Igbákejì Gómìnà tẹ́lẹ̀rí Agboola Ajayi jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò abẹ́lé PDP l’Ondo

Aworan Agboola Ajayi

Igbakeji gomina ipinle Ondo teleri, Agboola Ajayi ti jawe olubori ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ Oṣelu PDP.

Eleyii tumọ si pe Ajayi ni yoo du ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ PDP ninu eto idibo ti yoo waye ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu kọkanla ọdun 2024.

Alaga igbimọ ẹlẹni meje to dari eto idibo naa nipinlẹ Ondo ti i ṣe Igbakeji Gomina Ipinlẹ Bayelsa, Sẹnẹtọ Ewhrudjakpo Oborawhartevwo lo kede Ajayi gẹgẹ bi ẹni to bori.

Ajayi ni ibo ọta le lugba ati mẹrin lati fagba han awọn oludije mẹfa to ku.

Oborawhartevwo kede pe awọn to ku, Olusola Ebiseni ni ibo 99, Kolade Akinjo 157, Adeolu Akinwunmi 64, John Mafo 9, Benson Akingboye Bamidele 24 ati Arebuwa Bosun ni ibo meji pere.

Igbakeji Gomina ipinlẹ Bayelsa naa sọ pe awọn asoju 627 lo forukọ silẹ lati dibo sugbọn 621 lo kopa ninu eto idibo naa.

O ṣalaye pe eto idibo naa waye lai si wahala kankan ti gbogbo awọn oludije si figa gbaga ni ilana ofin eto idibo ẹgbẹ oṣelu PDP ati ti orilẹede Naijiria ti o safimọ rẹ pe gbogbo eto naa ni wọn ṣe lai fi igba kan bọkan ninu.

Oborawhartevwo dupẹ lọwọ awọn asọju ijọba ibilẹ ti wọn kopa ninu eto idibo naa lati yan ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ wọn ninu eto idibo sipo Gomina to n bọ lọna fun iwa omoluwabi ti wọn hu lasiko eto idibo naa.

Oborawhartevwo wa rọ awọn oludije to ku lati fọwọ sowọpọ pẹlu ẹni to jawe olubori ki ẹgbẹ PDP le pegede ninu eto idibo gomina oṣu kọkanla to n bọ.

O fikun ọrọ rẹ pe akoko ti to wayi fun ẹgbẹ PDP lati gba Ipinlẹ Ondo pada fun itesiwaju Ipinlẹ naa ki tẹru tọmọ le janfani ijọba awarawa.

Ètò ìdìbò abẹ́lé PDP láti yan olùdíje fún ipò gómìnà l’Ondo ti gbérasọ

Aworan aṣoju ẹgbẹ PDP

O keretan awọn asoju 627 jakejado ijọba ibilẹ mejidinlogun lo ti pejọ si gbọngan Dome n’iluu Akure lati dibo yan ẹni ti yoo gbe asia ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo gomina ipinlẹ Ondo oṣu Kọkanla ọdun yii.

Awọn adari ẹgbẹ PDP ti ṣagbekale igbimọ ẹlẹni meje ti yoo bojuto eto idibo abẹle ẹgbẹ naa eyi ti igbakeji Gomina Ipinlẹ Bayelsa Sẹnẹtọ Ewhrudjakpo Oborawhartevwo saaju.

Awọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ naa ni Oluwole Busayo Oke, Muktar Ahmed, Hassana Diko, John Mathew, Họnọreebu Nnena Ikondon ati Dare Adeleke.

Awọn meje ti wọn n dije sipo naa ni igbakeji Gomina Ipinlẹ Ondo tẹlẹri, Agboola Ajayi, Akọwe gbogbogbo ẹgbẹ Afenifere teleri, Oloye Olusola Ebiseni, Kolade Akinjo; Adeolu Akinwunmi, John Mafo, Otunba Benson Akingboye (Oba) ati Arebuwa Bosun.

Igbimọ to n bojuto eto idibo naa ti seleri pe wọn yoo ṣeto idibo abẹle naa ni ibamu pẹlu ofin ẹgbẹ PDP ati orilẹede Naijiria.

Eto idibo abẹle naa ti gbera sọ bayi ti gbogbo oludije si n fọwọ sọya pe awọn ni yoo jawe olubori.