Bí ẹ kò bá san Bílíọ́nù kan Náírà, March 26 ni á pa akẹ́kọ̀ọ́ 287 tí a gbé pamọ́ – Ajínigbé

Awọn ajinigbe

Oríṣun àwòrán, @DefenceInfoNG

Awọn ajinigbe ti wọn ji akẹkọọ 287 ati awọn olukọ kan gbe ni Kaduna laipẹ yii tí beere fun biliọnu kan naira owo itusilẹ ki wọn too le yọnda wọn.

Bi owo naa ko ba tẹ wọn lọwọ laarin asiko yii sí ọjọ kẹrìndinlọgbọn, oṣu kẹta ọdun 2024, awọn ajinigbe naa ni awọn yoo pa awọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ̀ọ́ to wa nigbekun wọ́n danu ni.

Gẹgẹ bi ẹka iroyin Reuters ṣe gbe e jade, Jubril Aminu to n ṣoju awọn ti wọn ji eeyan wọn gbe ni awọn ajinigbe naa pe lorii foonu.

Ọjọ Iṣẹgun ni wọn pe e pẹlu ikilọ iku, pe bi owo ọhun ko ba fi tẹ awọn lọwọ, iku ni fawọn eeyan naa.

Ọjọ keje oṣu kẹta 2024 yii ni wọn ji awọn akẹkọọ ati awọn oṣiṣẹ ileewe LEA Primary School ati Government Secondary School, Kuriga, ni Kaduna, gbe. Lati ọjọ naa ni wọn si ti n ka gbedeke ti wọn fun wọn lati sanwo itusilẹ yii.

Ibi inira ni wọn ko awọn ti wọn ji gbe si. Wọn n lo wọn bíi gàgá ti ko ni i jẹ k’awọn ologun ilẹ Naijiria wọle sọdọ wọn ni.

”Eeyan 493 lo wa nigbekun ajinigbe”

Ko din ni eeyan 493, ẹẹdẹgbẹta din meje ti wọn wa nigbekun ajinigbe bayii ni Kaduna, Borno ati ipinlẹ Sokoto.

Olori ogun to n ri si eto iroyin lorilẹ-ede yii, Maj. Gen Buba Edward, sọ fawọn akọroyin l’Ọjọbọ pe awọn ajinigbe n ji awọn alaiṣẹ gbe nitori bawọn ṣọja ṣe n kọlu wọn ni.

‘’Ojo ni awọn ajinigbe yii, wọn ti mọ pe a ko ni i pẹẹ kapa awọn ni wọn ṣe n ji awọn akẹkọọ atawọn to wa nibudo ogunlende gbe.

Tẹ ẹ ba n wo bi a ṣe n ṣiṣẹ wa, ẹ maa ri i pe a ti pa olori wọn pẹlu awọn ọmọ ogun wọn ninu ikọlu to kọja.

Wọn ri i pe a ti n faye ni wọn lara ni wọn ṣe n ji awọn eeyan ti ko le gba ara wọn silẹ yii gbe.

‘’Ọrọ aabo la n sọ yii, a gbọdọ tun un sọ, ka gba ọna mi-in yatọ si ti tẹlẹ, ka le ri esi to daa gba jade’’ Bẹẹ ni Ọgagun Buba Edward ṣalaye.

A kò ní san 10 kọbọ láti gba ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 287 tí wọ́n jígbé ní Kaduna – Ìjọba àpapo

Ijọba apapọ ti sọ pe oun ko ni san owo kankan lati gba itusilẹ awọn akẹkọọ to le ni 287 ti awọn agbebọn ji gbe nile ẹkọ wọn nipinlẹ Kaduna.

Ile ẹkọ Government Secondary School ati ile ẹkọ alakọbẹrẹ LEA Primary School to wa ni Kuriga, Kaduna ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Ijọba ni ijọba ilẹ Amẹrika atawọn orilẹ-ede mii ti dide iranlọwọ lati doola awọn ọmọ naa, oun si n gbe awọn iranlọwọ naa yẹwo lati mọ boya oun yoo tẹwọ gba a.

Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Minisita eto iroyin, Mohammed Idris lo sọ ọrọ naa fun awọn akọroyin nile ijọba to wa niluu Abuja.

O ni “Aarẹ ko faramoo sisan owo itusilẹ rara, o si ti paṣẹ pe ẹnikẹni ninu ijọba ko gbọdọ san owo itusilẹ kankan fun eyikeyi ninu awọn ọdaran naa.”

Idris fidi rẹ mulẹ pe awọn oṣiṣẹ eto abo n ṣiṣẹ karakara lati ri pe wọn doola awọn akẹkọọ naa, ati pe oun gbagbọ pe ayọ ati alaafia lawọn akẹkọọ ọhun yoo pada wale.

