Tinubu ló yọ ìpínlẹ̀ Eko kúrò nínú irà- Shettima

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Igbakeji oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Kashim Shettima ti ni bi ipinlẹ Eko ṣe wa gẹgẹ bi ipinlẹ to lamilaka ju lorilẹede Naijiria lonii ko sẹyin iṣẹ ribiribi ti oludije sipo aarẹ APC ṣe nigba to wa nipo gomina.

Shettima sọ eyi nigba to n sọrọ ni ipinlẹ Eko lọjọ Aje ọjọ kẹtalelogun, oṣu kiini ọdun 2023.

O ni ṣaaju ki Asiwaju to jẹ gomina, ọpọ eeyan lati apa ariwa Naijiria ni ko fẹran lati ma wa si ipinlẹ Eko ṣugbọn ti ọrọ yipada lẹyin ti Tinubu tun gbogbo Eko ṣe.

“Ira ni Eko nigba kan sugbọn nigba ti Asiwaju lo ọgbọn ati oye rẹ, ayipada ti deba ipinlẹ Eko, to si sọ Eko di ipinlẹ ti ọrọ aje rẹ gbooro si.

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Borno fi kun pe ti awọn ọmọ Naijiria ba fun Tinubu ni anfani lati mu oye ati iriri rẹ wa to ba di aarẹ, ọrọ aje orilẹede Naijiria yoo gbooro si.

O wa pe fun pe ki awọn eeyan tu sita lati dibo fun Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC.

“Mo fẹ rọ yin pe ki ẹ dibo fun ẹni to tẹsiwaju iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari, ẹni to ni iwa, ọpọlọ ati oye ti wọn fi n ṣe ijọba.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, Tinubu gba iwuri lati apa ariwa gẹgẹ bi oludije nitori to ni amuyẹ lati fi koju ipenija aabo to n ba awọn eniyan naa finra.

“Awa ti a wa lati apa Ariwa mọ pe a jẹ Tinubu ni oore ọpẹ bi o ṣe ṣe atilẹyin fun aarẹ Buhari lọdun 2015 ati 2019 ninu eto idibo”

Ẹ dìbò fún APC láti fòpin sí ìkọlù àti ìjínigbé ní Nàìjíríà 

Aworan Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, others

Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu tí rọ awọn ọmọ Orilẹede Naijiria lati dibo yan ẹgbẹ oṣelu APC ati oun naa lati mu ilọsiwaju deba Orilẹede Naijiria ati lati fi opin si gbogbo rogbodiyan ijinigbe ati ikọlu to n waye.

Nigba to n sọrọ yii níbi eto ìpolongo ibo niluu ìlu Ilorin, olu ilu ipinlẹ Kwara lana, Tinubu ni ẹgbẹ oṣelu APC nìkan to gbena awọn rogbodiyan to n waye lorilẹede Naijiria.

“Ẹ fi igbalẹ gba iwa jẹgudujẹra, ole ati ijinigbe ninu eto ìdibo to n bọ.

“Loni, a n ṣe ayẹyẹ òmìnira. A n fi da ara wa loju lori òmìnira wa

.”Lana, wọn ko gbagbọ pe eleyi le sẹlẹ sugbọn o ṣẹlẹ lasiko ti yín.”A dupẹ lọwọ yín bí ẹ ṣe ni igbagbọ ninu Abdul Rahman AbdulRazaq. Eeyan nla ni, olódodo eeyan ni.

“Ẹ díbọ yan mi gẹgẹ bii aarẹ Orilẹede Naijiria ninu oṣu kejì, ẹ díbọ fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, lati ori gomina, sẹnẹto ati awọn ọmọ igbimọ ile aṣofin lorilẹede Naijiria.”

Tinubu ni bíi ẹgbẹ oṣelu APC ṣe borí ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2015 ti fi ọkan awọn eeyan ipinlẹ naa baalẹ sugbọn o rọ lati tubọ ni igbagbọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC.