Kí ló dé tí wàhálà bẹ̀rẹ̀ bí Togo ṣe fẹ́ kúrò nílànà òṣèlú ààrẹ sí ìṣèjọba ẹlẹ́kùnjẹkùn?

Aworan Aare Faure Gnassingbe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile igbimọ aṣofin lorilẹede Togo ti buwọlu iwe ofin tuntun yii ti yoo fikun iye ọjọ ti Aarẹ yoo lori ipo agbara.

Bakan naa ni iwe ofin yii yoo fun orilẹede Togo ni anfani lati parọ bi wọn ṣe n ṣeto ijọba lati eto Ìjọba Presidential lọ si Parliamentary.

Ọpọ ẹgbẹ alatako lo ti bu ẹnu atẹlu ìgbesẹ, ti wọn si sapejuwe rẹ gẹgẹ bii iditẹgbajọba.

Awọn alatilẹyin Aarẹ Faure Gnassingbe naa pẹlu awọn to bu ẹnu atẹlu igbesẹ naa pe yoo mu adikun ba agbara Aarẹ.

Labẹ eto isejọba tuntun yii, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ni yoo yan Aarẹ tuntun lai si aniani fun ọdun mẹfa yatọ si bi eto idibo ṣe gbe kalẹ.

Aarẹ Gnassingbe di Aarẹ lọdun 2005 lẹyin iku Baba rẹ to tí n jẹ Aarẹ lati ọdun 1967

Iyọnipo yii yoo jẹ Aarẹ wa ni po rẹ gẹgẹ bii Aarẹ títí wọ ọdun 2031 lẹyin ni wọn yoo yan Aarẹ mii tí yoo jẹ olori awọn Minisita.

Aarẹ Gnassingbe di Aarẹ lọdun 2005 lẹyin iku Baba rẹ to tí n jẹ Aarẹ lati ọdun 1967.

Atunṣe iwe ofin yii ni igbimọ aṣofin buwọlu ni oṣu to kọja. Sugbọn idaduro waye lẹyin tí Aarẹ pe fun iwadi to peye lori igbesẹ naa.

Minisita aja fẹtọmọniyan, Yawa Djigbodi Tségan bi ìgbesẹ yoo tun ìjọba awarawa ṣe lorilẹede naa.

Ṣugbọn oludije Aarẹ nigba kan ri, Brigitte Kaful Johnson, to lewaju ẹgbẹ oṣelu alatako CDPA sapejuwe igbesẹ gẹgẹ bii eyi to fẹ gba agbara.

Ní ọsẹ sẹyin, awọn igbisọ aṣofin lọ kaakiri ilu lati kede fara ilu pe atunṣe iwe ofin ti wa.

Ibẹruboju ti wa ni ilu bayii lori sísọ erongba ni ìta gbangba nitori bí awọn agbofinro ṣe n wa awọn eeyan to ba n gbero lati se bẹ.

Ninu oṣu to kọja, awọn Ọlọpaa yawọ apero kan nibi ti wọn ti n sọrọ nipa iwe ofin naa.

Ohun taa mọ nípa Faure Gnassingbe

Aworan Aarẹ Faure Gnassingbe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Faure Gnassingbe Eyedema bọ sipo Aarẹ lẹyin iku Baba rẹ to wa gẹgẹ bii Aarẹ fun ọdun mejidinlogoji ni ọdun 2005.

Ileeṣẹ ologun fi Faure Gnassingbe sipo Aarẹ sugbọn lẹyin ọpọlọpọ idunkoko lati ọdọ àjọ agbaye, o pe fun eto idibo.

Gnassingbe ti bori eto idibo fun igba mẹta ni odun 2010, 2015 ati 2020.

Gbogbo eto idibo yii ni awọn ẹgbẹ oṣelu alatako bu ẹnu atẹlu pe wọn ṣe deede.

Atunṣe iwe ofin ni ọdun 2019 fi aye gba Aarẹ Gnassingbe lati jade dupo, eyi to fun ni anfani lati wa nipo títi wọ ọdun 2030.