“Àdó olóró pa àwọn òbí mi, gé orí àbúrò mi sọnù, èmi gan ń bẹ̀bẹ̀ fún ikú”

Isẹlẹ nla ti ko si ẹda to le gbadura pe ki iru rẹ sẹlẹ si oun lo sẹlẹ si ọmọ ọdun mejila kan, Alma Muhammed.

Agbegbe Gaza lo n gbe pẹlu awọn obi rẹ, ki ogun to bẹrẹ laarin Israel ati Gaza.

Lọwọlọwọ bayii, gbogbo ẹbi Alma lo ti ku lati ipasẹ ado oloro, amọ oun nikan ni ori ko yọ ninu isẹlẹ naa.

Nigba to n salaye bi gbogbo ẹbi rẹ ti ipasẹ ado oloro ku, Alma salaye pe igba mẹta ọtọọtọ ni awọn ti sa fun ado iku yii, ko to pa ẹbi oun.

Alma Muhammed

Bi ifọrọ werọ BBC ati Alma Muhammed naa se lọ niyi:

“Orukọ mi ni Alma Muhammed, ọmọ ọdun mejila ni miAdo oloro balẹ sibi ti a kọkọ salọ.

Bakan naa, ni ado oloro tun ka wa mọ ibi keji ti a fara pamọ si.

Ibi kẹta ti a wa ni ado oloro ti ba wa.

Gbogbo ẹmi mi lo jade laye, ayọ ni gbogbo wa wa tẹlẹ, ti a si maa n di mọ ara wa lasiko ibẹru.

Aago mẹfa irọlẹ ni wọn ju ado oloro sile wa, mo pe aburo mi, mo ro pe aburo mi Tarazan, tii se ọmọ ọdun kan ati osu mẹfa, si wa laye ni.

Mo bẹrẹ si pe orukọ rẹ kikankikan boya o si n mi, sugbọn ipo ti mo ba a, ko dara rara.

Ori rẹ ti ge sọnu, mo si bẹrẹ si ni gbadura fun iku lẹyin ti mo ri ni ipo buruku yii.

Ki ni ẹsẹ wa ninu ogun yii?”

Alma Muhammed ati awọn ẹbi rẹ to di oloogbe

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí