba naa ninu to si ni ki wọn dawọ rẹ duro bi wọn ko ba le waa gba aṣẹ lọwọ oun gẹgẹ bi ọba.

Ṣugbọn awọn ọdọ kan nibi eto naa ti ko fẹ Akinpẹlu loye tẹlẹ binu si eyi. Wọn lawọn ko nilo aṣẹ rẹ, awọn to n ṣe oro ibilẹ ko si le da eto wọn duro nitori aṣẹ Ọba Akinpẹlu.

Ọrọ naa di wahala, a gbọ pe wọn bẹrẹ si i ju oriṣiiriṣii nnkan lu ọba alaye yii, awọn alatilẹyin rẹ naa si da a pada fawọn igun keji gidi.

Ìkọlù tẹ̀síwájú lọ́jọ́ kejì láàrin ọjà

O ṣoju mi koro naa tẹsiwaju pe lọjọ keji iṣẹlẹ akọkọ ni awọn janduku kan tun kọlu Kabiyesi Akinpẹlu laarin ọja.

O ni rogbodiyan naa di ohun ti ọpọ eeyan da si, bẹẹ ni eeyan pupọ farapa nigba tawọn janduku bẹrẹ ikọlu yii.

Gẹgẹ bo ṣe wi, awọn eeyan kan ti sa kuro l’Agọṣaṣa bayii, nitori ibẹru ikọlu mi-in to tun le waye.

Kí ló ṣẹlẹ̀ táwọn kan fi ń bínú sí ìyànsípò Ọba Akínpẹ̀lu?

Oṣu keji ọdun 2022 ni Ọba James Elegbede to jẹ ọba akọkọ l’Agọṣaṣa waja, yiyan ọba mi-in sipo naa si mu ariyanjiyan dani.

Lọjọ kẹrinla oṣu kẹsan-an ọdun 2022 naa, ko din ni eeyan mẹta to padanu ẹmi wọn latari rogbodiyan to bẹ silẹ nitori ipo ọba yii.

Awọn ọdọ ilu figba kan fẹhonu han lori ondije kan, wọn ni oloṣelu kan lo n ti i lẹyin, awọn ko si fẹ ẹ nipo ọba.

Ọdun 2023 ni Gomina Dapọ Abiọdun fọwọ si iyansipo Ọba Azeez Akinpẹlu.

Ikunsinu atigba naa la gbọ pe ko ti i tan nilẹ lasiko yii, to fi dohun ti wọn n kọlu ọba.