Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba Eko buwọ́lu ₦70,000 bíi owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ?

Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu

Iroyin to gbode lọjọbọ ni pe gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti buwọlu ₦70,000 gẹgẹ bii owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ nipinlẹ naa.

Inu ọpọ awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ naa lo bẹrẹ si n dun lẹyin iroyin, naa amọ ṣe lootọ ni?

Iroyin ọhun lo gbode lẹyin ti fidio Sanwo-Olu kan milẹ titi, nibi to ti sọ pe laipẹ ni ijọba yoo buwolu afikun owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.

“Sanwo-Olu ko tii ṣafikun owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ”

Ẹwẹ, ninu atẹjade kan lo opo Twitter rẹ, kọmiṣọna eto iroyin ipinlẹ Eko, Gbenga Omotoso ni ko si ohun to jọ bẹẹ ati pe awọn araalu kan ṣi gomina naa gbọ ni.

Omotoso sọ pe ibi eto ti wọn ti ṣi aṣọ loju eegun eto ‘Eko Care’ ni ọọfisi ijọba lagbegbe Ikeja, eyii to jẹ eto adojutofo latari ọwọngogo to gbode ni ọrọ naa ti jade.

O ni “ijọba ipinlẹ Eko ko tii ṣe afikun owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ lodi si awọn iroyin to n lọ nigboro.

“Awọn eeyan ṣi gomina Sanwo-Olu gbọ pe o ti kede ₦70,000 gẹgẹ bii owo oṣu oṣiṣẹ to kere ju.

“Eyii ko ri bẹẹ rara. Gomina ko sọ bẹẹ.”

Ki ni gomina sọ nipa owo oṣu oṣiṣẹ?

Omotoso ṣalaye siwaju si pe ohun ti Sanwo-Olu sọ ni pe “lati inu oṣu Kinni, awọn oṣiṣẹ ti bẹrẹ si n gba ₦35,000 owo to kẹrẹ ju gẹgẹ bii asẹ ijọba apapọ.

“Ohun ti eyii tumọ si ni pe, awọn to n gba ₦35,000 tẹlẹ ti n gba ₦70,000 bayii, ko kede ₦70,000 gẹgẹ bii owo oṣu oṣiṣẹ to kere ju.”

Ẹwẹ, ninu fidio ọhun ti akọroyin BBC wo, ohun ti Sanwo-Olu sọ nibẹ ni pe oun gbagbọ pe ijọba apapọ yoo buwọlu afikun owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ laipẹ.

O pari ọrọ rẹ pe awọn to n gba ₦35,000 si ₦40,000 tẹlẹ nipinlẹ Eko ti n gba ₦70,000.