Ọrọ yii lo n waye lẹyin nnkan bii wakati mẹrinlelogun ti olukọ ẹsin Islam, Sheikh Ahmad Gumi jọwọ ara rẹ lati lọ dunadura pẹlu awọn ajinigbe naa lọna gba itusilẹ awọn ọmọ ọhun.

Gumi sọ pe ki ijọba fun oun lanfani lati lọ ba awọn ajinigbe naa sọrọ ki ipadawale awọn akẹkọọ ọhun le ya kankan.

O kilọ pe ijọba ko gbọdọ ṣe aṣiṣe ti ijọba Muhammadu Buhari ṣe lẹyin to kọ lati dunadura pẹlu awọn agbesunmọmi.

Ọjọ keje, oṣu Kẹta, ọdun 2024w yii ni awọn agbebọn naa ṣadede yabo ilu Kuriga, ni ijọba ibilẹ Chikun, nibi ti wọn ti ji awọn akẹkọọ ati olukọ wọn gbe lọ nile ẹkọ mejeji.

Awọn olugbe agbegbe naa sọ fun awọn akọroyin pe ẹnu lọlọ yii ni wọn ṣẹṣẹ ko awọn akẹkọọ ile ẹkọ girama to wa nibẹ lọ si ibi ti awọn alakọbẹrẹ wa lọna ati daabo bo lọwọ irufẹ ijinigbe bayii.

Ṣaaju iṣẹlẹ Kaduna yii ni awọn agbebọn kan ti kọkọ lọ ji awọn ogunlende to le ni 200 gbe lọ nipinlẹ Borno lasiko ti wọn lọ wa igi idana ninu igbo.

Ile itura ti ijinigbe ti waye

Egbinrin ọtẹ, bi a ṣe n pana ọkan ni omiran n ru.

Awọn ajinigbe ti ẹnikẹni ko mọ ẹyẹ to ṣu wọn, ti ji ọmọ ilẹ China gbe lọ ni ipinlẹ Kwara.

Ni agbegbe Eyenkorin, to wa nijọba ibilẹ Asa ni isẹ̀lẹ̀ ijinigbe naa ti waye.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, awọn ajinigbe naa ti wọn to mẹfa niye, ni wọn yawọ ile itura ti oyinbo naa de si ni Eyenkorin, ti wọn si ji gbe lọ.

Alakoso ile itura ọhun, ọgbẹni Idume David Joseph lo fi iṣẹlẹ naa to awọ̀n ọlọpaa leti.

Oyinbo ọmọ ilẹ China naa, Williams Yang lo ti wa ni ile itura ọ̀hun lati bi oṣu meji sẹyin.

“Iro ibọn lo le mi wọle nibi ti mo ti n gba atẹgun nita ile mi nitori ooru to mu”

Ọkan lara awon ara adugbo ti iṣẹlẹ naa ti waye, Kunle Olanrewaju sọ fun BBC News Yoruba pe iro ibọn lo le oun wọle nibi ti oun ti n gba atẹgun nita nitori oru to mu.

Olarenwaju ṣalaye pe bi awọn ajinigbe naa ṣe de ni wọn da ibọn bolẹ ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ.

O ni wọn si ji oyinbo naa gbe lọ ati pe iṣẹlẹ naa ti da ibẹru bojo kalẹ si agbegbe ọhun.

Ọwọ tẹ afurasi mẹta ti wọn lọwọ ninu ìṣẹ̀lẹ̀ ijinigbe naa, iwadii si n tẹsiwaju -Ọlọ́pàá

Nigba to n fidi isẹ̀lẹ̀ naa múlẹ̀, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Victor Olaiya sọ pe, loju ẹsẹ ti iṣẹlẹ naa de etigbọ awọn ọ́lọ́pàá, lawọn ti fi ikọ eleto aabo ṣọwọ si ile itura naa.

Kọmiṣanna ọlọpaa ọhun wa parọwa sawọn araalu lati ma ṣe bẹru nitori awọn n sa ipa awọn lati pese eto aabo to gbopọn fun tolori tẹlẹmu.

Agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, arabinrin Ejire Toun Adeyemi sọ pe ọkọ ayọkẹlẹ alamojuto ile itura naa ni wọn fi gbe oyinbo naa lọ, ti wọn si pada ri ọkọ naa ni opopona marosẹ Ilorin si Ogbomoso.

Agbẹnusọ ọlọpaa ọhun ni ọwọ ti tẹ awọn afurasi mẹta ti erongba wa pe wọn lọwọ ninu ijinigbe naa ati pe iwadii si n tẹsiwaju.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí