Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ kéde pé owó òṣù tí ìjọba ń san fún aya ààrẹ àti aya igbákejì ààrẹ lòdi sófin

Aworan aya aarẹ ati igbakeji aarẹ Ghana

Oríṣun àwòrán, Samira Bawumia/Facebook

Ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Ghana ti kede pe owo oṣu ti ijọba orilẹede naa n san fun aya aarẹ ati aya igbakeji aarẹ lodi si ofin.

Igbimọ adajọ ẹlẹni meje ti adajọ Gertrude Torkonoo dari rẹ fidi rẹ mulẹ pe ipo aya aarẹ ati aya igbakeji aarẹ kii ṣe ipo ọfiisi ijọba to tọ si owo oṣu gbigba.

Ṣaaju akoko yii ni igbimọ kan ti ijọba gbe dide sọ pe o yẹ kawọn obinrin mejeeji yii maa gbowo oṣu nitori iṣẹ ilu ti wọn n ṣe.

Lẹyin ti ijọba orilẹede Ghana buwọlu aba igbimọ naa wi pe ki ijọba maa sanwo fun wọn ni awọn eeyan meji kan gbe ẹjọ yii lọ sile ẹjọ to gaju lọdun 2021.

Ọkan lara awọn eeyan meji yii ti orukọ rẹ n jẹ Kwame Baffoe wa lati ẹkun Bono lorilẹede Ghana.

Ninu ẹjọ ti o pe, Ọgbẹni Baffoe rọ ile ẹjọ to julọ pe ki o kede pe ‘’ọfiisi aya aarẹ ati ti igbakeji aarẹ ko si lara ọfiisi ijọba gẹgẹ bi alakalẹ iwe ofin Ghana.’’

Baffoe fikun un pe ‘’ile igbimọ aṣofin ko laṣẹ lati maa fun wọn lowo oṣu tori ko si ofin to sọ bẹẹ.’’

Aworan aya aarẹ ati igbakeji aarẹ Ghana

Oríṣun àwòrán, REBECCA AKUFO-ADDO/FACEBOOK

Ọgbẹni Baffoe tun rọ ile ẹjọ to julọ lati kede pe bi ijọba ṣe buwọlu sisan owo oṣu fun aya aarẹ ati aya igbakeji aarẹ ko le fẹsẹ mulẹ.

Ọmọ ẹgbẹ alatako ni ẹnikeji, eyi ti orukọ tiẹ n jẹ Nelson Rockson Dafeamekpor.

Nnkan ti Baffoe sọ fun ile ẹjọ giga ni Dafeamekpor naa beere fun.

Oun tun rọ ile ẹjọ to ga julọ wi pe ki o tu aba igbimọ to ni ki ijọba maa sanwo oṣu fun aya aarẹ ati aya igbakeji aarẹ ka.

Aba ti igbimọ ti ijọba gbe dide lori owo oṣu aya aarẹ ati aya igbakeji aarẹ ree

Ni ọdun 2020 ni igbimọ ti ijọba aarẹ Nana Akufo-Addo gbe dide fẹnuko pe ki ijọba maa sanwo owo oṣu fun aya aarẹ ati aya igbakeji aarẹ atawọn eeyan mii to n ṣiṣẹ pẹlu ijọba.

Awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ ijọba kan, awọn oṣiṣẹ eto idajọ ati ile igbimọ aṣofin naa wa nibẹ.

Igbimọ naa sọ pe ki ijọba maa san iye owo ti awọn minisita to tun jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin n gba fun aya aarẹ.

Fun aya igbakeji aarẹ, igbimọ yii sọ pe ki ijọba san iye owo oṣu ti minisita ti ki i ṣe ọmọ ile aṣofin n gba fun un.

Aworan aarẹ Ghana

Oríṣun àwòrán, REBECCA AKUFO-ADDO/FACEBOOK

Ijọba yoo maa san owo yii fun wọn niwọn igba tawọn ọkọ wọn ba fi wa lori aleefa.

Ẹwẹ, aya aarẹ, Rebecca Akufo-Addo yoo maa gba $3,500 loṣu, iye kan naa laya igbakeji aarẹ pẹlu yoo maa gba.

Eyi tumọ si pe aya aarẹ yoo tẹwọ gba $191,268 ti ijọba ba sanwo yii fun un lati ọdun 2017.

Bayii ni ile aṣofin buwọlu sisan owo yii, amọ, ọpọ ọmọbibi orilẹede Ghana lo tako igbesẹ ijọba yii lori ayelujara..

Aya aarẹ ati aya igbakeji aarẹ ti da owo ti wọn gba pada

Lẹyin ti ọrọ owo yii di iṣu ata yan-an yan-an ni aya aarẹ kede pe oun ṣetan lati da gbogbo owo ti ijọba ti san foun lati ọdun 2017 ti ọkọ rẹ ti di aarẹ pada.

O ṣalaye pe awọn aya aarẹ ati aya igbakeji aarẹ ti jẹ anfani owo ajẹmọnu kan labẹ awọn ijọba to ti wa siwaju.

Aya aarẹ Rebecca ni ọpọ awọn to tako igbesẹ ijọba lati maa sanwo foun ati aya igbakeji aarẹ n sọrọ naa bi ẹni pe oun ko nan-an ni ọpọ ọmọ Ghana ti ko ri ọwọ họri.

‘’Gbogbo owo ti mo ti gba lati ọjọ kejila oṣu Keje ọdun 2021 tii ṣe $67,000 ni mo maa da pada.

Aworan aya igbakeji aarẹ

Oríṣun àwòrán, Samira Bawumia/Facebook

Mo ṣi fẹ kawọn eeyan mọ pe mi o ti gba owo kankan lati igba ti ijọba ti buwọlu sisan owo oṣu fun emi ati igbakeji aarẹ.

Samira Bawumia to jẹ aya igbakeji aarẹ Ghana naa ti kede pe oun naa yoo da gbogbo owo ti ijọba ti san foun lati ọdun 2017 pada.

O ni ‘’mo ti ba ọkọ mi to jẹ igbakeji aarẹ sọrọ, gbogbo owo ti mo ti gba ni maa da pada.’’

Ninu ọrọ rẹ, Nii Samoa Addo, to jẹ agbẹjọro ọkan lara awọn olupẹjọ sọ pe idajọ to dara ni ile ẹjọ gbe kalẹ bo tilẹ jẹ pe ọrọ naa ti wa nile ẹjọ fun bi ọdun mẹta bayii.

Ọgbẹni Addo ni ohun to kan bayii ni sisọ asọyepọ lori ọfiisi aya aarẹ ati aya igbakeji aarẹ tori ko si ninu ofin orilẹede Ghana.