Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní Otegbeye ni ojúlówó olùdíje sípò gómìnà lẹ́gbẹ́ ADC ní Ogun

Biyi Otegbeye

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ilé ejọ́ kòtẹ́milọ́rùn kan tó fi ìlú Ibadan, olú ìlú ìpínlẹ̀ Oyo ti ní Biyi Otegbeye gangan ni ojúlówó olùdíje sípò gómìnà lẹ́gbẹ́ òṣèlú African Democratic Party, ADC ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹtàlélógún oṣù Kìíní ọdún 2023 ni ilé ẹjọ́ gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀.

Yàtọ̀ sí Otegbeye, ilé ẹjọ́ tún ní gbogbo àwọn olùdíje mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n tó ń díje sípò aṣòfin ìpínlẹ̀ náà lábẹ́ ẹgbẹ́ ADC ni wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti díje dupò.

Ìdájọ́ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí Otegbeye àti àwọn mìíràn pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ gíga kan tó wà ní Abeokuta pàṣẹ pé kí àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbó INEC láti yọ Otegbeye àti àwọn mẹ́tàlélógún mìíràn kúrò lórí ìwé ìdìbò.

Ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party àti All Progressives Congress, APC ló wọ Otegbeye àti àwọn ènìyàn mìíràn lọ sí ilé ẹjọ́ wí pé wọ́n tẹ ẹ̀tọ́ òfin ètò ìdìbò lójú mọ́lẹ̀.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ náà, Otegbeye nínú àtẹ̀jáde kan ní ìlú Abeokuta júwe ìdájọ́ náà bí i ìjáwé olúborí fún gbogbo ènìyàn ìpínlẹ̀ Ogun.